Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 10
Orin 205
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù November sílẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ará ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo Ilé Ìṣọ́ November 1 àti Jí! October-December lóde ẹ̀rí, ní kí wọ́n sọ bí wọ́n ṣe lo àwọn ìwé ìròyìn yìí tó sì so èso rere.
15 min: Ẹ Máa Mú Ẹ̀mí Ìfẹ́ àti Ọ̀làwọ́ Dàgbà. Kí alàgbà kan sọ àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ November 15, 2008, ojú ìwé 6 àti 7.
20 min: “A Ní Ìṣúra Iyebíye Láti Pín.”a Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ kejì, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kọ́ Bíbélì kan pàtó tó mú kí wọ́n wá sínú ètò Jèhófà tàbí èyí tó wú wọn lórí gan-an látìgbà tí wọ́n ti ṣèrìbọmi.
Orin 71
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 17
Orin 80
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: Àpótí Ìbéèrè.b
20 min: “O Lè Di Olùkọ́!”c Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àkéde tàbí aṣáájú ọ̀nà kan tó ti borí èrò tó ni tẹ́lẹ̀ pé òun ò lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Báwo ló ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́? Àwọn ọ̀nà pàtó wo ni ètò Ọlọ́run gbà ràn án lọ́wọ́ láti dẹni tó tóótun? Àwọn ìbùkún wo ló ti rí nínú bó ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Orin 143
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 24
Orin 217
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Sọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá máa lò lóṣù December, ṣàṣefihàn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tàbí méjì.
20 min: “Kíkọ́ Àwọn Ibi Ìjọsìn Lọ́nà Tó Mọ Níwọ̀n Ń Fìyìn fún Jèhófà.”d Ìpínrọ̀ 1 sí 8. Alàgbà ni kó bójú tó apá yìí. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 8, ní kí àwùjọ sọ ìrírí ṣókí nípa àǹfààní tí wọ́n rí nígbà tí wọ́n ń ṣèrànwọ́ láti kọ́ àwọn ibi ìjọsìn ládùúgbò wọn. O lè ṣètò ìdáhùn kan tàbí méjì sílẹ̀.
15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Ilé Ìṣọ́ December 1 àti Jí! October-December. Ṣàlàyé ṣókí nípa àwọn ìwé ìròyìn náà, kó o wá ní kí àwùjọ sọ èyí tí wọ́n rò pé ó le fani mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ní kí wọ́n sọ àwọn ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi nasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn. Ṣàṣefihàn bí wọ́n ṣe lè lo ọ̀kan lára àwọn àbá tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ní kí alàgbà kan ṣàṣefihàn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ ṣókí kan tó ti múra sílẹ̀, kó lo àpilẹ̀kọ tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu.
Orin 208
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 1
Orin 84
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù November sílẹ̀.
15 mi: “Kíkọ́ Àwọn Ibi Ìjọsìn Lọ́nà Tó Mọ Níwọ̀n Ń Fìyìn fún Jèhófà.”e Ìpínrọ̀ 9 sí 14, àti àpótí tó wà lójú ìwé 5 àti 6. Akọ̀wé ìjọ ni kó bójú tó apá yìí. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 12, rán àwọn ará létí pé àwọn náà ti ṣe ìpinnu tó jọ èyí nígbà kan. Gbóríyìn fáwọn ará láwọn apá ibi tí wọ́n ti ṣe dáadáa, nípa mímú ìpinnu wọn ṣẹ. Sọ ohun tí wọ́n tún lè ṣe láti fowó ṣètìlẹ́yìn tàbí láti máa bójú tó àwọn ibi ìjọsìn wa.
20 min: “Ran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́ Láti Fara Da Àtakò.”f Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2, ní ṣókí sọ bí àlàyé tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ta Ni Wọ́n Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́? ojú ìwé 27 sí 31 ṣe lè ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn mọ̀lẹ́bí àti ọ̀rẹ́ lè bi wọ́n.
Orin 105
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
f Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.