Mọyì Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tó O Ní
1. Ojú wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé fi ń wo iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe?
1 “Ọ̀rọ̀ òmùgọ̀” ni ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé Sátánì yìí ka iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe sí. (1 Kọ́r. 1:18-21) Tá ò bá ṣọ́ra, èrò òdì táwọn èèyàn ní yìí lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, kó sì mú kí ìtara wa dín kù. (Òwe 24:10; Aísá. 5:20) Kí nìdí tó fi yẹ ká mọyì àǹfààní tá a ní pé a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà?—Aísá. 43:10.
2. Kí nìdí tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa fi jẹ́ “iṣẹ́ mímọ́”?
2 “Iṣẹ́ Mímọ́”: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá à ń ṣe ní “iṣẹ́ mímọ́.” (Róòmù 15:15, 16) Ọ̀nà wo ni iṣẹ́ ìwàásù wa fi jẹ́ “iṣẹ́ mímọ́”? Tá a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, èyí ń mú ká jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú “Ẹni Mímọ́” náà, Jèhófà, ó sì ń sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. (1 Kọ́r. 3:9; 1 Pét. 1:15) Jèhófà ń wo iṣẹ́ ìwàásù wa gẹ́gẹ́ bí “ẹbọ ìyìn,” torí náà iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa.—Héb. 13:15.
3. Kí ló mú kí wíwàásù ìhìn rere jẹ́ àǹfààní ńláǹlà?
3 Àǹfààní ńláǹlà ni wíwàásù ìhìn rere jẹ́, ìwọ̀nba àwọn èèyàn díẹ̀ ló sì ń ní in. Bí àwọn ańgẹ́lì bá ní àǹfààní yìí, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n á fi máa ṣe é, ó sì dájú pé wọ́n máa ṣe é dáadáa gan-an. (1 Pét. 1:12) Àmọ́, àwa èèyàn aláìpé tó jẹ́ “àwọn ohun èlò tí a fi amọ̀ ṣe” ni Jèhófà gbé iṣẹ́ pàtàkì yìí fún!—2 Kọ́r. 4:7.
4. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
4 Ó Yẹ Ká Fi Sípò Àkọ́kọ́: Torí pé a mọyì àǹfààní tá a ní, a ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sí ọ̀kan lára “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù” nígbèésí ayé wa. (Fílí. 1:10) Torí náà, a máa ń ṣètò àkókò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti kópa nínú rẹ̀. Olórin kan tó mọyì àǹfààní tó ní láti kọrin láàárín àwọn gbajúgbajà olórin jákèjádò ayé máa múra sílẹ̀ dáadáa fún ipa tirẹ̀, á sì ṣiṣẹ́ kára láti mú kí ọ̀nà tí ó ń gbà kọrin túbọ̀ dára sí i. Bákan náà, a máa ń múra sílẹ̀ ká tó lọ sí òde ẹ̀rí ká bàa lè máa “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́,” a ó sì ṣiṣẹ́ lórí bá a ṣe máa mú kí “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” wa dára sí i.—2 Tím. 2:15; 4:2.
5. Àwọn wo ló ń mọrírì iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
5 Má ṣe jẹ́ kí èrò tí kò tọ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. Má gbàgbé pé ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tí wọ́n mọrírì bá a ṣe ń wá sọ́dọ̀ wọn. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe ojúure àwọn èèyàn là ń wá o. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni bí iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe ń rí lára Jèhófà, ó sì mọyì bá a ṣe jẹ́ aláápọn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.—Aísá. 52:7.