“Aláyọ̀ Ni Ẹni Tí Ń Bá A Nìṣó ní Fífarada Àdánwò”
1 Gbogbo Kristẹni ló máa ní láti kojú àdánwò. (2 Tím. 3:12) Lára irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀ ni àìlera, àìríná àìrílò, ìdánwò tàbí inúnibíni, ó sì lè jẹ́ láwọn ọ̀nà míì. Sátánì máa ń fa àdánwò bá wa ká lè dẹwọ́, ká lè bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ yẹpẹrẹ mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa tàbí ká tiẹ̀ lè ṣíwọ́ sísin Ọlọ́run. (Jóòbù 1:9-11) Ọ̀nà wo ni fífara da àdánwò lè gbà mú wa láyọ̀?—2 Pét. 2:9.
2 Múra Sílẹ̀ De Àdánwò: Jèhófà ti fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀, nínú èyí tá a ti lè kà nípa ìgbésí ayé Jésù àtàwọn ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni. Bá a bá ń kà á, tá a sì ń fi sílò, ìpìlẹ̀ tó lágbára là ń fi lélẹ̀ yẹn, èyí tó túmọ̀ sí pé à ń múra sílẹ̀ de àdánwò. (Lúùkù 6:47-49) A tún máa ń rí okun gbà nípasẹ̀ àwọn ará wa, nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń tẹ̀ àti nípàdé ìjọ. Lóòrèkóòrè la sì ń láǹfààní láti gbàdúrà sí Ọlọ́run.—Mát. 6:13.
3 A tún nírètí pé Jèhófà máa mú ìlérí tó ṣe fún wa ṣẹ. Bá a bá mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú àwọn ìlérí Jèhófà lágbára, ńṣe ni ìrètí wa á dà ‘bí ìdákọ̀ró fún ọkàn, tó dájú, tó sì fìdí múlẹ̀ gbọn-in.’ (Héb. 6:19) Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọkọ̀ ojú omi kì í kúrò ní èbúté láìsí ìdákọ̀ró, ojú ọjọ́ ì báà tiẹ̀ dára jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ìjì ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í jà, tí wọ́n sì ju ìdákọ̀ró sínú òkun, ọkọ̀ ò ní forí sọ àpáta. Bákan náà, bá a bá mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run lágbára nísinsìnyí, ó máa jẹ́ ká lè dúró gbọn-in bí àdánwò bá dé. Àdánwò lè ṣàdédé bá wa lọ́sàn-án kan òru kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tọwọ́ tẹsẹ̀ làwọn aráàlú Lísírà fi kọ́kọ́ tẹ́wọ́ gba Pọ́ọ̀lù àti Bánábà nígbà tí wọ́n wàásù fún wọn, síbẹ̀ bírí ni nǹkan yí padà nígbà táwọn Júù bẹ̀rẹ̀ àtakò.—Ìṣe 14:8-19.
4 Ìfaradà Máa Ń Yọrí sí Ayọ̀: Bá a bá ń bá a nìṣó láti máa wàásù lákòókò tí àdánwò ń dojú kọ wá, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Ńṣe ló yẹ kínú wa máa dùn bí wọ́n bá kàn wá lábùkù nítorí orúkọ Kristi. (Ìṣe 5:40, 41) Bá a bá ń fara da àdánwò, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní àwọn ànímọ́ bí ìrẹ̀lẹ̀, ìgbọràn àti ìfaradà. (Diu. 8:16; Héb. 5:8; Ják. 1:2, 3) Ìfaradà máa ń kọ́ wa bá a ṣe lè máa gbọ́kàn lé Jèhófà, bá a ṣe lè máa gba àwọn ìlérí rẹ̀ gbọ́ àti bá a ṣe lè máa fi í ṣe odi agbára wa.—Òwe 18:10.
5 A mọ̀ pé àdánwò kì í wà lọ títí, fúngbà díẹ̀ ni. (2 Kọ́r. 4:17, 18) Àdánwò máa ń jẹ́ ká ní àǹfààní tá a fi lè jẹ́ kí Jèhófà mọ bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ òun tó. Bá a bá lè fara da àwọn àdánwò tó bá dojú kọ wá, á lè mú kó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti fún Sátánì lésì. Nítorí náà, a ò gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ o! Ó ṣe tán, “aláyọ̀ ni ẹni tí ń bá a nìṣó ní fífarada àdánwò, nítorí nígbà tí ó bá di ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, yóò gba adé ìyè.”—Ják. 1:12.