ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | TÍTÙ 1–FÍLÉMÓNÌ
“Ẹ Yan Àwọn Alàgbà”
Pọ́ọ̀lù sọ fún Títù pé kó “yan àwọn alàgbà láti ìlú dé ìlú.” Àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì yìí làwọn alábòójútó àyíká máa ń tẹ̀ lé tí wọ́n bá fẹ́ yan àwọn arákùnrin sípò nínú ìjọ.
ÌGBÌMỌ̀ OLÙDARÍ
Àpẹẹrẹ tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi lélẹ̀ ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí tòde òní ń tẹ̀ lé, wọ́n fa iṣẹ́ bàǹtàbanta lé àwọn alábòójútó àyíká lọ́wọ́, pé kí wọ́n yan àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.
ÀWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ
Alábòójútó àyíká kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ gbàdúrà, kí wọ́n sì fara balẹ̀ wo àwọn arákùnrin tí àwọn alàgbà dámọ̀ràn, kí wọ́n sì yan ẹni tó bá tóótun sípò.
ÀWỌN ALÀGBÀ
Lẹ́yìn tá a bá ti yan àwọn alàgbà sípò, wọ́n ṣì ní láti máa dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè.