ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/07 ojú ìwé 8
  • Máa Sọ̀rọ̀ Ìtùnú Fáwọn Tó Sorí Kọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Sọ̀rọ̀ Ìtùnú Fáwọn Tó Sorí Kọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Bí Ọlọ́run Ṣe Ń Tù Wá Nínú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • “Tu Gbogbo Àwọn Tí Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìtùnú àti Ìṣírí—Àwọn Ohun Iyebíye Alápá Púpọ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 12/07 ojú ìwé 8

Máa Sọ̀rọ̀ Ìtùnú Fáwọn Tó Sorí Kọ́

1 Àsìkò yìí gan-an làwọn èèyàn nílò ọ̀rọ̀ ìtùnú ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Bíi ti Ọba wa Kristi Jésù, àwa náà ní láti máa “di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn.”—Aísá. 61:1.

2 Bá A Ṣe Lè Ṣe É: Tá a bá fẹ́ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn èèyàn, a ní láti máa fọgbọ́n gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lóde ẹ̀rí, kọ́rọ̀ wa sì máa tù wọ́n lára. Bá a bá tiẹ̀ máa sọ̀rọ̀ nípa ipò ayé tó ń dojú rú àtàwọn ẹ̀kọ́ èké tó ń gbilẹ̀, ṣókí ni kó jẹ́, ká lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ti ṣe láti mú kí nǹkan sunwọ̀n sí i. Ìyẹn ò wá ní ká máà dẹ́nu lé ọ̀rọ̀ nípa Amágẹ́dọ́nì rárá o. Ojúṣe wa ni láti “pòkìkí ọdún ìtẹ́wọ́gbà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà àti ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa” ká sì “kìlọ̀ fún ẹni burúkú . . . pé kí ó kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀.” Síbẹ̀ a ò gbọ́dọ̀ wá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ nípa Amágẹ́dọ́nì àti ìparun tó máa mú wá bo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù mọ́lẹ̀.—Aísá. 61:2; Ìsík. 3:18; Mát. 24:14.

3 Láti Ilé dé Ilé: Pé àìsàn, ikú ará tàbí ọ̀rẹ́ ẹni, ìwà ìrẹ́nijẹ àti ipò ọrọ̀ ajé tó ń dojú rú ń sorí àwọn èèyàn kodò kì í ṣe nǹkan tuntun mọ́. Bíi ti Kristi, ‘àánú àwọn èèyàn ń ṣe wá,’ a sì ń ṣe ohun gbogbo tá a lè ṣe láti fi han àwọn tá à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù pé à ń bá wọn kẹ́dùn. (Lúùkù 7:13; Róòmù 12:15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò burú tá a bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro wọn, ó yẹ ká máa “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́” ká lè fún wọn láyè láti sọ tọkàn wọn. (Jak. 1:19) Tá a bá ti gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ tán la tó lè mọ ohun tá a máa sọ láti tù wọ́n nínú.

4 Bá a ṣe ń bá ọ̀rọ̀ lọ a lè láǹfààní láti sọ pé, “Àwọn ọ̀rọ̀ tó lè gbéni ró wà nínú Bíbélì, màá fẹ́ láti ka díẹ̀ nínú ẹ̀ sí yín létí.” Ó yẹ ká ṣọ́ra kó má lọ jẹ́ pé gbogbo èrò tí kò tọ̀nà tí onílé ń sọ la ó máa fẹ́ tún ṣe lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, bá a ṣe fẹ́ fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tù wọ́n nínú ká sì tún fi gbé wọn ró la fẹ́ gbájú mọ́. O lè wo ìwé Reasoning From the Scriptures ojú ìwé 117 sí 121, lábẹ́ “Encouragement,” [Ìṣírí]. O sì lè fún onílé ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ìtùnú fun Awọn ti o Soríkọ́, kó o sì jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú tó wà níbẹ̀.

5 Máa Wá Bó O Ṣe Lè Tu Àwọn Ẹlòmíì Nínú: Ǹjẹ́ o mọ aládùúgbò, alábàáṣiṣẹ́, ọmọ iléèwé tàbí mọ̀lẹ́bí ẹ kan tó yẹ kó o tù nínú? O ò kúkú ṣe wá àyè láti bẹ onítọ̀hún wò nílé kó o lè fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù ú nínú? Tó o bá mọ ìdí tí wọ́n fi nílò ìtùnú, wàá mọ bó o ṣe máa múra ọ̀rọ̀ tó o máa bá wọn sọ sílẹ̀. Àwọn kan ti kọ lẹ́tà tàbí kí wọ́n pe àwọn èèyàn sórí tẹlifóònù kí wọ́n lè tù wọ́n nínú. Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa, a ó máa fọ̀rọ̀ wọn ro ara wa wò, a ó sì máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ tó lè tù wọ́n nínú fún wọn.—Lúùkù 10:25-37.

6 Bẹ́ẹ̀ ni, ojúṣe wa ni láti tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú, ká dá àwọn tó sorí kọ́ lára yá, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Irú ìtùnú báwọ̀nyí gan-an laráyé nílò lákòókò tá a wà yìí. Tá a bá ń sọ nípa àwọn nǹkan mèremère tí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wọn, ó dájú pé ìyẹn á tù wọ́n nínú, àwọn tó dìídì fẹ́ mọ òtítọ́ á sì mọ̀ pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa. Ẹ jẹ́ ká máa rántí nígbà gbogbo pé ojúṣe wa ni láti di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́