ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁÀKÙ 11-12
Ó Fi Púpọ̀ Sí I Ju Àwọn Tó Kù Lọ
Báwo ni ìtàn tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe kọ́ wa ní àwọn ẹ̀kọ́ yìí?
Jèhófà mọ rìrì gbogbo ìsapá wa
Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà
Má ṣe fi ohun tó o lè ṣe wéra pẹ̀lú tàwọn ẹlòmíì tàbí ohun tó o ti ṣe tẹ́lẹ̀
Kò yẹ káwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ fà sẹ́yìn láti fúnni ní nǹkan kódà kí ohun tó wà lọ́wọ́ wọn má tó nǹkan
Àwọn ẹ̀kọ́ míì wo lo tún kọ́?