ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/07 ojú ìwé 1
  • Ìṣúra Tó Wà Níkàáwọ́ Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìṣúra Tó Wà Níkàáwọ́ Wa
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fọkàn sí Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • O Lè Rí “Ìmọ̀ Ọlọ́run”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Mọyì Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tó O Ní
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Mọyì Àwọn Ìṣúra Tí Kò Ṣeé Fojú Rí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 2/07 ojú ìwé 1

Ìṣúra Tó Wà Níkàáwọ́ Wa

1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọyì iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́, ó sì kà á sí “ìṣúra.” (2 Kọ́r. 4:7) Ọ̀pọ̀ ìṣòro àti inúnibíni ló fara dà nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ ọ̀hún. Kì í jẹ́ kó rẹ òun débi tí ò fi ní lè wàásù fẹ́nikẹ́ni tó bá bá pàdé. Èyí tó pọ̀ lára àwọn ìrìn àjò rẹ̀ lórí ilẹ̀ àti lórí omi ló wu ẹ̀mí rẹ̀ léwu. Báwo la ṣe lè ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù? Ọ̀nà wo la sì lè gbà fi hàn pé a mọyì iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? (Róòmù 11:13) Kí ló mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa jẹ́ ìṣúra tó ṣàrà ọ̀tọ̀?

2 Ìṣúra Tó Ju Ìṣúra Lọ: Èèyàn ní láti làágùn kọ́wọ́ ẹ̀ tó lè tẹ ohun táyé kà sí ìṣúra, síbẹ̀ àǹfààní téèyàn lè rí látinú ìṣúra ọ̀hún kì í tọ́jọ́. Àmọ́ ní ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tó jẹ́ ìṣúra, títí ayé làǹfààní tó ń ṣe wá, kì í tiẹ̀ wá ṣe fáwa nìkan ṣùgbọ́n fáwọn ẹlòmíì pẹ̀lú. (1 Tím. 4:16) Ó máa ń ran àwọn tí ọkàn wọn pé pérépéré lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa Jèhófà, kí wọ́n lè ṣe àyípadà tó bá yẹ nígbèésí ayé wọn láti lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. (Róòmù 10:13-15) Bá a bá mọyì iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ìgbésí ayé wa á nítumọ̀, ọkàn wa á balẹ̀ pé a ti ṣe ohun tó yẹ ká ṣe, a ò sì ní máa ṣiyè méjì nípa bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí.—1 Kọ́r. 15:58.

3 Bó O Ṣe Lè Fi Hàn Pé O Mọyì Ìṣúra Rẹ: Bá a bá ka ohun kan sí pàtàkì, a ò ní kọ ohunkóhun tó lè ná wa kọ́wọ́ wa bàa lè tẹ̀ ẹ́. Àǹfààní ńláǹlà ló jẹ́ láti máa fi àkókò àti agbára wa yin Jèhófà! (Éfé. 5:16, 17) Ọ̀nà tá a gbà ń lo àkókò wa gbọ́dọ̀ fi hàn pé àwọn nǹkan tó kan ìjọsìn wa sí Jèhófà la kà sí pàtàkì ju àwọn nǹkan ìní, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti fàájì lọ. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iṣẹ́ pàtàkì la ní láti jẹ́ fáwọn èèyàn, ṣe ló yẹ ká máa fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà jẹ́ iṣẹ́ náà, ká sì máa wà lójúfò láti wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ.

4 A kì í fi ìṣúra iyebíye pa mọ́, ńṣe la máa ń fẹ́ káwọn èèyàn rí i. Bá a bá ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sí irú ìṣúra bẹ́ẹ̀, òun la máa jẹ́ kó gbawájú nígbèésí ayé wa. (Mát. 5:14-16) Ǹjẹ́ ká máa fi ìmọrírì àtọkànwá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ká sì máa lo àǹfààní èyíkéyìí tá a bá ní láti fi hàn pé lóòótọ́ la mọyì iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, pé ìṣúra ló jẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́