ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 32-34
Iṣẹ́ Ńlá Ni Iṣẹ́ Olùṣọ́
Àwọn olùṣọ́ sábà máa ń dúró sórí ògiri ìlú tàbí òkè ilé gíga kí wọ́n lè tètè kìlọ̀ fáwọn ará ìlú tí nǹkan aburú bá fẹ́ wọ inú ìlú. Jèhófà yan Ìsíkíẹ́lì lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti jẹ́ ‘olùṣọ́ fún ilé Ísírẹ́lì.’