Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Sefanáyà
1. Báwo ni ipò nǹkan ṣe rí nígbà tí Sefanáyà ń sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì, báwo ló sì ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa lónìí?
1 Ní nǹkan bí àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta [650] ọdún ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìjọsìn Báálì gbòde kan ní ilẹ̀ Júdà. Wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa Ámọ́nì Ọba búburú ni, Jòsáyà Ọba tó jẹ́ ọ̀dọ́ sì ti ń jọba báyìí. (2 Kíró. 33:21–34:1) Láàárín ìgbà yẹn ni Jèhófà ní kí Sefanáyà lọ kéde ọ̀rọ̀ ìdájọ́ òun. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ìdílé tó ń jọba ní ilẹ̀ Júdà ní wọ́n bí i sí, síbẹ̀ ó jíṣẹ́ ìdálẹ́bi tí Jèhófà rán an sáwọn aṣáájú Júdà. (Sef. 1:1; 3:1-4) Àwa náà ń sapá ká lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgboyà Sefanáyà, a ò sì ní jẹ́ kí àjọṣe àárín àwa àti ìdílé wa bá ìjọsìn wa sí Jèhófà jẹ́. (Mát. 10:34-37) Iṣẹ́ wo ní Sefanáyà jẹ́, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
2. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Jèhófà lè pa wá mọ́ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀?
2 Ẹ Wá Jèhófà: Jèhófà nìkan ló lè gbani là ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Sefanáyà fi rọ àwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà pé kí wọ́n wá Jèhófà, kí wọ́n wá òdodo, kí wọ́n sì wá ọkàn-tútù kó tó pẹ́ jù. (Sef. 2:2, 3) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lákòókò tiwa. Bí i ti Sefanáyà, à ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá Jèhófà, àmọ́ àwa náà gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀, ká pinnu pé a ò ní “fà sẹ́yìn kúrò ní títọ Jèhófà lẹ́yìn” láé. (Sef. 1:6) Tá a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Jèhófà, tá a sì gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà rẹ̀, èyí á fi hàn pé à ń wá Jèhófà. À ń wá òdodo nípa gbígbé ìgbésí ayé oníwà mímọ́. À ń wá ọkàn-tútù tá a bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti nípa fífi tinútinú ṣègbọràn sí ìtọ́ni tó wá látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run.
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lẹ́mìí tó dáa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?
3 Àbájáde rere: Ìdájọ́ tí Sefanáyà kéde yẹn wọ àwọn kan lára àwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà lọ́kàn, àmọ́ ní pàtàkì, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ náà wọ Jòsáyà tó jẹ́ ọ̀dọ́ lọ́kàn tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá Jèhófà nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé. Lẹ́yìn náà, Jòsáyà fi gbogbo agbára rẹ̀ gbógun ti ìbọ̀rìṣà ní ilẹ̀ náà. (2 Kíró. 34:2-5) Lóde òní, bó tílẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára irúgbìn Ìjọba Ọlọ́run bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, orí àpáta tàbí sáàárín àwọn ẹ̀gún, àwọn míì náà bọ́ sórí erùpẹ̀ àtàtà, wọ́n sì ń so èso. (Mát. 13:18-23) Ó dá wa lójú pé Jèhófà á túbọ̀ máa bù kún ìsapá wa bí a ṣe ń jẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú títan irúgbìn Ìjọba náà kálẹ̀.—Sm. 126:6.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká ‘máa wà ní ìfojúsọ́nà fún Jèhófà’?
4 Àwọn kan nílẹ̀ Júdà rò pé Jèhófà kì yóò gbé ìgbésẹ̀ láé. Àmọ́ Jèhófà fi dá wọn lójú pé ọjọ́ ńlá òun sún mọ́lé. (Sef. 1:12, 14) Kìkì àwọn tó bá sá di Jèhófà nìkan ló máa rí ìgbàlà. (Sef. 3:12, 17) Bí a ṣe ń ‘fojú sọ́nà fún Jèhófà,’ ẹ jẹ́ ká máa fi ìdùnnú sin Ọlọ́run wa gíga jù lọ níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa.—Sef. 3:8, 9.