Iṣẹ́ Ìyọ́nú Ni Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
1 Nígbà tí Jésù kíyè sí ogunlọ́gọ̀ tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀, ó rí i pé “a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mát. 9:36) Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àti tìfẹ́tìfẹ́ ló fi fi àwọn ìlànà Ọlọ́run kọ́ wọn, ó tù wọ́n nínú, ìyọ́nú sì mú kó ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí bí wọ́n á ṣe máa jọ́sìn Ọlọ́run. Bá a bá ń ṣàṣàrò lórí ọ̀nà tí Jésù gbà ń ṣe nǹkan, a ó lè máa ronú bíi tiẹ̀, a óò tún lè máa yọ́nú sáwọn èèyàn bíi tiẹ̀, èyí á sì jẹ́ ká lè máa fi ìyọ́nú hàn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
2 Tiẹ̀ ronú ná nípa ohun tí Jésù ṣe nígbà táwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ lójú méjèèjì wá sọ́dọ̀ rẹ̀. (Lúùkù 5:12, 13; 8:43-48) Ó gba tàwọn tí ìṣòro wọn lékenkà rò. (Máàkù 7:31-35) Ó mọ ohun tó ń da àwọn ẹlòmíì láàmú, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ òun lógún. Ó mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn. (Lúùkù 7:36-40) Ká sòótọ́, Jésù ò kù síbì kan tó bá dọ̀rọ̀ ká fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn bíi ti Ọlọ́run wa.
3 “Àánú Wọ́n Ṣe É”: Jésù ò fi ọwọ́ pé ká-ṣá-ti-ṣe-é mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. ‘Àánú àwọn èèyàn ṣe é.’ (Máàkù 6:34) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, kì í ṣe pé a kàn ń wàásù, ṣùgbọ́n ṣe là ń gbìyànjú láti gba àwọn ẹni tí ẹ̀mí wọn ṣeyebíye là. Mọ ohun tó mú káwọn èèyàn máa fún wa nírú ìdáhùn tá à ń bá lẹ́nu wọn. Kí ló mú kí wọ́n máa ṣàníyàn tàbí kí ló ń dí wọn lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀? Ṣé kì í ṣe títàn táwọn olùṣọ́ àgùntàn èké tàn wọ́n tí wọ́n sì pa wọ́n tì ló fà á? Bá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú, ó ṣeé ṣe kí wọ́n fetí sí ìhìn rere.— 2 Kọ́r. 6:4, 6.
4 Ẹni tá a bá fi ìyọ́nú hàn sí kì í sábà gbà gbé. Àpẹẹrẹ kan rèé: Ọmọ oṣù mẹ́ta ṣàdédé kú lọ́wọ́ obìnrin kan. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí méjì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i, ó ní kí wọ́n wọlé kó bàa lè tako àlàyé wọn lórí ìdí tí Ọlọ́run fi yọ̀ǹda kí ohun burúkú máa ṣẹlẹ̀. Àmọ́, nígbà tó ṣe, obìnrin náà sọ pé: “Wọ́n tẹ́tí sí mi tìyọ́nútìyọ́nú, nígbà tí wọ́n sì fẹ́ máa lọ, ara tù mí débi tí mo fi gbà pé kí wọ́n padà wá.” Ṣé ìwọ náà máa ń sapá láti fi ìyọ́nú hàn sí gbogbo ẹni tó o bá bá pàdé nígbà tó o bá wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?
5 Bá a bá mọ bá a ṣe lè máa fi ìyọ́nú ṣèwà hù, a ó lè máa tu àwọn èèyàn nínú bó ṣe yẹ. A ó sì lè máa ṣàlékún ògo “Bàbá àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́,” Jèhófà.—2 Kọ́r. 1:3.