Iṣẹ́ Ìwàásù Gba Ìfaradà
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbádùn iṣẹ́ ajíhìnrere tó ṣe fún ohun tó lé lọ́gbọ̀n ọdún. Báwọn iṣẹ́ àṣegbádùn míì téèyàn máa ń ṣe ṣe láwọn ìpèníjà tiẹ̀ náà niṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù ṣe láwọn ìpèníjà. (2 Kọ́r. 11:23-29) Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù kò juwọ́ sílẹ̀. (2 Kọ́r. 4:1) Ó mọ̀ pé Jèhófà ló máa fóun lágbára tóun á fi fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun. (Fílí. 4:13) Àpẹẹrẹ àtàtà ni Pọ́ọ̀lù jẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ ká fara da ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù láìyẹsẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi lè sọ pé: “Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.”—1 Kọ́r. 11:1.
2 Bá A Ṣe Lè Fara Da Àdánwò Lónìí: Ojoojúmọ́ làwọn arákùnrin wa ń kojú ìfiṣẹ̀sín, àtakò tàbí ìdágunlá látọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ wọn. (Mát. 10:35; Jòh. 15:20) Ó sì lè jẹ́ bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn. Yàtọ̀ síyẹn, ó lè jẹ́ ìṣòro àìsàn lò ń bá yí tàbí kó jẹ́ pé ńṣe lò ń sapá láti borí ohun tó ń pín ọkàn níyà tàbí tó ń dán ìgbàgbọ́ àti ìfaradà rẹ wò. Bá a bá ń ronú nípa àwọn èèyàn tó fòótọ́ sin Ọlọ́run nígbàanì àtàwọn Kristẹni òde òní tó kojú ìpèníjà tó sì borí rẹ̀, èyí á fún wa lókun láti fara da ìpèníjà.—1 Pét. 5:9.
3 Bá a bá rí i dájú pé a “gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀.” a máa lágbára láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ. (Éfé. 6:10-13, 15) Ó sì tún ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ ká lè fara dà á. Ọlọ́run máa ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ká bàa lè fara da àdánwò. (2 Kọ́r. 6:4-7) Ká bàa lè borí ogun tẹ̀mí tá à ń jà, a gbọ́dọ̀ kọbi ara sí àwọn ìránnilétí Ọlọ́run ká bàa lè máa lókun nípa tẹ̀mí. (Sm. 119:24, 85-88) Bí ọmọ kan ṣe lè máa ka lẹ́tà tí bàbá tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ kọ sí i ní àkàtúnkà, bẹ́ẹ̀ náà ni kíka Bíbélì lójoojúmọ́ ṣe máa jẹ́ kí àjọṣe àwa àti Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i. Bá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, à máa ní ọgbọ́n tá a fi máa kojú àdánwò, a ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ìrònú Ọlọ́run máa darí àwọn ìpinnu wa, kó sì fún ìwà títọ́ wa lókun.—Òwe 2:10, 11.
4 Ìfaradà Ń Mú Ìbùkún Wá: Bó ṣe rí nínú ọ̀rọ̀ ti Pọ́ọ̀lù, fífara da ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa pẹ̀lú ìṣòtítọ́ ń múnú Jèhófà dùn, ó sì tún jẹ́ ìbùkún fún àwa àtàwọn ẹlòmíì. (Òwe 27:11) Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ò ní juwọ́ sílẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ká lè fi hàn pé ìgbàgbọ́ tí kì í yẹ̀ la ní àti pé ‘ó níye lórí púpọ̀púpọ̀ ju wúrà tí ń ṣègbé láìka fífi tí a fi iná dán an wò sí.’—1 Pét. 1:6, 7.