ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb22 May ojú ìwé 11
  • Kó Ara Ẹ Níjàánu Tí Èròkerò Bá Ń Wá Sí Ẹ Lọ́kàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kó Ara Ẹ Níjàánu Tí Èròkerò Bá Ń Wá Sí Ẹ Lọ́kàn
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Sìgá Mímu?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àwọn Ewu Wo Ló Wà Nínú Sìgá Mímu Tó Yẹ Kí N Mọ̀?
    Jí!—2011
  • Ojú Wo ni Ọlọ́run fi Ń Wo Sìgá Mímu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Báwo Lo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́?
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
mwb22 May ojú ìwé 11

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Kó Ara Ẹ Níjàánu Tí Èròkerò Bá Ń Wá Sí Ẹ Lọ́kàn

Aláìpé ni wá, torí náà léraléra ni èròkerò á máa wá sí wa lọ́kàn. Tá a bá fàyè gbà wọ́n, tá a sì jẹ́ kí wọ́n máa darí wa, a lè pàdánù ojúure Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ti jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé pọ̀ ju ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run lọ. Àwọn míì máa ń wá bí wọ́n á ṣe ní ìbálòpọ̀ láìka ìlànà Ọlọ́run sí rárá. (Ro 1:26, 27) Àwọn kan máa ń jẹ́ káwọn míì sún wọn ṣe ohun tí kò tọ́ káwọn èèyàn lè gba tiwọn.​—Ẹk 23:2.

Kí la lè ṣe tá ò fi ní gba èròkerò láyè nínú ọkàn wa? A gbọ́dọ̀ máa sapá láti ronú nípa àwọn ohun tí inú Jèhófà dùn sí. (Mt 4:4) Bákan náà, ó yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti gbé èròkerò kúrò lọ́kàn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà mọ ohun tó dáa jù fún wa, ó sì lè pèsè gbogbo ohun tá a nílò.​—Sm 145:16.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ SÌGÁ MÍMU LÈ BA AYÉ ÈÈYÀN JẸ́, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Apá kan nínú fídíò “Sìgá Mímu Lè Ba Ayé Èèyàn Jẹ́.” Ẹ̀rọ kan ń gbé sìgá sẹ́nu àwọn èèyàn.

    Kí nìdí táwọn kan fi máa ń mu sìgá?

  • Apá kan nínú fídíò “Sìgá Mímu Lè Ba Ayé Èèyàn Jẹ́.” Ẹ̀dọ̀fóró amusìgá kan ń wúkọ́.

    Àkóbá wo ni sìgá mímu lè ṣe fún ẹ?

  • Apá kan nínú fídíò “Sìgá Mímu Lè Ba Ayé Èèyàn Jẹ́.”Oníṣòwò ńlá kan ń fi sìgá tí wọ́n ń fi páìpù fà ṣe ìjẹ láti mú obìnrin kan.

    Kí nìdí tí sìgá mímu àti èyí tí wọ́n ń fi páìpù fà fi burú?​—2Kọ 7:1

  • Apá kan nínú fídíò “Sìgá Mímu Lè Ba Ayé Èèyàn Jẹ́.” Ọ̀dọ́bìnrin kan wà lórí òrùlé, ó sì ń wo bí ojú ọjọ́ ṣe mọ́lẹ̀ rekete.

    O lè kó ara ẹ níjàánu tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o mu sìgá!

    Kí lo lè ṣe tí wọ́n bá fi sìgá lọ̀ ẹ́? Kí lo sì lè ṣe tó o bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́