ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 41
ORIN 13 Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa
Àwọn Nǹkan Tá A Kọ́ Lára Jésù ní Ogójì Ọjọ́ Tó Lò Kẹ́yìn Láyé
“Wọ́n rí i jálẹ̀ ogójì (40) ọjọ́, ó sì ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run.”—ÌṢE 1:3.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Jésù ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan ní ogójì (40) ọjọ́ tó lò kẹ́yìn láyé, torí náà a máa kọ́ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀.
1-2. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń rìn lọ sí Ẹ́máọ́sì?
NÍ Nísàn 16 ọdún 33 S.K., ohun kan ṣẹlẹ̀. Ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbọgbẹ́ gan-an, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n. Méjì lára wọn kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì forí lé Ẹ́máọ́sì, ìyẹn abúlé kan tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mọ́kànlá (11) sí Jerúsálẹ́mù. Inú àwọn ọkùnrin yìí bà jẹ́ gan-an torí pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa Jésù aṣáájú wọn ni. Ó sì jọ pé ohun tí wọ́n rò pé Mèsáyà máa ṣe fún wọn ti já sásán. Àmọ́, ohun tó máa ṣẹlẹ̀ báyìí máa ya àwọn ọkùnrin yìí lẹ́nu gan-an.
2 Ọkùnrin kan tí wọn ò mọ̀ rí pàdé wọn, wọ́n sì jọ ń rìn lọ. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà sọ bí inú wọn ṣe bà jẹ́ tó torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù. Ọkùnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn nǹkan tó yà wọ́n lẹ́nu, tí wọn ò sì ní gbàgbé fún wọn. Ó “bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Mósè àti gbogbo àwọn Wòlíì,” ó sì ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kí Mèsáyà jìyà, kó sì kú. Nígbà táwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta dé Ẹ́máọ́sì, àjèjì yẹn jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tóun jẹ́. Ǹjẹ́ ẹ mọ ẹni náà? Jésù tó ti jíǹde ni! Ẹ wo bínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n rí i pé Mèsáyà ti jíǹde!—Lúùkù 24:13-35.
3-4. Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, kí la sì máa kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Ìṣe 1:3)
3 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù fara han àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ jálẹ̀ ogójì (40) ọjọ́ tó lò kẹ́yìn láyé.a (Ka Ìṣe 1:3.) Inú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ò dùn, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n, àmọ́ ní àkókò yẹn, Jésù fún wọn níṣìírí. Torí náà, inú wọn dùn, wọ́n nígboyà láti wàásù, wọ́n sì ń kọ́ni ní ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.
4 Àwa náà máa jàǹfààní gan-an tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí Jésù ṣe láwọn ọjọ́ tó lò kẹ́yìn láyé. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí Jésù ṣe lo àkókò yìí láti (1) fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ níṣìírí, (2) jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́ àti (3) dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè bójú tó àwọn ojúṣe tó pọ̀ sí i. Bá a ṣe ń gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yẹ̀ wò, a máa rí bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù.
MÁA FÚN ÀWỌN ÈÈYÀN NÍṢÌÍRÍ
5. Kí nìdí táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi nílò ìṣírí?
5 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nílò ìṣírí. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn kan ti fi ilé, ìdílé àti okòwò wọn sílẹ̀, kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé Jésù ní gbogbo ìgbà. (Mát. 19:27) Wọ́n tún ń fojú àwọn èèyàn rí màbo torí pé wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Jòh. 9:22) Síbẹ̀, wọ́n fara da àwọn nǹkan yìí torí wọ́n gbà pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Mát. 16:16) Àmọ́ nígbà tí wọ́n pa Jésù, ọkàn wọn bà jẹ́ gan-an, ó sì jọ pé kò sírètí fún wọn mọ́.
6. Kí ni Jésù ṣe lẹ́yìn tó jíǹde?
6 Jésù mọ̀ pé ọ̀fọ̀ tó ṣẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ló mú kí ọkàn wọn gbọgbẹ́, kì í ṣe torí pé wọn ò nígbàgbọ́. Torí náà, àtọjọ́ tó ti jíǹde ló ti ń fún wọn níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, Jésù fara han Màríà Magidalénì nígbà tó ń sunkún níbi ibojì ẹ̀. (Jòh. 20:11, 16) Ó tún fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Yàtọ̀ síyẹn, ó fara han àpọ́sítélì Pétérù. (Lúùkù 24:34) Kí la rí kọ́ nínú àwọn nǹkan tí Jésù ṣe yìí? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó fara han Màríà Magidalénì.
7. Bó ṣe wà nínú Jòhánù 20:11-16, kí ni Jésù rí Màríà tó ń ṣe láàárọ̀ Nísàn 16, kí ni Jésù sì ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
7 Ka Jòhánù 20:11-16. Ní àárọ̀ kùtù Nísàn 16, àwọn obìnrin olóòótọ́ kan lọ síbi tí wọ́n sin Jésù sí. (Lúùkù 24:1, 10) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀kan lára àwọn obìnrin náà, ìyẹn, Màríà Magidalénì. Nígbà tí Màríà dé ibojì náà, kò rí òkú Jésù níbẹ̀. Ó lọ sọ ohun tó rí fún Pétérù àti Jòhánù, làwọn méjèèjì bá sáré lọ sí ibojì náà, Màríà náà sì gbá tẹ̀ lé wọn. Nígbà tí Pétérù àti Jòhánù rí i pé òkú Jésù ò sí níbẹ̀ mọ́, wọ́n pa dà sílé. Àmọ́, Màríà ò kúrò níbẹ̀, ńṣe ló ń sunkún láìmọ̀ pé Jésù ń wo òun. Jésù rí bí obìnrin olóòótọ́ yìí ṣe ń wa ẹkún mu, àánú ẹ̀ sì ṣe é. Torí náà, ó fara han Màríà, ó sì ṣe nǹkan tó máa tù ú nínú. Ó bá a sọ̀rọ̀, ó sì gbéṣẹ́ pàtàkì kan fún un. Iṣẹ́ náà ni pé kó lọ sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn tó kù pé òun ti jíǹde.—Jòh. 20:17, 18.
A lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tá a bá ń fara balẹ̀ kíyè sí àwọn èèyàn, tá a sì ń fàánú hàn sáwọn tó nílò ìtùnú (Wo ìpínrọ̀ 7)
8. Báwo la ṣe lè fara wé Jésù?
8 Báwo la ṣe lè fara wé Jésù? A lè fara wé Jésù tá a bá ń fún àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin níṣìírí kí wọ́n lè máa sin Jèhófà nìṣó. Ohun tó sì máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká ṣe bíi ti Jésù, ká mọ ìṣòro tí wọ́n ní, ká mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn, ká sì tù wọ́n nínú. Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Jocelyn tí àbúrò ẹ̀ obìnrin kú nígbà tí jàǹbá kan ṣẹlẹ̀. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ oṣù ni mo fi ní ẹ̀dùn ọkàn tó le gan-an.” Nígbà tí arákùnrin kan àtìyàwó ẹ̀ gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n ní kó wá sílé wọn, wọ́n fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, wọ́n bá a kẹ́dùn, wọ́n sì jẹ́ kó dá a lójú pé ó ṣeyebíye gan-an lójú Jèhófà. Jocelyn sọ pé: “Ṣe ló dà bíi pé mo ti ń rì sínú agbami òkun. Àmọ́, Jèhófà lo arákùnrin yìí àtìyàwó ẹ̀ láti fà mí jáde. Wọ́n jẹ́ kó túbọ̀ wù mí láti máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó.” Àwa náà lè fún àwọn èèyàn níṣìírí tá a bá ń fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, tá a sì ń tù wọ́n nínú kí wọ́n lè lókun bí wọ́n ṣe ń sin Jèhófà.—Róòmù 12:15.
RAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ TÚBỌ̀ LÓYE Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
9. Ìṣòro wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní, báwo ni Jésù sì ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?
9 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́, wọ́n sì máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti fi í sílò. (Jòh. 17:6) Síbẹ̀, wọ́n ṣì ń ronú pé kò yẹ kí wọ́n fẹ̀sùn ọ̀daràn kan Jésù, kí wọ́n sì pa á sórí òpó igi oró. Àmọ́ Jésù mọ̀ pé kì í ṣe torí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ò nígbàgbọ́, kì í sì í ṣe torí pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ìdí tí wọ́n fi ń ronú bẹ́ẹ̀ ni pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lóye Ìwé Mímọ́. (Lúùkù 9:44, 45; Jòh. 20:9) Torí náà, ó ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ lóye ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ. Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe ṣe é nígbà tó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì lójú ọ̀nà tó lọ sí Ẹ́máọ́sì.
10. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ kó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lójú pé òun ni Mèsáyà náà? (Lúùkù 24:18-27)
10 Ka Lúùkù 24:18-27. Ẹ kíyè sí i pé kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tóun jẹ́. Dípò kó ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló bi wọ́n ní ìbéèrè. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé ó fẹ́ kí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, ó sì fẹ́ mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn. Wọ́n sọ fún un pé Jésù làwọn ń retí pé kó di ọba Ísírẹ́lì, kó sì máa ṣàkóso àwọn dípò àwọn ará Róòmù. Lẹ́yìn tí wọ́n sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, Jésù lo Ìwé Mímọ́ láti jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ṣẹ.b Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, Jésù tún ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn fáwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù. (Lúùkù 24:33-48) Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Jésù ṣe yìí?
11-12. (a) Kí la kọ́ nínú bí Jésù ṣe kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Báwo lẹni tó kọ́ Nortey lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ràn án lọ́wọ́?
11 Báwo la ṣe lè fara wé Jésù? Ohun àkọ́kọ́ ni pé tó o bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, máa béèrè ìbéèrè táá jẹ́ kó sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. (Òwe 20:5) Tó o bá ti mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀, jẹ́ kó mọ bó ṣe lè rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó máa ràn án lọ́wọ́. Má sọ ohun tó máa ṣe fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, bi í ní ìbéèrè táá jẹ́ kó ronú lórí ẹsẹ Bíbélì tó kà, kó o sì ràn án lọ́wọ́ láti fi ohun tó kọ́ sílò. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Nortey lórílẹ̀-èdè Gánà.
12 Ìgbà tí Nortey wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ kò pẹ́ tí ìdílé ẹ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò ó. Kí ló jẹ́ kó máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó? Ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti bá a jíròrò ohun tó wà nínú Mátíù orí 10, ó sì ti ṣàlàyé fún un pé wọ́n máa ṣenúnibíni sáwa Kristẹni tòótọ́. Nortey sọ pé: “Nígbà tí inúnibíni náà bẹ̀rẹ̀, ó dá mi lójú pé mo ti rí òtítọ́.” Ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tún jíròrò ohun tó wà nínú Mátíù 10:16 pẹ̀lú ẹ̀, ó sì sọ pé kó máa yẹra fún ohunkóhun tó lè dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìdílé ẹ̀. Wọ́n sì tún sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe lè ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́ fáwọn ará ilé ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Lẹ́yìn tí Nortey ṣèrìbọmi, bàbá ẹ̀ fẹ́ kó lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga, àmọ́ aṣáájú-ọ̀nà ló fẹ́ ṣe ní tiẹ̀. Dípò kí ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ ohun tó máa ṣe fún un, ó bi í láwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kó ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì kan. Kí nìyẹn wá mú kí Nortey ṣe? Ó pinnu pé òun máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Torí náà, bàbá ẹ̀ lé e kúrò nílé. Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ṣe rí lára Nortey? Ó sọ pé: “Ó dá mi lójú pé ìpinnu tó tọ́ ni mo ṣe.” Táwa náà bá ń jẹ́ káwọn èèyàn ronú lórí àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́, àá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀.—Éfé. 3:16-19.
O lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó o bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́ (Wo ìpínrọ̀ 11)e
RAN ÀWỌN ARÁKÙNRIN LỌ́WỌ́ LÁTI DI “Ẹ̀BÙN TÍ Ó JẸ́ ÈÈYÀN”
13. Kí ni Jésù ṣe kó lè rí i pé iṣẹ́ Bàbá ẹ̀ ń tẹ̀ síwájú? (Éfésù 4:8)
13 Nígbà tí Jésù wà láyé, ó fìtara bójú tó iṣẹ́ tí Bàbá ẹ̀ gbé fún un. (Jòh. 17:4) Àmọ́, Jésù kì í ronú pé tí nǹkan bá máa lọ dáadáa, àfi kí òun fúnra òun ṣe é. Láàárín ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó fi ṣiṣẹ́ ìsìn ẹ̀, ó dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣiṣẹ́ náà bó ṣe yẹ. Kí Jésù tó pa dà sọ́run, ó gbéṣẹ́ pàtàkì kan fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà, kí wọ́n sì máa darí iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ó ṣeé ṣe káwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí má ju ẹni ogún (20) ọdún sí mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) lọ. (Ka Éfésù 4:8.) Àwọn ọkùnrin yìí ti ṣiṣẹ́ kára pẹ̀lú Jésù, wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́. Àmọ́ kó tó pa dà sọ́run, ó tún dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ láti di “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn.” Báwo ló ṣe dá wọn lẹ́kọ̀ọ́?—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Éfésù 4:8 nínú nwtsty-E.
14. Báwo ni Jésù ṣe ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lọ́wọ́ ní gbogbo ogójì (40) ọjọ́ tó lò kẹ́yìn láyé? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
14 Ìgbà kan wà tí Jésù rí i pé ó yẹ kóun bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wí, àmọ́ kò bínú sí wọn bó ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó kíyè sí i pé àwọn kan nínú wọn máa ń ṣiyèméjì, ó sì fún wọn nímọ̀ràn tó ràn wọ́n lọ́wọ́. (Lúùkù 24:25-27; Jòh. 20:27) Ó tún sọ fún wọn pé kí wọ́n túbọ̀ máa bójú tó àwọn èèyàn Jèhófà dípò kí wọ́n gbájú mọ́ iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn. (Jòh. 21:15) Ó rán wọn létí pé kí wọ́n má fi àǹfààní tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà wé àǹfààní táwọn ẹlòmíì ní. (Jòh. 21:20-22) Bákan náà, ó tún èrò wọn ṣe nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà. (Ìṣe 1:6-8) Kí làwọn alàgbà lè kọ́ lára Jésù?
O lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó o bá ń ran àwọn ọkùnrin lọ́wọ́ kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n láti bójú tó ojúṣe tó pọ̀ sí i (Wo ìpínrọ̀ 14)
15-16. (a) Báwo làwọn alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? (b) Àǹfààní wo ni Patrick rí nínú ìmọ̀ràn tí alàgbà kan fún un?
15 Báwo làwọn alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? Ó yẹ káwọn alàgbà máa dá àwọn arákùnrin lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bójú tó ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ìjọ títí kan àwọn tí ọjọ́ orí wọn ṣì kéré.c Àwọn alàgbà mọ̀ pé àwọn tí wọ́n ń dá lẹ́kọ̀ọ́ kì í ṣe ẹni pípé. Wọ́n tún mọ̀ pé wọ́n ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti kọ́, torí náà ó yẹ kí wọ́n máa fìfẹ́ gbà wọ́n nímọ̀ràn, kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe máa ṣiṣẹ́ tí wọ́n gbé fún wọn. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n nírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, kí wọ́n sì ṣe tán láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́.—1 Tím. 3:1; 2 Tím. 2:2; 1 Pét. 5:5.
16 Ẹ jẹ́ ká wo àǹfààní tí arákùnrin kan tó ń jẹ́ Patrick rí nígbà tí wọ́n gbà á nímọ̀ràn. Nígbà tó ṣì kéré, ó máa ń sọ̀rọ̀ sáwọn èèyàn bó ṣe wù ú, kì í sì í finúure hàn sí wọn títí kan àwọn arábìnrin. Alàgbà kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ kíyè sí ìwà burúkú tí Patrick ní yìí, ó fìfẹ́ gbà á nímọ̀ràn, ó sì sòótọ́ ọ̀rọ̀ fún un. Patrick sọ pé: “Inú mi dùn gan-an pé wọ́n gbà mí nímọ̀ràn. Tẹ́lẹ̀, inú mi kì í dùn tí mo bá rí i pé wọ́n fún àwọn arákùnrin míì láǹfààní láti ṣiṣẹ́ ìsìn tó wù mí. Àmọ́, alàgbà yẹn jẹ́ kí n rí i pé ohun tó ṣe pàtàkì jù ni kí n nírẹ̀lẹ̀, kí n sì máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará dípò kí n máa wá ipò tàbí kí n máa retí pé kí wọ́n fún mi níṣẹ́ kan nínú ìjọ.” Torí pé Patrick fi ìmọ̀ràn yẹn sílò, ó di alàgbà nígbà tó pé ẹni ọdún mẹ́tàlélógún (23).—Òwe 27:9.
17. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun fọkàn tán àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun?
17 Kì í ṣe iṣẹ́ ìwàásù nìkan ni Jésù gbé fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, ó tún ní kí wọ́n máa kọ́ni. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ “teaching them” tó wà ní Mátíù 28:20 nínú nwtsty-E.) Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ronú pé àwọn ò kúnjú ìwọ̀n láti ṣe ohun tí Jésù fẹ́ kí wọ́n ṣe. Àmọ́, ó dá Jésù lójú pé wọ́n lè ṣiṣẹ́ náà, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bẹ́ẹ̀. Kódà, ó sọ fún wọn pé: “Bí Baba ṣe rán mi gẹ́lẹ́ ni èmi náà ń rán yín.”—Jòh. 20:21.
18. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fara wé Jésù?
18 Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fara wé Jésù? Àwọn alàgbà tó nírìírí máa ń faṣẹ́ lé àwọn míì lọ́wọ́. (Fílí. 2:19-22) Bí àpẹẹrẹ, àwọn alàgbà lè ní káwọn ọmọdé náà dara pọ̀ mọ́ wọn tí wọ́n bá ń ṣe ìmọ́tótó Ilé Ìpàdé tàbí tí wọ́n ń tún un ṣe. Tí wọ́n bá gbéṣẹ́ fáwọn arákùnrin kan, ó yẹ kí wọ́n dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n á ṣe ṣiṣẹ́ náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n á fọkàn tán wọn pé wọ́n á ṣiṣẹ́ náà dáadáa. Arákùnrin Matthew tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di alàgbà sọ pé òun mọyì bí àwọn alàgbà tó nírìírí ṣe dá òun lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n gbéṣẹ́ kan fún òun, tí wọ́n sì fọkàn tán òun pé òun máa ṣe é dáadáa. Ó sọ pé: “Tí mo bá ṣàṣìṣe, wọ́n máa ń jẹ́ kí n rí ohun tí mo lè ṣe láti sunwọ̀n sí i.”d
19. Kí ló yẹ ká pinnu pé àá máa ṣe?
19 Láàárín ogójì (40) ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, ó fún àwọn èèyàn níṣìírí, ó kọ́ wọn, ó sì dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. (1 Pét. 2:21) Ó sì dájú pé Jésù máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, ó ti ṣèlérí pé: “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mát. 28:20.
ORIN 15 Ẹ Yin Àkọ́bí Jèhófà!
a Àwọn Ìwé Ìhìn Rere àtàwọn ìwé Bíbélì míì ṣàkọsílẹ̀ ìgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Jésù fara han àwọn èèyàn lẹ́yìn tó jíǹde. Bí àpẹẹrẹ, ó fara han Màríà Magidalénì (Jòh. 20:11-18); àwọn obìnrin míì (Mát. 28:8-10; Lúùkù 24:8-11); àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì (Lúùkù 24:13-15); Pétérù (Lúùkù 24:34); àwọn àpọ́sítélì, àmọ́ Tọ́másì ò sí níbẹ̀ (Jòh. 20:19-24); àwọn àpọ́sítélì pẹ̀lú Tọ́másì (Jòh. 20:26); méje lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ (Jòh. 21:1, 2); àwọn tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ (Mát. 28:16; 1 Kọ́r. 15:6); Jémíìsì àbúrò ẹ̀ (1 Kọ́r. 15:7); gbogbo àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ (Ìṣe 1:4) àti àwọn àpọ́sítélì tó wà nítòsí Bẹ́tánì. (Lúùkù 24:50-52) Ó ṣeé ṣe kí Jésù tún fara han àwọn míì tí Bíbélì ò dárúkọ wọn.—Jòh. 21:25.
b Kó o lè rí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà náà, ka àpilẹ̀kọ yìí lórí jw.org, “Ṣé Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà Fẹ̀rí Hàn Pé Jésù Ni Mèsáyà Náà?”
c Nígbà míì, àwọn arákùnrin tó kúnjú ìwọ̀n máa ń di alábòójútó àyíká nígbà tí wọ́n ṣì wà lẹ́ni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) sí ọgbọ̀n (30) ọdún. Àmọ́ irú àwọn arákùnrin bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ ti di alàgbà tó nírìírí.
d Kó o lè mọ bó o ṣe lè ran àwọn arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n láti bójú tó iṣẹ́ tó pọ̀ sí i nínú ètò Ọlọ́run, wo Ilé Ìṣọ́ August 2018, ojú ìwé 11-12, ìpínrọ̀ 15-17 àti Ilé Ìṣọ́ April 15, 2015, ojú ìwé 3-13.
e ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ran ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ lóye Ìwé Mímọ́. Lẹ́yìn náà, akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn da gbogbo nǹkan tó fi ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́ nígbà ayẹyẹ Kérésìmesì nù.