ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 79-86
Ta Ló Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ?
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àtọmọdọ́mọ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Léfì tó ń jẹ́ Ásáfù ló kọ Sáàmù 83, ó sì gbé ayé lákòókò kan náà pẹ̀lú Dáfídì Ọba. Àkókò tí àwọn orílẹ̀-èdè gbìmọ̀ pọ̀ láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́ ló kọ sáàmù yìí.
Kàkà tí ì bá fi máa gbàdúrà nípa ààbò ti ara rẹ̀, ohun tí àdúrà rẹ̀ dá lé ni orúkọ Jèhófà àti ipò ọba aláṣẹ rẹ̀
Lóde òní, ìgbà gbogbo làwọn èèyàn ń ta ko àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́, tá a sì ń lo ìfaradà ńṣe là ń bọlá fún Jèhófà
Jèhófà fẹ́ ká mọ orúkọ òun
O yẹ kó máa hàn nínú ìwà àti ìṣe wa pé Jèhófà ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé wa