July 25 Sí 31
SÁÀMÙ 79-86
Orin 138 àti Àdúrà
Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
“Ta Ló Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ?”: (10 min.)
Sm 83:1-5—Orúkọ Jèhófà àti ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ ló yẹ kó jẹ wá lógún jù lọ (w08 10/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 7 àti 8)
Sm 83:16—Ìdúróṣinṣin àti ìfaradà wa ń bọlá fún Jèhófà (w08 10/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 16)
Sm 83:17, 18—Jèhófà ni Ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé àtọ̀run (w11 5/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1 àti 2; w08 10/15 ojú ìwé 15 àti 16 ìpínrọ̀ 17 àti 18)
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)
Sm 79:9—Kí ni ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn àdúrà wa? (w06 7/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 5)
Sm 86:5—Lọ́nà wo ni Jèhófà gbà “ṣe tán láti dárí jini”? (w06 7/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 9)
Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?
Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?
Bíbélì Kíkà: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Sm 85:8–86:17
MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ
Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg ẹ̀kọ́ 7 ìpínrọ̀ 1
Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg ẹ̀kọ́ 7 ìpínrọ̀ 3
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) fg ẹ̀kọ́ 7 ìpínrọ̀ 7 àti 8
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣé Ọlọ́run ní Orúkọ?: (15 min.) Jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ wo fídíò Ṣé Ọlọ́run ní Orúkọ? yìí, ó wà lórí ìkànnì jw.org. (Wo abẹ́ ÀWỌN ÌTẸ̀JÁDE > ÀWỌN ÌWÉ ŃLÁ ÀTÀWỌN ÌWÉ PẸLẸBẸ. Lẹ́yìn náà, lọ síbi tí ìwé Ìròyìn Ayọ̀ wà, kó o sì ṣí i. Wàá rí fídíò náà lábẹ́ ẹ̀kọ́ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ta Ni Ọlọ́run?”) Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Báwo la ṣe lè lo fídíò yìí tá a bá ń jẹ́rìí fún àwọn èèyàn lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà, níbi tí àwọn èèyàn pọ̀ sí àti láti ilé-dé-ilé? Àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni wo lẹ ní nígbà tẹ́ ẹ lo fídíò yìí?
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: (30 min.) ia orí 20 ìpínrọ̀ 14 sí 26 àti àtúnyẹ̀wò tó wà lójú ìwé 179
Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)
Orin 143 àti Àdúrà
Ìránnilétí: Jọ̀wọ́ jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ gbọ́ orin tuntun yìí lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn náà, kí ẹ kọ ọ́.