Ohun Táwọn Kan Sọ Nípa Àdúrà
“Tí mo bá ń gbàdúrà, ńṣe ló da bíi pé Ọlọ́run wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi tó dì mí lọ́wọ́ mú, tó sì ń tọ́ mi sọ́nà.”—MARÍA.
“Ìyàwó mi kú lẹ́yìn tí àrùn jẹjẹrẹ ti bá á fínra fún ọdún mẹ́tàlá (13). Mo rántí pé ojoojúmọ́ ni mo máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, mo sì mọ̀ pé nínú ìrora tí mo wà ó ń gbọ́ mi. Èyí sì mú kí ọkàn mi balẹ̀.”—RAÚL.
“Àdúrà jẹ́ ẹ̀bùn pàtàkì tí Ọlọ́run fún àwa èèyàn.”—ARNE.
Lójú María, Raúl, Arne àtàwọn míì, àdúrà jẹ́ ẹ̀bùn pàtàkì. Wọ́n gbà pé àdúrà làwọn lè fi bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, káwọn fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, káwọn sì fi wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. Wọ́n gbà pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ àdúrà, ó sọ pé: “Ohun tó dá wa lójú nípa rẹ̀ ni pé, tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.”—1 Jòhánù 5:14.
Àmọ́, ní ti ọ̀pọ̀ àwọn míì, ó ṣòro fún wọn láti gbà pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ àdúrà. Steve ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ àdúrà ṣe rí lára rẹ̀. Ó sọ pé: “Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) ni mí nígbà tí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí mẹ́ta nínú àwọn ọ̀rẹ́ mi, tí wọ́n sì kú. Ọ̀kan kú nínú jàǹbá ọkọ̀, òkun sì gbé àwọn méjì tó kù lọ.” Kí ni Steve wá ṣe? Ó ní: “Mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó sọ ìdí tí gbogbo nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀, àmọ́ mi ò rí ìdáhùn. Torí náà, mo bi ara mi pé, ‘Kí wá làǹfààní àdúrà tí mò ń gbà?’” Ọ̀pọ̀ ronú pé kò sídìí tó fi yẹ káwọn máa gbàdúrà, torí ó jọ pé Ọlọ́run ò gbọ́ àdúrà àwọn.
Àwọn èèyàn tún sọ ìdí míì tí kò fi yẹ káwọn máa gbàdúrà. Àwọn kan sọ pé torí Ọlọ́run mọ ohun gbogbo, ó mọ ohun táwọn nílò, ó mọ ìṣòro àwọn, torí náà kò sídìí táwọn á ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ fún un.
Àwọn míì gbà pé Ọlọ́run kò ní tẹ́tí sí àdúrà wọn torí àwọn àṣìṣe tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Jenny sọ pé: “Ìṣòro mi tó le jù ni pé mo máa ń rò pé mi ò já mọ́ nǹkan kan. Mò ń kábàámọ̀ àwọn nǹkan tí mo ti ṣe sẹ́yìn, torí ìyẹn, mo gbà pé Ọlọ́run ò lè gbọ́ àdúrà mi.”
Kí lèrò tìẹ nípa àdúrà? Tí ìwọ náà bá ti ń ṣiyè méjì lórí ọ̀rọ̀ àdúrà, fọkàn balẹ̀ pé wàá rí ìdáhùn tó máa tẹ́ ẹ lọ́rùn nínú Bíbélì. A lè fọkàn tán ohun tí Bíbélì bá sọ lórí ọ̀rọ̀ àdúrà.a Ó lè jẹ́ kó o rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè bíi:
Ṣé Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà wa lóòótọ́?
Kí nìdí tí Ọlọ́run kì í fi dáhùn àwọn àdúrà kan?
Báwo lo ṣe lè gbàdúrà kí Ọlọ́run sì gbọ́?
Àǹfààní wo lo máa rí nínú àdúrà?
a Àwọn àdúrà ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì, títí kan àwọn àdúrà tí Jésù gbà. A rí àwọn àdúrà tó lé ní àádọ́jọ (150) nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, táwọn èèyàn ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé.