Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Ń Jẹ́ Ká Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
1. Kí ni ìfẹ́ tí Jésù ní fún Ọlọ́run sún un láti ṣe?
1 Ìfẹ́ ló sún Jésù láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Gbogbo ohun tó ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ fi hàn kedere pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Jésù sọ pé: “Nítorí kí ayé lè mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Baba, àní gẹ́gẹ́ bí Baba ti fi àṣẹ fún mi láti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni mo ń ṣe.” (Jòh. 14:31) Níwọ̀n bí a ti ń tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù, a láǹfààní láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run nínú ọ̀nà tá a gbà ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.— Mát. 22:37; Éfé. 5:1, 2.
2. Ipa wo ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ń ní lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
2 “Kí Orúkọ Rẹ Di Sísọ Di Mímọ́”: Bá a ṣe ń fìtara lo gbogbo àǹfààní tá a ní láti sọ fáwọn èèyàn nípa Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀, ṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ipa ti wa nínú sísọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. (Sm. 83:18; Ìsík. 36:23; Mát. 6:9) Bíi ti Jésù, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa máa ń fi hàn pé tọkàntọkàn la fi fẹ́ kí orúkọ Jèhófà di mímọ́ kí ìfẹ́ rẹ̀ sì di ṣíṣe.— Mát. 26:39.
3. Báwo ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro?
3 Ìfẹ́ Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Borí Ìṣòro: Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà lágbára ju gbogbo ìṣòro tó lè fẹ́ dí wa lọ́wọ́. (1 Kọ́r. 13:4, 7) Nígbà tí Jésù wà láyé, ó kojú àwọn ìṣòro kan tí ì bá dí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́. Àmọ́, nítorí ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú tó sì wù ú láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀, ó borí àwọn ìṣòro tó dojú kọ ọ́. (Máàkù 3:21; 1 Pét. 2:18-23) Àwa náà ń kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro, ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí wọn. Bá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi pẹ́kípẹ́kí, ọkàn wa á balẹ̀, a ò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àtakò látọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí, àìlera, ara tó ń dara àgbà, tàbí ìdágunlá táwọn èèyàn máa ń ṣe sí wa lè dùn wá, kì í dí wa lọ́wọ́ láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nípa ṣíṣe ìṣẹ́ òjíṣẹ́ wa dójú àmì.
4. Àǹfààní wo ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà mú ká a ní?
4 Ìfẹ́ lágbára gan-an ni, àǹfààní ńlá ló sì jẹ́ pé a lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run dénú nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (1 Kọ́r. 13:13) Bí àkókò tí orúkọ Jèhófà máa di sísọ di mímọ́ títí láé ṣe ń yára sún mọ́lé, ǹjẹ́ ‘kí ìfẹ́ wa lè túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú.’—Fílí. 1:9; Mát. 22:36-38.