ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/08 ojú ìwé 1
  • A Ní Ìṣúra Iyebíye Láti Pín

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Ní Ìṣúra Iyebíye Láti Pín
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Rí Ìṣúra Tá A Rọra Fi Pa Mọ́ Sínú Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Máa Fọkàn sí Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Mọyì Àwọn Ìṣúra Tí Kò Ṣeé Fojú Rí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Nípìn-ín Nínú Ayọ̀ Tó Wà Nínú Fífúnni!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 11/08 ojú ìwé 1

A Ní Ìṣúra Iyebíye Láti Pín

1 A mọyì ọ̀pọ̀ ìṣúra iyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sm. 12:6; 119:11, 14) Nígbà kan, Jésù lo oríṣiríṣi àpèjúwe láti ṣàlàyé apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó wá bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Òye gbogbo nǹkan wọ̀nyí ha yé yín bí?” Nígbà tí wọ́n fèsì pé ó yé àwọn, ó wá sọ fún wọn pé: “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn rí, olúkúlùkù olùkọ́ni ní gbangba, nígbà tí a bá ti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìjọba ọ̀run, dà bí ọkùnrin kan, baálé ilé kan, tí ń mú àwọn ohun tuntun àti ògbólógbòó jáde láti inú ibi ìtọ́jú ìṣúra pa mọ́ rẹ̀.”—Mát. 13:1-52.

2 Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́ nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ dà bí ìṣúra ògbólógbòó. Bá a ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, à ń kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ mìíràn, èyí tó dà bí àwọn ìṣúra tuntun. (1 Kọ́r. 2:7) Bákan náà, nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” à ń lóye àwọn ẹ̀kọ́ tuntun.—Mát. 24:45.

3 A mọyì àwọn ìṣúra tẹ̀mí yìí gan-an ni, ì báà ṣe ògbólógbòó tàbí tuntun. Èyí ló mú ká fẹ́ máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́, ká sì túbọ̀ mọ bá a ṣe ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni. A sì ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣíṣeyebíye tá a ti kọ́ pẹ̀lú ẹ̀mí ọ̀yàyà.

4 Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Jésù: Jésù fi hàn pé òun mọyì àwọn ìṣúra tẹ̀mí yìí nípa bó ṣe sapá gidigidi láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ nípa rẹ̀. Kódà, nígbà tó rẹ̀ ẹ́ pàápàá, kò yéé mú àwọn ìṣúra jáde látinú “ibi ìtọ́jú ìṣúra pa mọ́” rẹ̀.—Jòh. 4:6-14.

5 Ìfẹ́ tí Jésù ní sáwọn tí kò ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe ló mú kó kọ́ wọn ní ohun iyebíye tó ń fúnni ní ìyè látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sm. 72:13) Ó káàánú àwọn tí ebi tẹ̀mí ń pa, èyí sì mú kó “kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.”—Máàkù 6:34.

6 Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù: Tá a bá mọyì àwọn ohun iyebíye tẹ̀mí tá a ní bíi ti Jésù, á máa wù wá láti fi wọ́n han àwọn èèyàn látinú Bíbélì ní tààràtà. (Òwe 2:1-5) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè rẹ̀ wá láwọn ìgbà míì, síbẹ̀ a ó máa fi ìtara kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ látinú Ìwé Mímọ́. (Máàkù 6:34) Tá a bá ní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fáwọn ohun iyebíye yìí, èyí á mú ká túbọ̀ fi ara wa fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, a ó sì máa ṣe púpọ̀ sí i.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́