Àpéjọ Àkànṣe Tó Ń Bọ̀ Lọ́nà
Ẹṣin ọ̀rọ̀ Àpéjọ Àkànṣe tọdún iṣẹ́ ìsìn 2008 ni, “Amọ̀ Ni Wá, Jèhófà Ló sì Ń Mọ Wá,” èyí tá a gbé ka Aísáyà 64:8. Ìmọ̀ràn tó bá Ìwé Mímọ́ mu tá a máa rí gbà ní àpéjọ yìí á mú kí ìmọrírì tá a ní fún ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo, agbára àti ìfẹ́ Jèhófà, tó jẹ́ Amọ̀kòkò wa, túbọ̀ pọ̀ sí i.
Àsọyé tí alábòójútó àyíká máa sọ, èyí tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́, “Bá A Ṣe Lè Máa Sìn Gẹ́gẹ́ Bí Ohun Èlò Tó Lọ́lá Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,” á jẹ́ ká rí i pé ńṣe làwọn tó láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí wọ́n sì ń wàásù rẹ̀ fáwọn ẹlòmíì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àsọyé tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Máa Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ara Rẹ Nípa Ṣíṣe Àṣàrò,” máa jẹ́ ká rí i pé ààbò ni ṣíṣàṣàrò gidigidi lórí àwọn ìlànà òdodo Jèhófà jẹ́ fún wa. Olùbánisọ̀rọ̀ tá a máa rán wá máa bá àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tó sọ pé, “A Kò ‘Dáṣà Ní Àfarawé Ètò Àwọn Nǹkan Yìí’” àti “Jẹ́ Kí Amọ̀kòkò Tí Kò Lẹ́gbẹ́ Náà Mọ Ẹ́.” Àsọyé tá a pè ní “Àwọn Ọ̀dọ́ Tí Wọ́n Wúlò fún Jèhófà” àti “Ipa Pàtàkì Táwọn Òbí Ń Kó Nínú Títọ́ Àwọn Ọmọ Wọn” máa gba àwọn òbí àtàwọn ọ̀dọ́ níyànjú. Nípasẹ̀ àṣefihàn àtàwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, inú wa máa dùn láti gbọ́ nípa gudugudu táwọn ará wa ń ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, a ó sì tún fojú ara wa rí bí wọ́n ti ń ṣe é. Kí àwọn tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run sọ fún alága àwọn alábòójútó ìjọ wọn láìfi àkókò falẹ̀. Rántí mú Ilé Ìṣọ́ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́sẹ̀ yẹn dání tó o bá ń bọ̀ wá sí àpéjọ àkànṣe yìí.
Gbogbo ohun tí Amọ̀kòkò Tí Kò Lẹ́gbẹ́ yìí bá gbèrò àtiṣe ló máa ń di ṣíṣe. Ó wá kù sọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa láti pinnu bóyá a máa gbà pé kó mọ wá. Àwọn tó bá gbà pé kí Jèhófà darí àwọn, kó sì báwọn wí, máa dà bí amọ̀ tútù lórí àgbá kẹ̀kẹ́ amọ̀kòkò. Amọ̀kòkò á lè mọ wọ́n bí ìgbà tó ń fi amọ̀ mọ nǹkan, á wá mú kí wọ́n dùn-ún wò, ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá di ohun èlò tó wúlò. Jèhófà máa rọ̀jò ìbùkún yabuga sórí wa bá a bá gbà pé kó mọ wá lọ́nà yìí, a ó sì gbé ipò rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ.