ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 9-11
“Èdè Kan Ni Gbogbo Ayé Ń Sọ”
Jèhófà mú kí àwọn èèyàn tó ṣàìgbọràn sí i fọ́n káàkiri nígbà tó da èdè wọn rú ní Bábélì. Àmọ́ lónìí, ó ń kó ogunlọ́gọ̀ èèyàn jọ látinú gbogbo orílẹ̀-èdè tí èdè wọn yàtọ̀ síra, ó sì ń mú kí wọ́n máa sọ “èdè mímọ́,” kí gbogbo wọn lè ‘máa pe orúkọ Jèhófà, kí wọ́n sì máa sìn ín ní ìṣọ̀kan’. (Sef 3:9; Ifi 7:9) Àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà tó wà nínú Bíbélì ló para pọ̀ di “èdè mímọ́” yìí.
Kéèyàn tó lè kọ́ èdè tuntun, ó gba pé kẹ́ni náà yí ọ̀nà tó ń gbà ronú pa dà sí ti èdè tuntun tó ń kọ́, kì í kàn ṣe pé kónítọ̀hún há àwọn ọ̀rọ̀ tuntun náà sórí. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú òtítọ́ tá à ń kọ́ látinú Bíbélì, ṣe ló máa ń jẹ́ ká yí èrò wa pa dà. (Ro 12:2) Bá a ṣe ń yí èrò wa pa dà ti mú káwa èèyàn Ọlọ́run wà níṣọ̀kan.—1Kọ 1:10.