ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 42
ORIN 103 Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn
Máa Fi Hàn Pé O Mọyì “Àwọn Ẹ̀bùn Tí Ó Jẹ́ Èèyàn”
“Nígbà tó gòkè lọ sí ibi gíga . . . , ó fúnni ní àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn.”—ÉFÉ. 4:8.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa rí bí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àwọn alàgbà àtàwọn alábòójútó àyíká ṣe ń ràn wá lọ́wọ́. A tún máa rí bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì ohun táwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí ń ṣe fún wa.
1. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jésù ṣe fún wa?
KÒ SẸ́NÌ kankan láyé yìí tó lawọ́ bíi Jésù. Nígbà tó wà láyé, ọ̀pọ̀ ìgbà ló ṣiṣẹ́ ìyanu kó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. (Lúùkù 9:12-17) Àmọ́, ohun tá a mọyì jù ni bó ṣe fi ẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ fún wa. (Jòh. 15:13) Kódà lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó ṣì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Jésù ṣèlérí pé òun máa bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ kí ẹ̀mí náà lè máa kọ́ wa, kó sì máa tù wá nínú. Jésù sì ti mú ìlérí náà ṣẹ. (Jòh. 14:16, 17, àlàyé ìsàlẹ̀; 16:13) Ìyẹn nìkan kọ́ o, Jésù tún ń kọ́ wa láwọn ìpàdé ìjọ ká lè máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn kárí ayé.—Mát. 28:18-20.
2. Àwọn wo ló wà lára “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” tí Éfésù 4:7, 8 sọ?
2 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀bùn míì tí Jésù fún wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé lẹ́yìn tí Jésù lọ sọ́run, “ó fúnni ní àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn.” (Ka Éfésù 4:7, 8.) Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé ìdí tí Jésù fi fún wa láwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn yìí ni pé kí wọ́n lè máa ran ìjọ lọ́wọ́ lónírúurú ọ̀nà. (Éfé. 1:22, 23; 4:11-13) Lónìí, àwọn tó wà lára “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” yìí ni àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àwọn alàgbà ìjọ àtàwọn alábòójútó àyíká.a Ká sòótọ́, aláìpé làwọn ọkùnrin yìí, torí náà wọ́n máa ń ṣàṣìṣe nígbà míì. (Jém. 3:2) Síbẹ̀, àwọn ni Jésù Kristi Olúwa wa ń lò láti ràn wá lọ́wọ́, ẹ̀bùn ni wọ́n lóòótọ́.
3. Sọ àpèjúwe tó jẹ́ ká mọ bí gbogbo wa ṣe lè ran “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” lọ́wọ́.
3 Jésù fún wa láwọn “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” kí wọ́n lè máa gbé ìjọ ró. (Éfé. 4:12) Àmọ́, gbogbo wa la lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa bójú tó iṣẹ́ pàtàkì yìí. Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí. Tá a bá ń kọ́ àwọn Ilé Ìpàdé wa, àwọn kan lára wa ló máa ń kọ́lé náà. Àwọn míì sì máa ń ṣèrànwọ́ láti se oúnjẹ, láti ṣètò mọ́tò tí wọ́n máa fi kó ẹrù tàbí kí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ míì. Lọ́nà kan náà, gbogbo wa la lè ṣèrànwọ́ fáwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àwọn alàgbà ìjọ àtàwọn alábòójútó àyíká tá a bá ń ṣohun táá jẹ́ kí wọ́n lè bójú tó iṣẹ́ wọn dáadáa, tá a sì ń sọ̀rọ̀ tó gbé wọn ró. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní tá à ń rí nínú iṣẹ́ àṣekára táwọn ọkùnrin yìí ń ṣe àti bá a ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn àti Jésù tó fún wa láwọn “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” yìí.
ÀWỌN ÌRÁNṢẸ́ IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ Ń ṢE “IṢẸ́ ÌRÀNWỌ́”
4. Sọ díẹ̀ lára “iṣẹ́ ìrànwọ́” táwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣe nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀.
4 Wọ́n yan àwọn arákùnrin kan láti máa ṣe ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. (1 Tím. 3:8) Ó jọ pé àwọn ló ṣe “àwọn iṣẹ́ ìrànwọ́” tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. (1 Kọ́r. 12:28) Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ pàtàkì míì nínú ìjọ káwọn alàgbà lè ráyè bójú tó àwọn ará àti iṣẹ́ kíkọ́ni. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe káwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan bá wọn ṣàdàkọ Ìwé Mímọ́ tàbí kí wọ́n bá wọn ra àwọn ohun èlò ìkọ̀wé tí wọ́n lò.
5. Sọ díẹ̀ lára iṣẹ́ ìrànwọ́ táwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe lónìí.
5 Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára iṣẹ́ ìrànwọ́ táwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe nínú ìjọ ẹ. (1 Pét. 4:10) Wọ́n máa ń bójú tó àkáǹtì àti ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ, wọ́n máa ń béèrè àwọn ìwé tá a máa ń lò tá a bá ń wàásù, wọ́n sì máa ń ṣètò báwọn ará ṣe máa rí i gbà. Wọ́n máa ń bójú tó ẹ̀rọ tó ń gbóhùn àti àwòrán jáde, wọ́n máa ń bójú tó èrò, wọ́n sì máa ń ṣètò bá a ṣe máa tún Ilé Ìpàdé ṣe. Gbogbo iṣẹ́ yìí ló ṣe pàtàkì kí nǹkan lè máa lọ dáadáa nínú ìjọ. (1 Kọ́r. 14:40) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń bójú tó àwọn apá kan nínú Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, wọ́n sì tún máa ń sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn. Wọ́n tún lè ní kí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan máa ran alábòójútó àwùjọ kan lọ́wọ́. Àwọn ìgbà míì sì wà táwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó kúnjú ìwọ̀n máa ń tẹ̀ lé àwọn alàgbà tí wọ́n bá fẹ́ lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará.
6. Kí ni díẹ̀ lára ìdí tá a fi mọyì àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ kára?
6 Báwo làwọn ará ìjọ ṣe ń jàǹfààní iṣẹ́ táwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe? Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Beberlyb lórílẹ̀-èdè Bòlífíà sọ pé: “Mo máa ń gbádùn àwọn ìpàdé wa gan-an, torí náà mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn nǹkan tá à ń lò nípàdé máa ń jẹ́ kí n kọrin, kí n dáhùn, kí n gbọ́ àsọyé, ó sì máa ń jẹ́ kí n kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn fídíò àtàwọn àwòrán tá à ń lò níbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń bójú tó gbogbo àwa tá a wà nípàdé kí jàǹbá má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa, wọ́n sì máa ń ṣètò bí àwọn tí ò lè wá ṣe máa dara pọ̀ mọ́ wa látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Tí ìpàdé bá sì parí, wọ́n máa ń tún Ilé Ìpàdé ṣe, wọ́n máa ń ṣe àkáǹtì, wọ́n sì máa ń rí i pé àwọn ará rí ìwé tí wọ́n máa lò lóde ìwàásù gbà. Mo mọyì wọn gan-an!” Ìyàwó alàgbà kan tó ń jẹ́ Leslie ní Kòlóńbíà sọ pé: “Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lára ọkọ mi, àwọn ló ń ràn án lọ́wọ́ kó lè máa ṣe onírúurú iṣẹ́ nínú ìjọ. Tí kì í bá ṣe tiwọn ni, ọwọ́ ọkọ mi ì bá ti dí jù. Torí náà, mo dúpẹ́ pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ náà tọkàntọkàn, wọ́n sì ń fìtara ṣe é.” Ó dájú pé bó ṣe rí lára tìẹ náà nìyẹn.—1 Tím. 3:13.
7. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
7 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a mọyì àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wà láàárín wa, Bíbélì ṣì sọ fún wa pé ká “máa dúpẹ́” lọ́wọ́ wọn. (Kól. 3:15) Alàgbà kan tó ń jẹ́ Krzysztof lórílẹ̀-èdè Finland sọ bóun ṣe máa ń mọrírì iṣẹ́ táwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe. Ó ní: “Mo máa ń fi káàdì ìkíni tàbí àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sáwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, màá sì kọ ẹsẹ Bíbélì kan sínú ẹ̀ tàbí kí n sọ nǹkan pàtó tí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ṣe tó fún mi níṣìírí tàbí tí mo mọrírì.” Pascal àti Jael tó ń gbé ní New Caledonia máa ń dìídì gbàdúrà fáwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Pascal sọ pé: “Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a máa ń bẹ Jèhófà nítorí àwọn arákùnrin yìí, a sì tún máa ń dúpẹ́ nítorí wọn.” Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà wa, gbogbo ìjọ ló sì ń jàǹfààní iṣẹ́ wọn.—2 Kọ́r. 1:11.
ÀWỌN ALÀGBÀ “Ń ṢIṢẸ́ KÁRA LÁÀÁRÍN” WA
8. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé àwọn alàgbà ìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ “ń ṣiṣẹ́ kára”? (1 Tẹsalóníkà 5:12, 13)
8 Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn alàgbà máa ń ṣiṣẹ́ kára gan-an nínú ìjọ. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:12, 13; 1 Tím. 5:17) Wọ́n “ń ṣe àbójútó” ìjọ, wọ́n ń darí ìpàdé, wọ́n sì máa ń ṣèpinnu nínú ìgbìmọ̀ alàgbà. Wọ́n máa ‘ń gba àwọn ará níyànjú,’ wọ́n sì máa ń fìfẹ́ gbà wọ́n nímọ̀ràn kí wọ́n lè dáàbò bo ìjọ. (1 Tẹs. 2:11, 12; 2 Tím. 4:2) Àwọn ọkùnrin yìí tún máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè pèsè fún ìdílé wọn, kí wọ́n sì lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.—1 Tím. 3:2, 4; Títù 1:6-9.
9. Kí ni díẹ̀ lára iṣẹ́ táwọn alàgbà ń ṣe lónìí?
9 Ọwọ́ àwọn alàgbà máa ń dí gan-an. Wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ ajíhìnrere. (2 Tím. 4:5) Wọ́n ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n máa ń ṣètò iṣẹ́ ìwàásù láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn, wọ́n tún máa ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè wàásù, ká sì kọ́ni lọ́nà tó dáa. Wọ́n tún máa ń fàánú hàn tí wọ́n bá ń gbọ́ ẹjọ́, wọn kì í sì í ṣojúsàájú. Tí Kristẹni kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, àwọn alàgbà máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí àjọṣe ẹni náà àti Jèhófà lè pa dà gún régé. Bí wọ́n sì ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń mú kí ìjọ wà ní mímọ́. (1 Kọ́r. 5:12, 13; Gál. 6:1) Iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù táwọn alàgbà máa ń ṣe ni iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn. (1 Pét. 5:1-3) Wọ́n máa ń sọ àwọn àsọyé Bíbélì tí wọ́n múra dáadáa, wọ́n máa ń gbìyànjú láti mọ gbogbo àwọn ará ìjọ, wọ́n sì máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará. Yàtọ̀ sáwọn iṣẹ́ míì táwọn alàgbà máa ń ṣe, àwọn alàgbà kan tún máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń kọ́ Ilé Ìpàdé wa tí wọ́n sì ń tún un ṣe, wọ́n máa ń ṣètò àpéjọ agbègbè, àwọn míì sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn àti Àwùjọ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn alàgbà yìí ń ṣe nítorí wa!
10. Kí ni díẹ̀ lára ìdí tá a fi mọyì àwọn alàgbà tó ń ṣiṣẹ́ kára?
10 Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn alàgbà máa bójú tó wa àti pé ‘ẹ̀rù ò ní bà wá mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní jáyà mọ́.’ (Jer. 23:4) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Johanna láti orílẹ̀-èdè Finland gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí nígbà tí màmá ẹ̀ ṣàìsàn tó le gan-an. Ó sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í rọrùn fún mi láti sọ bó ṣe ń ṣe mí fáwọn èèyàn, alàgbà kan tí mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ dáadáa mú sùúrù fún mi, ó gbàdúrà pẹ̀lú mi, ó sì jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi. Mi ò rántí ohun tó sọ gangan o, àmọ́ mo rántí pé ó fi mí lọ́kàn balẹ̀. Mo gbà pé Jèhófà ló rán an wá torí àsìkò yẹn ni mo nílò ìránwọ́ jù.” Báwo làwọn alàgbà ìjọ ẹ ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́?
11. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì nǹkan táwọn alàgbà ń ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
11 Jèhófà fẹ́ ká mọyì àwọn alàgbà “nítorí iṣẹ́ wọn.” (1 Tẹs. 5:12, 13) Henrietta tóun náà ń gbé lórílẹ̀-èdè Finland sọ pé: “Tinútinú làwọn alàgbà fi máa ń ran àwọn ará lọ́wọ́, àmọ́ ìyẹn ò sọ pé wọ́n ráyè ju àwa yòókù lọ tàbí pé wọ́n lágbára jù wá lọ, ìyẹn ò sì sọ pé wọn ò níṣòro. Nígbà míì mo máa ń sọ fún wọn pé: ‘Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé iṣẹ́ ńlá lẹ̀ ń ṣe? Alàgbà tó dáa ni yín.’” Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sera lórílẹ̀-èdè Türkiyec sọ pé: “Ó yẹ ká máa fún àwọn alàgbà níṣìírí kí wọ́n lè máa báṣẹ́ wọn lọ. Torí náà, a lè fi káàdì ìkíni ránṣẹ́ sí wọn, a lè pè wọ́n pé ká jọ jẹun, a sì lè bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù.” Ṣé alàgbà kan wà tó o mọyì iṣẹ́ ẹ̀ gan-an? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, wá bó o ṣe máa gbóríyìn fún un.—1 Kọ́r. 16:18.
Máa sọ ohun tó máa fún àwọn alàgbà níṣìírí kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ wọn nìṣó (Wo ìpínrọ̀ 7, 11, 15)
ÀWỌN ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ Ń GBÉ ÌJỌ RÓ
12. Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, ètò wo làwọn alàgbà ṣe láti gbé ìjọ ró? (1 Tẹsalóníkà 2:7, 8)
12 Kristi Jésù tún yan “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ míì nínú ìjọ. Ó darí àwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pé kí wọ́n rán Pọ́ọ̀lù, Bánábà àtàwọn míì láti máa ṣiṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò. (Ìṣe 11:22) Kí nìdí? Ìdí tí wọ́n fi rán wọn lọ ni pé kí wọ́n lè máa gbé ìjọ ró bíi tàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àtàwọn alàgbà. (Ìṣe 15:40, 41) Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn ọkùnrin yìí yááfì kí wọ́n lè gbé ìjọ ró. Kódà, wọ́n máa ń fẹ̀mí ara wọn wewu.—Ka 1 Tẹsalóníkà 2:7, 8.
13. Iṣẹ́ wo làwọn alábòójútó àyíká máa ń ṣe?
13 Àwọn alábòójútó àyíká máa ń lọ láti ibì kan sí ibòmíì. Àwọn kan máa ń rìnrìn àjò ọ̀pọ̀ kìlómítà láti ìjọ kan sí òmíì. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, alábòójútó àyíká máa ń sọ àwọn àsọyé fún ìjọ, ó máa ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, ó máa ń darí ìpàdé aṣáájú-ọ̀nà, ìpàdé alàgbà àti ìpàdé iṣẹ́ ìwàásù. Ó máa ń múra àsọyé sílẹ̀, ó sì máa ń ṣètò àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè. Ó tún máa ń darí ilé ẹ̀kọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà, ó máa ń ṣètò àkànṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà ní àyíká tó ń bójú tó. Nígbà míì, ó máa ń bójú tó àwọn iṣẹ́ tí ẹ̀ka ọ́fíìsì bá yàn fún un, iṣẹ́ náà sì lè jẹ́ pàjáwìrì.
14. Kí nìdí tá a fi mọyì àwọn alábòójútó àyíká tó ń ṣiṣẹ́ kára?
14 Báwo làwọn ìjọ ṣe ń jàǹfààní iṣẹ́ rere táwọn alábòójútó àyíká ń ṣe? Arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Türkiye sọ bí ìbẹ̀wò àwọn alábòójútó àyíká ṣe máa ń rí lára ẹ̀, ó ní: “Gbogbo ìgbà táwọn alábòójútó àyíká bá bẹ̀ wá wò ló máa ń wu èmi náà láti túbọ̀ lo àkókò pẹ̀lú àwọn ará, kí n sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ alábòójútó àyíká ni mo mọ̀, kò sì sí ìkankan nínú wọn tó máa ń jẹ́ kí n rò pé òun ò ní ráyè bá mi sọ̀rọ̀ tàbí pé ọwọ́ òun dí jù.” Johanna tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú àti alábòójútó àyíká lọ wàásù, àmọ́ wọn ò bá ẹnì kankan nílé. Ó sọ pé: “Síbẹ̀ mi ò gbàgbé ọjọ́ yẹn. Àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin méjèèjì ṣẹ̀ṣẹ̀ kó kúrò nílé, torí náà àárò wọn ń sọ mí. Alábòójútó àyíká fún mi níṣìírí, ó sì jẹ́ kí n mọ̀ pé a lè má gbé nítòsí ìdílé wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa báyìí, àmọ́ nínú ayé tuntun, gbogbo wa jọ máa wà pa pọ̀ ni.” Ọ̀pọ̀ lára wa ló mọyì àwọn alábòójútó àyíká àti bí wọ́n ṣe ń ràn wá lọ́wọ́.—Ìṣe 20:37–21:1.
15. (a) Bí 3 Jòhánù 5-8 ṣe sọ, báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn alábòójútó àyíká? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa mọyì ìyàwó àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ, báwo la sì ṣe lè ṣe é? (Wo àpótí náà “Máa Rántí Ìyàwó Wọn.”)
15 Àpọ́sítélì Jòhánù gba Gáyọ́sì níyànjú pé kó máa ṣaájò àwọn arákùnrin tó bá wá bẹ̀ wọ́n wò, ó sì sọ pé tí wọ́n bá ti ń lọ, kó “ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ọ̀nà tí inú Ọlọ́run dùn sí.” (Ka 3 Jòhánù 5-8.) Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká pe àwọn alábòójútó àyíká wá jẹun nílé wa. Nǹkan míì tá a tún lè ṣe ni pé ká máa wá sípàdé iṣẹ́ ìwàásù tí alábòójútó àyíká máa ń darí ká lè jọ wàásù. Leslie tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú tún sọ àwọn ọ̀nà míì tóun gbà mọyì wọn. Ó sọ pé: “Mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó pèsè ohun tí wọ́n nílò. Èmi àtọkọ mi tún máa ń kọ lẹ́tà sí wọn, kí wọ́n lè mọ̀ pé a gbádùn ìbẹ̀wò wọn gan-an.” Ká má gbàgbé pé èèyàn bíi tiwa làwọn alábòójútó àyíká. Nígbà míì, wọ́n máa ń ṣàìsàn, ọkàn wọn lè má balẹ̀ tàbí kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì. Ó ṣeé ṣe kí alábòójútó àyíká kan ti máa gbàdúrà pé kí Jèhófà dáhùn àdúrà òun. Torí náà, Jèhófà lè lò ẹ́ láti sọ̀rọ̀ tó tura fún un, ó sì lè jẹ́ ẹ̀bùn kékeré kan tó o fún un ló máa fún un níṣìírí!—Òwe 12:25.
A NÍLÒ “ÀWỌN Ẹ̀BÙN TÍ Ó JẸ́ ÈÈYÀN”
16. Bí Òwe 3:27 ṣe sọ, àwọn ìbéèrè wo ló yẹ káwọn arákùnrin bi ara wọn?
16 A túbọ̀ nílò “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn,” ìyẹn àwọn arákùnrin táá máa ṣàbójútó nínú ìjọ kárí ayé. Tó o bá jẹ́ arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi, ṣé o lè yọ̀ǹda ara ẹ “tí o bá lágbára” láti ṣe bẹ́ẹ̀? (Ka Òwe 3:27, àlàyé ìsàlẹ̀.) Ṣé o ṣe tán láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́? Ṣé o lè sapá láti di alàgbà kó o lè ran àwọn ará lọ́wọ́?d Ṣé o lè ṣe àwọn àyípadà kan, kó o lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run? Ohun tó o máa kọ́ nílé ẹ̀kọ́ yìí máa jẹ́ kí Jésù túbọ̀ lò ẹ́. Tó o bá rò pé o ò kúnjú ìwọ̀n láti ṣe àwọn nǹkan yìí, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Sọ fún un pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o lè ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá gbé fún ẹ láṣeyanjú.—Lúùkù 11:13; Ìṣe 20:28.
17. Irú ẹni wo ni Jésù Kristi Ọba wa jẹ́ bó ṣe yan “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn”?
17 Bí Jésù ṣe yan “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn” fi hàn pé òun ló ń darí wa láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. (Mát. 28:20) A dúpẹ́ pé a ní Ọba tó nífẹ̀ẹ́ wa, tó jẹ́ ọ̀làwọ́, tó ń gba tiwa rò, tó sì yan àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti bójú tó wa. Wá bó o ṣe máa fi hàn pé o mọyì àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ kára yìí. Torí náà, gbogbo ìgbà ni kó o máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó fún wa ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.”—Jém. 1:17.
ORIN 99 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwa Ará
a Àwọn alàgbà tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí, àwọn olùrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí, àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka àtàwọn arákùnrin tó ń bójú tó àwọn iṣẹ́ míì wà lára “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn.”
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
c Turkey ni wọ́n ń pè é tẹ́lẹ̀.
d Kó o lè mọ bó o ṣe máa di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà, wo àpilẹ̀kọ náà “Ẹ̀yin Arákùnrin, Ṣé Ẹ̀ Ń Ṣiṣẹ́ Kára Kẹ́ Ẹ Lè Di Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?” àti “Ẹ̀yin Arákùnrin, Ṣé Ẹ̀ Ń Ṣiṣẹ́ Kára Kẹ́ Ẹ Lè Di Alàgbà?” nínú Ilé Ìṣọ́ November 2024.