ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb23 July ojú ìwé 15
  • Máa Fìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Bíi Ti Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Bíi Ti Jèhófà
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Ìfẹ́ Jèhófà Tí Kì Í Yẹ̀ Ṣe Ń Ṣe Ọ́ Láǹfààní?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ṣé Inú Rẹ Máa Ń Dùn sí Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Bíi Ti Jèhófà?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Jèhófà Ní Ìfẹ́ Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ Sí Ẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Báwo La Ṣe Lè Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
mwb23 July ojú ìwé 15

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Fìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Bíi Ti Jèhófà

Jèhófà ló fi àpẹẹrẹ tó ga jù lọ lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká fìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sẹ́nì kan. (Sm 103:11) Ìfẹ́ yìí kì í ṣe ìmọ̀lára kan lásán tó kàn wà fún ìgbà díẹ̀; àwọn tó bá ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ síra wọn máa ń sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí, ìfẹ́ yẹn máa ń jinlẹ̀ gan-an, ó sì máa ń wà pẹ́ títí. Onírúurú ọ̀nà ni Jèhófà gbà fi ìfẹ́ yìí hàn sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì tó ń fi wọ́n ṣẹrú, ó sì mú wọn wá sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Sm 105:42-44) Ó máa ń jà fáwọn èèyàn rẹ̀, léraléra ló sì máa ń dárí jì wọ́n tí wọ́n bá ṣẹ̀. (Sm 107:19, 20) Bá a ṣe ń “fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,” ó máa ń wù wá láti fara wé e.​—Sm 107:43.

Àwòrán: Àwọn àwòrán tó dá lórí fídíò “Fara Balẹ̀ Kíyè Sí Àwọn Ohun Tí Jèhófà Ṣe Nítorí Ìfẹ́ Rẹ̀ Tí Kì Í Yẹ̀.” 1. Arákùnrin Capra àti arákùnrin míì lọ bẹ arábìnrin kan wò nílé. 2. Arákùnrin Capra wà lẹ́wọ̀n pẹ̀lú àwọn arákùnrin míì, ó sì ń fún arákùnrin kan tára ẹ̀ ò yá tó sùn sórí bẹ́ẹ̀dì lóúnjẹ.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ “FARA BALẸ̀ KÍYÈ SÍ ÀWỌN OHUN TÍ JÈHÓFÀ ṢE NÍTORÍ ÌFẸ́ RẸ̀ TÍ KÌ Í YẸ̀,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn?

  • Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ yááfì àwọn nǹkan kan tá a bá fẹ́ fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́