ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb20 October ojú ìwé 8
  • Àkànṣe Ìwàásù Tá A Máa Ṣe ní Oṣù November Láti Kéde Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àkànṣe Ìwàásù Tá A Máa Ṣe ní Oṣù November Láti Kéde Ìjọba Ọlọ́run
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àkànṣe Ìwàásù Láti Kéde Ìjọba Ọlọ́run Lóṣù September
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Jẹ́ Káwọn Èèyàn Mọ̀ Pé Ayé Tuntun Ò Ní Pẹ́ Dé!
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Ohun Tá A Lè Bá Àwọn Èèyàn Sọ
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Pín Ìròyìn Ìjọba No. 35 Kiri Lọ́nà Gbígbòòrò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
mwb20 October ojú ìwé 8
Arákùnrin àti arábìnrin kan ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nídìí ìpàtẹ ìwé. ‘Ilé Ìṣọ́ ‘ No. 2 2020 wà nínú ọ̀kan lára ìpàtẹ ìwé náà.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àkànṣe Ìwàásù Tá A Máa Ṣe ní Oṣù November Láti Kéde Ìjọba Ọlọ́run

‘Ilé Ìṣọ́’ No. 2 2020 ní àkòrí náà ‘Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?’

Jésù wàásù “ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” (Lk 4:43) Ó tún kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí Ìjọba yẹn dé. (Mt 6:​9, 10) Lóṣù November, a máa ṣe ìkéde àkànṣe láti sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. (Mt 24:14) Ṣètò àkókò ẹ kíwọ náà lè kópa nínú iṣẹ́ yìí. Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù yẹn lè pinnu bóyá ọgbọ̀n (30) tàbí àádọ́ta (50) wákàtí ni wọ́n máa ròyìn.

O lè ka ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ronú nípa ẹ̀sìn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ń ṣe kó o tó yan ẹsẹ Bíbélì tó o máa kà. Tẹ́ni náà bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, fún un ní Ilé Ìṣọ́ No. 2 2020. Rí i pé o tètè pa dà sọ́dọ̀ ẹni náà, kó o sì fi ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀. Àsìkò díẹ̀ ló kù tí Ìjọba Ọlọ́run á fọ́ gbogbo àwọn tó ń ta kò ó. (Da 2:44; 1Kọ 15:​24, 25) Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu àkànṣe ìwàásù yìí ká lè fi hàn pé ọ̀dọ̀ Jèhófà la wà, a sì ń ṣojú fún Ìjọba rẹ̀!

Jésù jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀ lọ́run, ó sì ń jọba lórí Párádísè.

Ìjọba Ọlọ́run máa sọ ayé di Párádísè!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́