Mú Káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Mọrírì Àwọn Ànímọ́ Jèhófà Tí Ò Láfiwé
1 Lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, à ń ṣe kọjá kíkọ́ àwọn èèyàn ní àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì. À ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, kí wọ́n bàa lè mọrírì àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí ò láfiwé. Nígbà táwọn aláìlábòsí bá mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, ó ń ṣe bẹbẹ nínú ìgbésí ayé wọn, ó ń mú kí wọ́n tún ọ̀nà tí wọ́n gbà ń gbé ìgbésí ayé wọn ṣe kí wọ́n bàa “lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún.”—Kól. 1:9, 10; 3:9, 10.
2 Ìwé Tuntun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́: Bẹ̀rẹ̀ láti ojú ìwé àkọ́kọ́ ni ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ti ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà. Àkọ́kọ́ nínú àwọn àkòrí inú ìwé náà dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Ǹjẹ́ Ọlọ́run bìkítà nípa rẹ ní ti gidi?, Irú ẹni wo gan-an ni Ọlọ́run jẹ́? àti Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run? Orí yẹn tún tẹ́nu mọ́ bí Jèhófà ṣe jẹ́ mímọ́ (ìpínrọ̀ 10), ó sì sọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ míì bí ìdájọ́ òdodo àti ìyọ́nú (ìpínrọ̀ 11), ìfẹ́ (ìpínrọ̀ 13), agbára (ìpínrọ̀ 16), àánú, oore ọ̀fẹ́, bó ṣe ń wù ú láti dárí jini, sùúrù àti ìdúróṣinṣin (ìpínrọ̀ 19). Ìpínrọ̀ 20 kó gbogbo ẹ̀ pọ̀ pé: “Bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tó ni wàá túbọ̀ máa mọ̀ pé ẹni gidi ni, tí wàá sì máa rí ìdí tó fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kó o sì sún mọ́ ọn.”
3 Báwo la ṣe lè lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà? Lẹ́yìn tá a bá ti jíròrò àwọn ìpínrọ̀ tó sọ nípa ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, a lè bi akẹ́kọ̀ọ́ náà pé, “Kí lèyí jẹ́ kó o mọ̀ nípa Jèhófà fúnra rẹ̀?” tàbí “Ọ̀nà wo lèyí gbà jẹ́ kó o mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ìwọ alára?” Bá a bá ń bi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa nírú ìbéèrè báyìí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́, ṣe là ń kọ́ wọn láti máa ṣàṣàrò lórí ohun tí wọ́n ń kọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ máa mọyì àwọn ànímọ́ Jèhófà tí ò láfiwé.
4 Máa Lo Àpótí Àtúnyẹ̀wò: Bẹ́ ẹ bá ti ka orí kan tán, ní kí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣàlàyé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kókó tó wà nínú àpótí náà, “Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni” lọ́rọ̀ ara rẹ̀. Ní kó wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Láti lè mú kí akẹ́kọ̀ọ́ sọ èrò rẹ̀, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè bi í pé, “Kí lo rí sí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lórí kókó yìí?” Bó o bá ṣe ohun tá a sọ yìí, kì í ṣe pé wàá lè tẹ ẹ̀kọ́ tó wà nínú orí yẹn mọ́ akẹ́kọ̀ọ́ lọ́kàn nìkan ni, á tún jẹ́ kó o lè mọ ohun tó gbà gbọ́ nípa ẹ̀. Èyí á sì ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ kó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun táá mú kí inú Jèhófà dùn sí i.