Ànímọ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Tó Yẹ Kí Olùkọ́ Tó Dáńgájíá Ní
1. Ànímọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ wo ló yẹ kí olùkọ́ tó dáńgájíá ní?
1 Tó bá dọ̀rọ̀ ká kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí ló ń mú kí ẹnì kan jẹ́ olùkọ́ tó dáńgájíá? Ṣé bó ṣe kàwé tó ni? Ṣé bó ṣe ti pẹ́ tó nínú òtítọ́ ni? Ṣé àwọn ẹ̀bùn àbínibí rẹ̀ ni? Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ànímọ́ tó mú gbogbo Òfin ṣẹ ni, èyí táwọn èèyàn fi ń dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ̀, tó sì tún jẹ́ ànímọ́ tó gbawájú tó sì fani mọ́ra jù lọ lára àwọn ànímọ́ pàtàkì tí Jèhófà ní. (Jòh. 13:35; Gál. 5:14; 1 Jòh. 4:8) Ìfẹ́ ni. Olùkọ́ tó dáńgájíá máa ń fi hàn pé òun ní ìfẹ́.
2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn?
2 Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn: Jésù, Olùkọ́ Ńlá Náà, fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, èyí sì mú kí wọ́n fetí sí i. (Lúùkù 5:12, 13; Jòh. 13:1; 15:13) Tá a bá bìkítà fún àwọn èèyàn, a ó máa wàásù ní gbogbo ìgbà tí àyè bá ṣí sílẹ̀. Àwọn ohun ìdènà bí inúnibíni àti ìdágunlá kò ní mú ká rẹ̀wẹ̀sì. A ó máa fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn tá à ń wàásù fún jẹ wá lógún, a ó sì jẹ́ kí ọ̀nà tá à ń gbà bá wọn sọ̀rọ̀ bá ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn mu. A ó sì máa fara balẹ̀ nígbà tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti nígbà tá a bá ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀.
3. Báwo ni ìfẹ́ tá a ní sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?
3 Nífẹ̀ẹ́ Ẹ̀kọ́ Bíbélì: Jésù tún nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì, ó sì kà á sí ìṣúra iyebíye. (Mát. 13:52) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, a ó máa fi ìtara sọ̀rọ̀, èyí sì lè mú káwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ náà. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ á jẹ́ ká pọkàn pọ̀ sórí ìsọfúnni pàtàkì tá a fẹ́ kí wọ́n gbọ́, dípò tí a ó fi máa ronú nípa ibi tá a kù sí, a ò sì ní fi bẹ́ẹ̀ máa bẹ̀rù lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
4. Báwo la ṣe lè dẹni tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn?
4 Ní Ìfẹ́: Báwo la ṣe lè dẹni tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ronú nípa ìfẹ́ tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ fi hàn sí wa àti ipò tó burú tí àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa wà nípa tẹ̀mí. (Máàkù 6: 34; 1 Jòh. 4:10, 11) Ìfẹ́ tá a ní fún ẹ̀kọ́ Bíbélì máa túbọ̀ jinlẹ̀ tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé tá a sì ń ṣe àṣàrò. Ìfẹ́ jẹ́ apá kan lára èso tẹ̀mí. (Gál. 5:22) Torí náà, a lè rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, kó sì ràn wá lọ́wọ́ kí ìfẹ́ wa lè jinlẹ̀ sí i. (Lúùkù 11:13; 1 Jòh. 5:14) Láìka ti bá a ṣe kàwé tó, bá a ṣe ti pẹ́ tó nínú òtítọ́ tàbí ẹ̀bùn àbínibí yòówù ká ní sí, tá a bá ń fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, a lè jẹ́ olùkọ́ tó dáńgájíá, tó bá dọ̀rọ̀ ká kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.