Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Hábákúkù
1. Báwo lọ̀rọ̀ àwa àti wòlíì Hábákúkù ṣe jọra?
1 Bá a ṣe ń rí bí ìwà ibi ṣe ń gbèrú sí i láyé, ó lè máa ṣe wá bíi ti Hábákúkù tó bi Jèhófà pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi mú kí n rí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, tí ìwọ sì ń wo èkìdá ìdààmú?” (Háb. 1:3; 2 Tím. 3:1, 13) Tá a ba ń ronú lórí ọ̀rọ̀ Hábákúkù, tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ rẹ̀, èyí á máa fún wa lókun bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà.—2 Pét. 3:7.
2. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ olóòótọ́?
2 Jẹ́ Olóòótọ́: Dípò tí Hábákúkù á fi jẹ́ kí àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a, ńṣe ló túbọ̀ wà lójúfò nípa tẹ̀mí, tó sì ń bá iṣẹ́ wòlíì rẹ̀ lọ. (Háb. 2:1) Jèhófà fi í lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀rọ̀ Òun máa tó ṣẹ àti pé ‘olódodo yóò máa wà láàyè nìṣó nípa ìṣòtítọ́ rẹ̀.’ (Háb. 2:2-4) Kí lèyí túmọ̀ sí fún àwa Kristẹni tá à ń gbé ní àkókò tí òpin ti sún mọ́lé gan-an yìí? Ìdánilójú tá a ní pé òpin máa dé ṣe pàtàkì ju ìgbà tí òpin máa dé lọ. Ìgbàgbọ́ máa ń jẹ́ ká wà lójúfò, ká sì máa fi iṣẹ́ ìwàásù sí ipò àkọ́kọ́.—Héb. 10:38, 39.
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ìdùnnú sin Jèhófà?
3 Máa Yọ Ayọ̀ Ńláǹlà Nínú Jèhófà: Nígbà tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá gbógun tí àwa èèyàn Jèhófà, èyí máa dán ìgbàgbọ́ wa wò. (Ìsík. 38:2, 10-12) Ogun máa ń fa ìnira, kódà fáwọn tó bá ṣẹ́gun lẹ́yìn-ọ̀-rẹ́yìn pàápàá. Ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ lè wà, a lè pàdánù dúkìá, sànmánì sì lè lọ́ tín-ín-rín fún wa. Tí irú àwọn ìṣòro yìí bá dé, kí la máa ṣe? Torí pé Hábákúkù ń retí ìṣòro, ó pinnu pé òun á máa bá a lọ ní fífi ayọ̀ sin Jèhófà. (Háb. 3:16-19) “Ìdùnnú Jèhófà” máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò ọjọ́ iwájú.—Neh. 8:10; Héb. 12:2.
4. Ayọ̀ wo lá máa ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú?
4 Jèhófà á máa bá a lọ láti kọ́ àwọn tó bá la ọjọ́ ìdájọ́ rẹ̀ tó ń bọ̀ já ní ọ̀nà ìgbésí ayé tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Háb. 2:14) Àwọn tí Ọlọ́run bá jí dìde náà máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká máa lo gbogbo àǹfààní tá a bá ní láti sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ìṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ fáwọn èèyàn!—Sm. 34:1; 71:17.