Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run
1 Lónìí, gbogbo àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè là ń kọ́ ní àwọn ọ̀nà Jèhófà. (Aís. 2:2, 3) Àmọ́, kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tó lè máa “so èso pẹ̀lú ìfaradà,” wọ́n gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Lúùkù 8:15; Máàkù 12:30) Láìsí irú ìfẹ́ yẹn, wọn ò ní í lè lágbára tó láti ṣe mo-kọ̀-ọ́ sáwọn ohun tí kò bójú mu, wọn ò sì ní nígboyà láti ṣe ohun tó tọ́. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà ni pé ká mú kí àwọn ànímọ́ Ọlọ́run máa dá wọn lọ́rùn. Gbà wọ́n níyànjú láti ronú jinlẹ̀ lórí àlàyé tó wà nínú ìwé Sún Mọ́ Jèhófà.
2 Àpẹẹrẹ Rẹ: Àwọn nǹkan tíwọ alára ń ṣe lè nípa tó pọ̀ nínú ọkàn àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí wọ́n bá rí i pé ọwọ́ pàtàkì lo fi mú ìbárẹ́ ìwọ àti Jèhófà tí wọ́n sì rí bí ìbárẹ́ yẹn ṣe nípa lórí ìgbésí ayé rẹ, ó lè mú káwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa nírú ìbárẹ́ bẹ́ẹ̀. (Lúùkù 6:40) Ká sòótọ́, àpẹẹrẹ tiwa fúnra wa sábà máa ń ní ipa tó pọ̀ lórí àwọn ẹlòmíì ju ohun tá a bá fẹnu sọ lọ.
3 Ọ̀nà pàtàkì kan táwọn òbí lè gbà kọ́ àwọn ọmọ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni àpẹẹrẹ táwọn alára bá ń fi lélẹ̀. (Diu. 6:4-9) Tọkọtaya kan tó jẹ́ ìdàníyàn ọkàn wọn pé káwọn ọmọ àwọn dàgbà nínú òtítọ́ lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn òbí tí wọ́n ti kẹ́sẹ járí lẹ́nu òwò ọmọ títọ́. Ọkọ yẹn sọ pe: “Ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn òbí tí mo bá fèrò wérò sọ ni pé àpẹẹrẹ táwọn òbí bá fi lélẹ̀ ṣe kókó.” Èyí fi hàn pé gbogbo ohun táwọn òbí bá ń ṣe nínú ìgbésí ayé wọn á jẹ́ káwọn ọmọ rí ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ “ọ̀rẹ́ Jèhófà.”—Ják. 2:23.
4 Àdúrà Àtọkànwá: O tún lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà nípa kíkọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà látọkànwá. O lè fi àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tí Jésù gbà hàn wọ́n tàbí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà àtọkànwá tó wà nínú Ìwé Mímọ́. (Mátíù 6:9, 10) O lè fi àdúrà tó ò ń gbà kọ́ ọmọ rẹ tàbí àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bó ṣe ỵẹ kí wọ́n máa gbàdúrà. Bí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ àtọkànwá tó ń sọ nínú àdúrà rẹ, wọ́n á rí bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó. Gbà wọ́n níyànjú láti “máa ní ìforítì nínú àdúrà” lákòókò ìṣòro. (Róòmù 12:12) Bí wọ́n bá ṣe ń rí i pé Jèhófà ń ran àwọn lọ́wọ́ lákòókò táwọn nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í gbẹ́kẹ̀ lé e, wọ́n á sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ọ̀rẹ́ kòríkòsùn.—Sm. 34:8; Fílí. 4:6, 7.