ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 26-33
Bẹ Jèhófà Pé Kó Jẹ́ Kó O Ní Ìgboyà
Dáfídì túbọ̀ ní ìgboyà nígbà tó rántí bí Jèhófà ṣe gbà á sílẹ̀ láwọn ìgbà kan
Jèhófà gba Dáfídì sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún nígbà tó wà lọ́mọdé
Jèhófà jẹ́ kí Dáfídì pa béárì kan kó lè dáàbò bo agbo ẹran rẹ̀
Jèhófà ti Dáfídì lẹ́yìn nígbà tó pa Gòláyátì
Kí ló máa jẹ́ ká ní ìgboyà bíi ti Dáfídì?
Àdúrà
Iṣẹ́ ìwàásù
Lílọ sí ìpàdé
Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìjọsìn ìdílé
Fífún àwọn ẹlòmíì níṣìírí
Ká máa rántí bí Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láwọn ìgbà kan