Má Ṣaláì Ṣe É!
1. Kí là ń ṣe tó fi hàn pé a ò “fawọ́ ohun rere sẹ́yìn”?
1 Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó fi hàn pé a ò “fawọ́ ohun rere sẹ́yìn” kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ tá a ti ń wàásù. (Òwe 3:27) Kò sọ́rọ̀ tó dáa tá a lè sọ fáwọn èèyàn ju pé ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé nǹkan ń bọ̀ wá dára nígbà ìṣàkóso Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà tó o bá ń wàásù láìjẹ́-bí-àṣà tàbí tó ò ń fáwọn èèyàn láwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, o ti lè máa sọ nípa àwọn ohun tá a mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ń bọ̀ wá ṣe fún wọn, o ò ṣe kúkú fi ṣe ìfojúsùn rẹ láti máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ò bá tíì máa ṣe bẹ́ẹ̀.
2. Kí làwọn ohun tí kì í jẹ́ ká ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
2 Nígbà míì, bọ́ràn náà ṣe rí lára wa ni olórí ohun tí kì í jẹ́ ká ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìdí táwọn kan ò fi ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé wọ́n máa ń rò pé àwọn ò tóótun láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí pé ọwọ́ àwọn dí débi pé àwọn ò lè ráyè fún un. Tó bá jẹ́ pé bọ́ràn ṣe rí lára rẹ nìyẹn, àwọn ìmọ̀ràn tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí jíròrò báyìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—Mát. 28:19; Ìṣe 20:20.
3. Kí ló mú ká tóótun láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
3 Tó O Bá Rò Pé O Kò Tóótun: Ṣé torí pé o ò kàwé débi tó o rò pé ó yẹ tàbí torí àwọn nǹkan míì lo ṣe rò pé o kò tóótun láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn Kristẹni tó fìtara wàásù ní ọ̀rúndún kìíní “jẹ́ àwọn ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù.” Kí ló wá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé “wọ́n ti máa ń wà pẹ̀lú Jésù.” (Ìṣe 4:13) Jésù, Olùkọ́ Ńlá náà ló kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Gbogbo ohun tí Jésù sì kọ́ni àtàwọn ọ̀nà tó gbà kọ́ni ló ti wà lákọọ́lẹ̀ fún wa nínú Ìwé Mímọ́. Ká tiẹ̀ wá sọ pé o ò kàwé tó bó ṣe yẹ, ìmọ̀ tó ò ń gbà nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run máa ṣe ju ohun tí olùkọ́ kan lè kọ́ ẹ níléèwé lọ.—Aísá. 50:4; 2 Kọ́r. 3:5.
4. Kí la rí kọ́ lára Ámósì?
4 Nígbà míì, Jèhófà máa ń lo àwọn wòlíì rẹ̀ láti bá àwọn alákòóso àtàwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn wí, tí wọ́n bá pòfin rẹ̀ níjà. Àwọn kan lára àwọn wòlíì wọ̀nyí wá látinú ìdílé tí ò rí jájẹ, irú bí Ámósì. Ámósì alára ò jiyàn, ó sọ pé: “Èmi kì í ṣe wòlíì tẹ́lẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì í ṣe ọmọ wòlíì; ṣùgbọ́n olùṣọ́ agbo ẹran ni mí àti olùrẹ́ ọ̀pọ̀tọ́ igi síkámórè.” (Ámósì 7:14) Síbẹ̀, Ámósì ò fà sẹ́yìn láti kéde ìdájọ́ Jèhófà sórí Amasááyà àlùfáà tó tún ń jọ́sìn ère ọmọ màlúù. (Ámósì 7:16, 17) A gbọ́dọ̀ máa rántí ní gbogbo ìgbà pé iṣẹ́ Ọlọ́run là ń ṣe, òun ló sì máa jẹ́ ká tóótun fún iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́.—2 Tím. 3:17.
5. Kí nìdí tó fi yẹ ká bẹ̀rẹ̀ sí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bọ́wọ́ wa bá tiẹ̀ dí?
5 Bọ́wọ́ Rẹ Bá Dí: Bó ti lè wù kọ́wọ́ rẹ dí tó, ó dájú pé wàá lákòókò tó o máa ń lọ sóde ẹ̀rí. Dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà lára àwọn ohun tó máa fún ẹ láyọ̀ jù lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́ láti rí bí Ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe ń mú kí ayé àwọn èèyàn nítumọ̀. (Héb. 4:12) Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá yááfì àwọn nǹkan kan ká lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti “wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Àwọn áńgẹ́lì pàápàá máa ń láyọ̀ nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ronú pìwà dà tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí.—Lúùkù 15:10.
6. Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ wo la ní bá a ṣe ń ṣe nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́?
6 Ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run ni “pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ la ní láti máa ṣe nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́, bá a ṣe ń tiraka láti má ṣaláì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!