ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÉMÍÌSÌ 1-2
Ohun Tó Ń Fa Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú
Tí èròkerò bá wá sí ẹ lọ́kàn, ṣe àwọn nǹkan yìí:
Sapá láti gbé e kúrò lọ́kàn, kó o sì máa ro nǹkan míì.—Flp 4:8
Ronú nípa àbájáde búburú tó máa tẹ̀yìn ẹ̀ yọ tó o bá lọ́wọ́ sí ìwàkiwà.—Di 32:29
Gbàdúrà.—Mt 26:41
Tí èròkerò bá sọ sí ẹ lọ́kàn, àwọn nǹkan rere wo lo lè ronú lé táá mú kó o gbé èròkerò náà kúrò lọ́kàn?