ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/08 ojú ìwé 1
  • Ran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́ Láti Fara Da Àtakò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́ Láti Fara Da Àtakò
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Fi Ètò Jèhófà Sílẹ̀
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • “Ẹ Jẹ́ Kí Ìfaradà Ṣe Iṣẹ́ Rẹ̀ Pé Pérépéré”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • O Lè Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà Táwọn Èèyàn Bá Tiẹ̀ Ń Ta Kò Ẹ́
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìfaradà—Ṣekókó fún Àwọn Kristian
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 11/08 ojú ìwé 1

Ran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́ Láti Fara Da Àtakò

1 Nígbà táwọn èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì, tí wọ́n sì “ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run,” Sátánì máa ń sapá gidigidi láti gbógun tì wọ́n. (2 Tím. 3:12) Àtakò lè wá látọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ iléèwé tàbí aládùúgbò wọn. Èyí tó wá le jù níbẹ̀ ni pé káwọn mọ̀lẹ́bí wọn máa takò wọ́n.—Mát. 10:21; Máàkù 3:21.

2 Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Pé A Máa Rí Àtakò: Ó yẹ káwọn ẹni tuntun mọ̀ pé àwọn máa rí inúnibíni, èyí ló sì máa fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Kristi ni wọ́n lóòótọ́. (Jòh. 15:20) Láwọn ìgbà míì, ó lè jẹ́ pé èrò òdì táwọn kan ní nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló mú kí wọ́n máa ṣàtakò. Àmọ́ o, ká má gbàgbé pé a máa ní ayọ̀ ńláǹlà táwọn èèyàn bá fàbùkù kàn wá torí pé a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù tá a sì ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run. (Ìṣe 5:27-29, 40, 41) Ẹ jẹ́ kó dá àwọn ẹni tuntun lójú pé Jèhófà á tì wọ́n lẹ́yìn. (Sm. 27:10; Máàkù 10:29, 30) Tí wọ́n bá di ìwà títọ́ wọn mú, èyí á fi hàn pé wọ́n gba Jèhófà ní Ọba Aláṣẹ láyé àtọ̀run.—Òwe 27:11.

3 Iṣẹ́ Tí Ìmọ̀ Pípéye Máa Ń Ṣe: Jẹ́ kí àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa bá a nìṣó láti máa gba ìmọ̀ pípéye sínú láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n lè ní sí. Sátánì máa ń lo àtakò láti mú kí ohun tí wọ́n ń kọ́ má ṣe ta gbòǹgbò nínú ọkàn wọn. (Òwe 4:23; Lúùkù 8:13) Wọ́n gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti gba ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú, kí wọ́n lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.—Sm. 1:2, 3; Kól. 2:6, 7.

4 A Nílò Ìfaradà: Ìṣòro yòówù kéèyàn ní, ìfaradà ṣe pàtàkì torí pé ó máa ń so èso rere. (Lúùkù 21:16-19) Báwọn ẹni tuntun bá ń fara da àtakò, wọ́n ń ṣe ara wọn àtàwọn ẹlòmíì láǹfààní. Wọ́n á rí bí Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn tó ń bá a nìṣó láti fara dà á.—Ják. 1:12.

5 Inú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dùn gidigidi nítorí pé àwọn ará tó wà ní Tẹsalóníkà ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí wọn, àwọn tó jẹ́ pé òun ló kọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (2 Tẹs. 1:3-5) Àwa náà lè ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn bíi ti Pọ́ọ̀lù tá a bá ń ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti máa fara dà àtakò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́