ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | HÓSÉÀ 1-7
Ṣé Inú Rẹ Máa Ń Dùn sí Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Bíi Ti Jèhófà?
Ẹni tó bá ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́ olóòótọ́, ẹni tó ṣeé fọkàn tán, àdúrótini àti adúróṣinṣin. Jèhófà fi ọ̀rọ̀ Hóséà àti Gómérì ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ aláìṣòótọ́ kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìdáríjì.—Ho 1:2; 2:7; 3:1-5.
Báwo ni Gómérì ṣe fi hàn pé òun kò ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀?
Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé wọn kò ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀?
Báwo ni Hóséà ṣe fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn?
Báwo ni Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn?
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Báwo ni mo ṣe lè fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Jèhófà?