ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 22-24
Ǹjẹ́ O Ní ‘Ọkàn-àyà Láti Mọ’ Jèhófà?
Jèhófà fi àwọn èèyàn wé èso ọ̀pọ̀tọ́
Àwọn olóòótọ́ lára àwọn tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Bábílónì dà bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tó dára
Sedekáyà Ọba tó jẹ́ aláìṣòótọ́ àtàwọn míì tó hùwà búburú dà bí èso àjàrà tí kò dára
Báwo la ṣe lè ní ‘ọkàn-àyà láti mọ’ Jèhófà?
Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń fi ohun tá a kọ́ sílò, Jèhófà máa fún wa ní “ọkàn-àyà láti mọ̀” ọ́n
A gbọ́dọ̀ yẹ ọkàn wa wò dáadáa, ká sì mú àwọn ìwà tí kò dára àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ kúrò níbẹ̀