MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ọmọ Onínàákúnàá Pa Dà Wálé
JẸ́ KÍ ÀWỌN ARÁ WO FÍDÍÒ ỌMỌ ONÍNÀÁKÚNÀÁ PA DÀ WÁLÉ, LẸ́YÌN NÁÀ, KÍ WỌ́N DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo la ṣe mọ̀ pé àjọṣe tí David ní pẹ̀lú Jèhófà ti ń jó rẹ̀yìn, báwo sì làwọn ìdílé rẹ̀ àtàwọn alàgbà ṣe gbìyànjú láti ràn án lọ́wọ́?
Àwọn ọ̀nà wo ni Arákùnrin àti Arábìnrin Barker gbà jẹ́ àpẹẹrẹ rere gẹ́gẹ́ bí òbí?
Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni fídíò yìí kọ́ wa nípa . . .
kéèyàn máa fi gbogbo àkókò rẹ̀ ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà?
kíkó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́?
fífetí sí ìmọ̀ràn?
ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì?