ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp20 No. 3 ojú ìwé 14-15
  • Ẹlẹ́dàá Wa Máa Bù Kún Ẹ Títí Láé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹlẹ́dàá Wa Máa Bù Kún Ẹ Títí Láé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Jésù Kí Lo Lè Rí Kọ́ Látinú Wọn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Kí La Rí Kọ́ Nínú Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Tí Jésù Ṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ó Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ṣé Òótọ́ Ni Iṣẹ́ Ìyanu Ń Ṣẹlẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
wp20 No. 3 ojú ìwé 14-15
Àwọn èèyàn tó wá látinú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń gbádùn ara wọn nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.

“Ilẹ̀ yóò mú èso jáde; Ọlọ́run, àní Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.”​—SÁÀMÙ 67:6

Ẹlẹ́dàá Wa Máa Bù Kún Ẹ Títí Láé

Ọlọ́run ṣèlérí fún Ábúráhámù pé ọ̀kan lára àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ló máa mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá fún “gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Ta ni àtọmọdọ́mọ yẹn?

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run fún Jésù tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ní agbára láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yẹn fi hàn pé àwọn orílẹ̀-èdè máa rí ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí fún Ábúráhámù gbà nípasẹ̀ Jésù​—Gálátíà 3:14.

Àwọn ìṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé òun ni Ọlọ́run yàn láti bù kún aráyé, wọ́n tún jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe máa lo Jésù láti bù kún aráyé títí láé. Kíyè sí bí àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù ṣe jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ tó fani mọ́ra.

Ìwà tútù​—Jésù wo àwọn aláìsàn.

Ìgbà kan wà tí adẹ́tẹ̀ kan bẹ Jésù pé kó wo òun sàn. Jésù fọwọ́ kàn án, ó sì sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà kúrò lára rẹ̀.​—Máàkù 1:​40-42.

Ìwà ọ̀làwọ́​—Jésù bọ́ àwọn tí ebi ń pa.

Jésù ò fẹ́ kí ebi máa pa àwọn èèyàn. Láwọn ìgbà kan, Jésù fi iṣẹ́ ìyanu bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, ó sọ búrẹ́dì díẹ̀ àti ẹja kékeré mélòó kan di púpọ̀. (Mátíù 14:​17-21; 15:​32-38) Gbogbo wọn jẹ àjẹyó, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ ló sì ṣẹ́ kù.

Àánú​—Jésù jí òkú dìde.

Opó kan ń ṣọ̀fọ̀ ọmọkùnrin rẹ̀ kan ṣoṣo tó kú, kò sì ní ẹlòmíì tó máa tọ́jú rẹ̀. “Àánú rẹ̀ ṣe” Jésù, ló bá jí ọmọ náà dìde.​—Lúùkù 7:​12-15.

ỌLỌ́RUN MÁA BÙ KÚN ARÁYÉ TÍTÍ LÁÉ

Àwọn ohun tí Jésù ṣe fi hàn pé Ọlọ́run ní agbára láti bù kún aráyé. Láìpẹ́, nígbà tí Jésù bá dé bó ṣe ṣèlérí, Olódùmarè máa lò ó láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá kárí ayé, èyí tó máa ju ohun tó ṣe nígbà tó wá sáyé lọ!

Báwo ni nǹkan ṣe máa rí láyé nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ? Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún un ni “yóò jogún ayé, inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.” (Sáàmù 37:11) “Ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”​—Ìfihàn 21:4.

Ẹ ò rí bí ìbùkún náà ṣe máa pọ̀ tó tá a bá ń gbé ayé títí láé nínú àlàáfíà! Tó o bá fẹ́ kọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa bí Ọlọ́run ṣe máa bù kún aráyé láìpẹ́ nípasẹ̀ àkóso Jésù, a rọ̀ ẹ́ pé kó o lọ sórí ìkànnì www.jw.org.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́