MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Hùwà Sáwọn Àgbà Obìnrin Bí Ìyá, Àwọn Ọ̀dọ́bìnrin Bí Ọmọ Ìyá
Bíbélì sọ pé ó yẹ ká máa hùwà sáwọn àgbàlagbà bíi pé bàbá àti ìyá wa ni wọ́n jẹ́, ká sì mú àwọn tó kéré sí wa bí àbúrò. (Ka 1 Tímótì 5:1, 2.) Ní pàtàkì, àwọn arákùnrin tún gbọ́dọ̀ máa bọlá fáwọn arábìnrin, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn.
Arákùnrin kan ò gbọ́dọ̀ máa sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kọ́kàn arábìnrin kan balẹ̀. (Job 31:1) Tí arákùnrin kan ò bá ní i lọ́kàn láti fẹ́ arábìnrin kan, kò gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tá mú kí arábìnrin yẹn rò pé ó fẹ́ fẹ́ òun.
Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ máa gba tàwọn arábìnrin rò, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn nígbàkigbà tí wọ́n bá béèrè ìbéèrè tàbí tí wọ́n bá sọ ohun tó yẹ káwọn alàgbà kíyè sí. Ní pàtàkì, ó tún yẹ káwọn alàgbà máa gba tàwọn arábìnrin tí ò lọ́kọ rò.—Rut 2:8, 9.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA FI ÌFẸ́ TÍ KÌ Í YẸ̀ HÀN SÁWỌN—OPÓ ÀTÀWỌN ỌMỌ ALÁÌNÍBABA, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo làwọn ará ṣe fìfẹ́ hàn sí Arábìnrin Myint?
Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ará abúlé rí ìfẹ́ táwọn ará fi hàn sí Arábìnrin Myint?
Báwo ni ìfẹ́ táwọn ará fi hàn sí Arábìnrin Myint ṣe ran àwọn ọmọ ẹ̀ lọ́wọ́?
Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà fìfẹ́ hàn sáwọn arábìnrin nínú ìjọ?