ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 38-42
Inú Jèhófà Máa Ń Dùn Tá A Bá Gbàdúrà Fáwọn Ẹlòmíì
Jèhófà sọ pé kí Jóòbù gbàdúrà fún Élífásì, Bílídádì àti Sófár
Jèhófà sọ fún Élífásì, Bílídádì àti Sófárì pé kí wọ́n lọ bá Jóòbù pé kó rú ẹbọ sísun fún wọn
Jèhófà fẹ́ kí Jóòbù gbàdúrà fún wọn
Jèhófà bù kún Jóòbù lẹ́yìn tó gbàdúrà fún wọn
Jèhófà bù kún Jóòbù lọ́pọ̀lọpọ̀ torí ìgbàgbọ́ àti ìfaradà rẹ̀
Jèhófà mú ìpọ́njú Jóòbù kúrò, ó sì jẹ́ kó ní ìlera pípé
Àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Jóòbù tù ú nínú lọ́nà tó yẹ torí gbogbo nǹkan tí ojú rẹ̀ ti rí
Jèhófà jẹ́ kí Jóòbù ní ọrọ̀, ó fún un ní ìlọ́po méjì àwọn ohun tó pàdánù
Jóòbù àti ìyàwó rẹ̀ ní àwọn ọmọ mẹ́wàá míì
Jóòbù tún lo ogóje ọdún [140] míì láyé, ó sì wá rí ìran àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ mẹ́rin