ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb23 July ojú ìwé 9
  • Wọ́n Ń Ṣiṣẹ́ Kára Nítorí Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Ń Ṣiṣẹ́ Kára Nítorí Wa
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fi Hàn Pé O Mọyì “Àwọn Ẹ̀bùn Tí Ó Jẹ́ Èèyàn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Gbogbo Wa Ló Yẹ Ká Máa Fúnra Wa Níṣìírí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • “Pọ́ọ̀lù Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Ọlọ́run Ó sì Mọ́kànle”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Àwọn Alábòójútó Arìnrìn Àjò—Àwọn Ẹ̀bùn Nínú Ènìyàn
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
mwb23 July ojú ìwé 9
Àwòrán: Alábòójútó àyíká kan ń bẹ ìjọ kan wò. 1. Ó ń darí ìpàdé iṣẹ́ ìwàásù. 2. Ó ń bá ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ṣèpàdé. 3. Ó ń bá àwọn ọ̀dọ́kùnrin ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Wọ́n Ń Ṣiṣẹ́ Kára Nítorí Wa

Àwọn alábòójútó àyíká àtìyàwó wọn máa ń ṣiṣẹ́ kára, wọ́n sì máa ń fi ara wọn jìn fáwọn ará. Torí pé ẹlẹ́ran ara bíi tiwa làwọn náà, ó máa ń rẹ̀ wọ́n nígbà míì. Àwọn ìgbà míì sì wà tí wọ́n máa ń ṣàníyàn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì. (Jem 5:17) Láì fìyẹn pè, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n máa ń ronú nípa bí wọ́n ṣe lè gba àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin láwọn ìjọ tí wọ́n ń bẹ̀ wò níyànjú. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ó yẹ ká máa fún àwọn alábòójútó àyíká ní “ọlá ìlọ́po méjì.”​—1Ti 5:17.

Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fẹ́ ṣèbẹ̀wò sáwọn ará ní Róòmù kó lè “fún [wọn] ní ẹ̀bùn ẹ̀mí,” inú ẹ̀ dùn torí ó mọ̀ pé àwọn jọ máa “fún ara [àwọn] ní ìṣírí.” (Ro 1:11, 12) Ṣé o mọ̀ pé ìwọ náà lè fún alábòójútó àyíká àtìyàwó ẹ̀ níṣìírí, ìyẹn tó bá níyàwó? Báwo lo ṣe lè ṣe é?

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÌGBÉSÍ AYÉ ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ TÓ LỌ SÌN NÍ ÌGBÈRÍKO KAN, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn ọ̀nà wo làwọn alábòójútó àyíká àtìyàwó wọn máa ń gbà fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn ará níjọ tí wọ́n ń bẹ̀ wò?

  • Ọ̀nà wo ni ìbẹ̀wò wọn ti gbà ṣe ẹ́ láǹfààní?

  • Kí la lè ṣe láti fún wọn níṣìírí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́