ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/08 ojú ìwé 5
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Oúnjẹ Ní Àkókò Tí Ó Bẹ́tọ̀ọ́ Mu’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àkànṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe ti Ọdún 2010
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 12/08 ojú ìwé 5

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun

Ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àkànṣe wa tí ọdún iṣẹ́ ìsìn 2009 ni ‘Máa Ṣọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ, Kó O Lè Mú Un Ṣẹ,’ èyí tá a gbé ka Kólósè 4:17. Ọwọ́ pàtàkì làwa Kristẹni fi mú ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí. Ohun tó wà lórí ẹ̀mí wa ni láti fi òótọ́ inú parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa bí Jésù ti ṣe. (Jòh. 17:4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà fàpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa lórí ọ̀ràn yìí. Ó pinnu láti parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó gbà.—Ìṣe 20:24.

Apá tí alábòójútó àyíká máa bójú tó máa jẹ́ ká mọ ohun táwọn akéde kan ṣe kí wọ́n lè borí àwọn nǹkan tó fẹ́ dí wọn lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Lẹ́yìn náà, àsọyé kan tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Bomi Rin Ohun Tó O Gbìn” máa tẹnu mọ́ bá a ṣe lè ran àwọn tí wọ́n ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” lọ́wọ́. (Ìṣe 13:48) Àlejò tí ẹ̀ka ọ́fíìsì máa rán wá máa jíròrò ìwé 2 Kọ́ríńtì 6:1-10, lẹ́sẹẹsẹ nínú àsọyé tó máa kọ́kọ́ sọ, àkòrí àsọyé náà ni “Bá A Ṣe Ń Dámọ̀ràn Ara Wa Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́.” Bó bá di ọ̀sán, ó máa bá àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí kókó náà “Fọwọ́ Pàtàkì Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ.” Kò sí àní-àní pé àwọn ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ máa gbọ́ nínú àwọn àsọyé méjì tá a pé àkòrí wọn ní “Tèwetàgbà Ń Gbádùn Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wọn” àti “Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ń Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wọn Ṣẹ” máa fún yín níṣìírí gan-an ni. Káwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún Jèhófà ní àpéjọ àkànṣe tàbí àyíká tó ń bọ̀ yìí lọ sọ fún alága àwọn alábòójútó kó tó pẹ́ jù. Apá pàtàkì ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ jẹ́ láwọn àpéjọ àtàwọn àpéjọ àgbègbè wa. Nítorí náà, mú ẹ̀dà tá a máa kà lọ́sẹ̀ àpéjọ àkànṣe dání wá.

Bá a ṣe ń sapá láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ṣẹ, a fẹ́ rí i dájú pé ohunkóhun ò pín ọkàn wa níyà kúrò nídìí iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́. Ǹjẹ́ káwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wá látinú Ìwé Mímọ́ tá a máa gbọ́ ní àpéjọ àkànṣe wa tó ń bọ̀ yìí mú kó rọrùn fún wa láti mọ ohun tá a lè ṣe ká má bàa yẹsẹ̀, ká sì máa yẹ ara wa wò pẹ̀lú èrò láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ṣẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́