ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 74-78
Máa Rántí Àwọn Iṣẹ́ Jèhófà
Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe
Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí á jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì oúnjẹ tẹ̀mí dáadáa
Tá a bá ń ronú jinlẹ̀ nípa Jèhófà, a ò ní gbàgbé àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ àtàwọn ohun tó ṣèlérí fún wa
Ara àwọn iṣẹ́ Jèhófà ni:
Àwọn ohun tó dá
Bá a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe túbọ̀ máa rí i pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba
Àwọn ọkùnrin tó yàn láti máa bójú tó ìjọ
Ó yẹ ká máa tẹrí ba fún àwọn tí Jèhófà yàn láti máa múpò iwájú nínú ètò rẹ̀
Bó ṣe ń gba àwọn èèyàn rẹ̀ là
Tá a bá ń rántí bí Jèhófà ṣe ń gbà àwọn èèyàn rẹ̀ là, èyí á fún ìgbàgbọ́ wa lókun pé ó wu Jèhófà láti bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀