MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Kọ́ Agbára Ìfòyemọ̀ Rẹ
Àwọn tó ń sáré gbọ́dọ̀ máa ṣe ìdánrawò lóòrèkóòrè, kí iṣan ara wọn lè lágbára, kí wọ́n sì lè máa mókè nínú ìdíje. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ máa kọ́ agbára ìfòyemọ̀ wa ká lè máa ṣèpinnu tó tọ́. (Heb 5:14) Nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká ṣerú ìpinnu táwọn míì ṣe, àmọ́ àwa fúnra wa ló yẹ ká kọ́ bá a ṣe lè ronú jinlẹ̀ ká lè máa ṣèpinnu tó dáa. Kí nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé ẹnì kọ̀ọ̀kan lá jíhìn ìpinnu tó bá ṣe.—Ro 14:12.
Kò yẹ ká máa ronú pé ọjọ́ pẹ́ tá a ti ṣèrìbọmi, torí náà gbogbo ìgbà làá máa ṣèpinnu tó tọ́. Ká tó lè ṣèpinnu tó dáa, a gbọ́dọ̀ gbára lé Jèhófà pátápátá, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, ká sì fọkàn tán ètò Ọlọ́run.—Joṣ 1:7, 8; Owe 3:5, 6; Mt 24:45.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ “Ẹ DI Ẹ̀RÍ-ỌKÀN RERE MÚ,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Ìpinnu wo ló ṣòro fún Emma láti ṣe?
Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa gbé ìlànà tiwa kalẹ̀ lórí àwọn ìpinnu tó jẹ mọ́ ẹ̀rí ọkàn?
Ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n wo ni tọkọtaya kan fún Emma?
Ibo ni Emma ti rí ìsọfúnni tó ràn án lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó tọ́?