ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 17 SÍ 23
Àṣẹ Máa Ń Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹni Tó Bá Ń Ṣi Agbára Lò
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ṣẹ́bínà ni ìríjú “tí ń ṣe àbójútó ilé,” Ọba Hesekáyà. Òun ni igbákejì ọba, ó sì ní ọ̀pọ̀ ojúṣe láti bójú tó.
Ó yẹ kí Ṣẹ́bínà pèsè ohun táwọn èèyàn Jèhófà nílò
Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan ńláńlá ló ń wá fún ara rẹ̀
Jèhófà fi Élíákímù rọ́pò Ṣẹ́bínà
Ọlọ́run sọ pé òun máa fún Élíákímù ní “kọ́kọ́rọ́ ilé Dáfídì,” èyí to fi hàn pé Ọlọ́run máa gbé agbára àti àṣẹ wọ Élíákímù
Rò ó wò ná: Báwo ni Ṣẹ́bínà ì bá ṣe lo ipò tó wà kó lè ran àwọn míì lọ́wọ́?