MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Ká Má Dá Sí Ọ̀ràn Òṣèlú? (Mík 4:2)
Àpèjúwe ará Samáríà ràn wa létí pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú àti pé ó fẹ́ “kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn” tó fi mọ́ àwọn tí ipò, ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ sí tiwa.—Ga 6:10; Iṣe 10:34.
WO FÍDÍÒ NÁÀ KÍ NÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ PÉ KÁ MÁ DÁ SÍ Ọ̀RÀN ÒṢÈLÚ? (MÍK 4:2), KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo la ṣe mọ̀ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní ni Míkà 4:2 ń ṣàpèjúwe rẹ̀?
Kí ló túmọ̀ sí láti má ṣe dá sí tọ̀túntòsì, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì?
Báwo ni Ìṣípayá 13:16, 17 ṣe jẹ́ ká mọ bí ètò òṣèlú ayé yìí ṣe ń gbìyànjú láti nípa lórí ìrònú wa àti ìwà wa?
Àwọn nǹkan mẹ́ta wo ló lè mú kí àìdásí tọ̀túntòsì wa yingin?