Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, àmọ́ ṣó o ti béèrè rí pé kí ni Ìjọba Ọlọ́run, kí ló sì ń bọ̀ wá ṣe?
WO OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ:
Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?
Ó jẹ́ ìjọba kan ní ọ̀run, Jésù Kristi sì ni Ọba Ìjọba náà.—Àìsáyà 9:6, 7; Mátíù 5:3; Lúùkù 1:31-33.
Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe?
Ó máa fòpin sí gbogbo nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé, á sì mú àlàáfíà ayérayé wá fún àwọn tó wà láyé.—Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10.
Kí ló túmọ̀ sí láti máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́?
Ó túmọ̀ sí pé ká máa ti Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn, ká sì gbà pé òun nìkan ló lè mú kí ayé rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́.—Mátíù 6:33; 13:44.