ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 18
Ṣé Wàá Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Nípa Jésù Mú Kó O Kọsẹ̀?
“Aláyọ̀ ni ẹni tí kò rí ohunkóhun tó máa mú kó kọsẹ̀ nínú mi.”—MÁT. 11:6.
ORIN 54 “Èyí Ni Ọ̀nà”
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ló ṣeé ṣe kó yà ẹ́ lẹ́nu nígbà tó o kọ́kọ́ gbìyànjú láti wàásù fáwọn èèyàn?
ṢÉ O rántí bí inú ẹ ṣe dùn tó nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? O rí i pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ò lọ́jú pọ̀, ó sì rọrùn lóye. Lọ́kàn ẹ, ó dá ẹ lójú pé gbogbo èèyàn ló máa nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ yìí. O gbà pé òtítọ́ Bíbélì máa jẹ́ kí ìgbésí ayé wọn nítumọ̀ báyìí, á sì jẹ́ kí wọ́n ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. (Sm. 119:105) Torí náà, tọkàntara lo fi ń sọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí fáwọn mọ̀lẹ́bí ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ. Àmọ́ ó yà ẹ́ lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ni ò mọyì ohun tó ò ń sọ fún wọn.
2-3. Ojú wo ni ọ̀pọ̀ fi wo Jésù nígbà ayé rẹ̀?
2 Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu bí ọ̀pọ̀ èèyàn ò bá nífẹ̀ẹ́ sí ohun tá à ń wàásù. Ó ṣe tán, nígbà tí Jésù wà láyé, ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tó fi hàn pé Ọlọ́run ló fún un lágbára, tó sì ń tì í lẹ́yìn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò tẹ́tí sí i. Bí àpẹẹrẹ, ojú gbogbo èèyàn ló ṣe nígbà tí Jésù jí Lásárù dìde, síbẹ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù ò gbà pé òun ni Mèsáyà. Kódà, ṣe ni wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa pa Jésù àti Lásárù!—Jòh. 11:47, 48, 53; 12:9-11.
3 Jésù mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò ní gbà pé òun ni Mèsáyà. (Jòh. 5:39-44) Ó sọ fún àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jòhánù Arinibọmi pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí kò rí ohunkóhun tó máa mú kó kọsẹ̀ nínú mi.” (Mát. 11:2, 3, 6) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ò fi tẹ́tí sí Jésù?
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò ìdí tí ọ̀pọ̀ ò fi gba Jésù gbọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Àá tún rí ìdí tí ọ̀pọ̀ lónìí kì í fi tẹ́tí sí ìwàásù wa. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a máa rí ìdí tó fi yẹ ká ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jésù ká má bàa kọsẹ̀.
(1) IBI TÍ JÉSÙ DÀGBÀ SÍ
Ọ̀pọ̀ kọsẹ̀ nítorí ibi tí Jésù dàgbà sí. Báwo lèyí ṣe lè mú káwọn èèyàn kọsẹ̀ lónìí? (Wo ìpínrọ̀ 5)b
5. Kí ló ṣeé ṣe kó fà á táwọn kan fi ronú pé Jésù kọ́ ni Mèsáyà?
5 Ọ̀pọ̀ ló kọsẹ̀ torí ibi tí Jésù dàgbà sí. Wọ́n gbà pé kò sí olùkọ́ bíi Jésù àti pé ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu. Àmọ́ lójú wọn, ọmọ káfíńtà lásánlàsàn ni. Yàtọ̀ síyẹn Násárẹ́tì ló ti wá, àwọn èèyàn ò sì ka ìlú yìí sí pàtàkì rárá. Kódà, Nàtáníẹ́lì tó pa dà wá di ọmọlẹ́yìn Jésù sọ nígbà kan pé: “Ṣé ohun rere kankan lè wá láti Násárẹ́tì?” (Jòh. 1:46) Ó lè jẹ́ torí pé Nàtáníẹ́lì kì í fojú gidi wo àwọn tó wá láti ìlú yẹn, ó sì lè jẹ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Míkà 5:2 ló wà lọ́kàn ẹ̀ tó sọ pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n máa bí Mèsáyà náà sí, kì í ṣe Násárẹ́tì.
6. Kí ló yẹ kó mú kí àwọn èèyàn ìgbà yẹn gbà pé Jésù ni Mèsáyà?
6 Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ? Wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọ̀tá Jésù kò ní fiyè sí ‘kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìran tí Mèsáyà’ ti wá. (Àìsá. 53:8) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, gbogbo àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ yẹn ló wà lákọọ́lẹ̀. Ká sọ pé àwọn èèyàn yẹn fara balẹ̀ gbé àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ yẹn yẹ̀ wò ni, wọ́n á rí i pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n bí Jésù sí àti pé àtọmọdọ́mọ Ọba Dáfídì ni. (Lúùkù 2:4-7) Torí náà, ibi tí wọ́n bí Jésù sí bá àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Míkà 5:2 mu. Kí wá nìṣòro àwọn èèyàn náà? Ìṣòro wọn ni pé wọn ò ṣe ìwádìí dáadáa, wọn ò sì rídìí ọ̀rọ̀. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ wọn fi kọsẹ̀.
7. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fẹ́ tẹ́tí sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
7 Ṣé irú ìṣòro yìí wà lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Èyí tó pọ̀ jù lára àwa èèyàn Jèhófà ni ò lọ́rọ̀, a ò sì lẹ́nu láwùjọ. Torí náà, àwọn èèyàn máa ń fojú ẹni tí ‘ò kàwé àti gbáàtúù’ wò wá. (Ìṣe 4:13) Àwọn kan ronú pé a ò tóótun láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì torí pé a ò gboyè jáde nílé ẹ̀kọ́ àwọn pásítọ̀. Àwọn míì sọ pé “ìsìn àwọn ará Amẹ́ríkà” là ń ṣe bó tiẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lára wa ni ò gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Bẹ́ẹ̀ sì làwọn míì gbà pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò gba Jésù gbọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sọ pé a “máa ń da ìdílé rú.” Àwọn kan sọ pé “a máa ń dorí Bíbélì kodò,” nígbà táwọn míì ń pè wá ní “agbawèrèmẹ́sìn.” Ọ̀pọ̀ tó ń gbọ́rọ̀ yìí ò ṣèwádìí nípa wa, torí náà wọn kì í fetí sí wa, ìyẹn sì mú kí wọ́n kọsẹ̀.
8. Bó ṣe wà nínú Ìṣe 17:11, kí làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè dá àwọn tó ń sin Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́ mọ̀?
8 Kí lẹnì kan lè ṣe tí kò fi ní kọsẹ̀? Ó ṣe pàtàkì káwọn èèyàn ṣèwádìí kí wọ́n lè mohun tó jóòótọ́ nípa wa. Ohun tí Lúùkù tó kọ ọ̀kan lára àwọn Ìwé Ìhìn Rere ṣe nìyẹn. Ó rí i dájú pé òun “wádìí ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ lọ́nà tó péye.” Ó fẹ́ káwọn tó ń kàwé rẹ̀ mọ bí ohun tí wọ́n gbọ́ nípa Jésù “ṣe jẹ́ òótọ́ tó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Lúùkù 1:1-4) Àwọn Júù tó wà ní Bèróà náà ṣe bíi ti Lúùkù. Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere nípa Jésù, wọ́n lọ yẹ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù wò kí wọ́n lè mọ̀ bóyá òótọ́ lohun táwọn gbọ́. (Ka Ìṣe 17:11.) Lọ́nà kan náà, ó yẹ káwọn èèyàn máa ṣèwádìí dáadáa. Ó yẹ kí wọ́n ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kí wọ́n lè rí i dájú pé òótọ́ lohun táwa èèyàn Ọlọ́run fi ń kọ́ni. Ó tún yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa ìtàn àwa èèyàn Jèhófà lóde òní. Tí wọ́n bá fara balẹ̀ ṣe àwọn ìwádìí yìí, ohun táwọn èèyàn ń sọ kò ní mú wọn kọsẹ̀.
(2) JÉSÙ KỌ̀ LÁTI FI ÀMÌ HÀN
Ọ̀pọ̀ kọsẹ̀ nítorí pé Jésù ò fi àmì hàn wọ́n. Báwo lèyí ṣe lè mú káwọn èèyàn kọsẹ̀ lónìí? (Wo ìpínrọ̀ 9-10)c
9. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù kọ̀ láti fi àmì hàn láti ọ̀run?
9 Àwọn kan nígbà ayé Jésù gbà pé ó mọ̀ọ̀yàn kọ́ gan-an. Àmọ́ ìyẹn nìkan ò tẹ́ wọn lọ́rùn. Wọ́n ní kó “fi àmì kan han àwọn láti ọ̀run” káwọn lè gbà pé òun ni Mèsáyà lóòótọ́. (Mát. 16:1) Ó lè jẹ́ àṣìlóye ohun tó wà nínú Dáníẹ́lì 7:13, 14 ló mú kí wọ́n sọ bẹ́ẹ̀. Bó ti wù kó rí, kì í ṣe àsìkò yẹn ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí nímùúṣẹ. Ohun tí Jésù fi ń kọ́ni ti tó láti mú kí wọ́n mọ̀ pé òun ni Mèsáyà. Àmọ́ nígbà tó kọ̀ láti fi àmì tí wọ́n béèrè hàn wọ́n, ṣe ni wọ́n kọsẹ̀.—Mát. 16:4.
10. Báwo ni Jésù ṣe mú ohun tí Àìsáyà sọ nípa Mèsáyà ṣẹ?
10 Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ? Wòlíì Àìsáyà sọ nípa Mèsáyà pé: “Kò ní ké jáde tàbí kó gbé ohùn rẹ̀ sókè, kò sì ní jẹ́ ká gbọ́ ohùn rẹ̀ lójú ọ̀nà.” (Àìsá. 42:1, 2) Jésù ò pe àfiyèsí sí ara ẹ̀ nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣe àṣehàn. Jésù ò bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì tàbí kó wọ àwọn aṣọ oyè torí káwọn èèyàn lè gba tiẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbà káwọn èèyàn fi orúkọ oyè pe òun. Nígbà tí Jésù ń jẹ́jọ́ níwájú Ọba Hẹ́rọ́dù, kò ṣe iṣẹ́ àmì kó lè rí ojúure ọba náà. (Lúùkù 23:8-11) Òótọ́ ni pé Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, àmọ́ iṣẹ́ ìwàásù ló kà sí pàtàkì jù. Ó tiẹ̀ sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Torí ìdí tí mo ṣe wá nìyí.”—Máàkù 1:38.
11. Èrò tí ò tọ̀nà wo làwọn kan ní lónìí?
11 Ṣé irú ìṣòro yìí wà lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ohun tó ń mú kí ọ̀pọ̀ máa dara pọ̀ mọ́ ìsìn làwọn ilé ìjọsìn ńláńlá tó jojú ní gbèsè, àwọn aṣáájú ìsìn tó lórúkọ oyè kàǹkà-kàǹkà àtàwọn ayẹyẹ tí wọn ò mọbi tó ti ṣẹ̀ wá. Àmọ́, kí ni wọ́n ń rí kọ́ láwọn ilé ìjọsìn yẹn? Ṣé wọ́n mọ̀ nípa Ọlọ́run àtohun tó ní lọ́kàn láti ṣe? Lọ́wọ́ kejì, àwọn tó ń wá sáwọn ìpàdé wa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ṣe àti bí wọ́n ṣe lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa mọ níwọ̀n, wọ́n sì máa ń wà ní mímọ́. Àwọn tó ń múpò iwájú kì í wọ aṣọ oyè, wọn ò sì ní orúkọ oyè. Orí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la gbé gbogbo ẹ̀kọ́ wa àti ìgbàgbọ́ wa kà. Láìfi gbogbo nǹkan yìí pè, ọ̀pọ̀ èèyàn ló kọsẹ̀ torí wọ́n gbà pé ọ̀nà ìjọsìn wa ti tutù jù àti pé a kì í ṣe bíi tàwọn míì. Bákan náà, ohun tá à ń wàásù rẹ̀ kò bá wọn lára mu.
12. Bó ṣe wà nínú Hébérù 11:1, 6, kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè ní ìgbàgbọ́?
12 Kí la lè ṣe tá ò fi ní kọsẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni tó ń gbé nílùú Róòmù pé: “Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́. Ohun tí a gbọ́ sì jẹ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Kristi.” (Róòmù 10:17) Torí náà, ohun tó lè mú kéèyàn ní ìgbàgbọ́ tó lágbára ni pé kó máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kì í ṣe kó máa lọ́wọ́ nínú àwọn ayẹyẹ tí kò bá Bíbélì mu, bó ti wù kí ayẹyẹ náà gbádùn mọ́ àwọn èèyàn tó. Ó ṣe pàtàkì ká ní ìmọ̀ tó péye ká lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára torí pé “láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa.” (Ka Hébérù 11:1, 6.) Nípa bẹ́ẹ̀, kò dìgbà tá a bá rí àmì kan láti ọ̀run ká tó gbà pé a ti rí òtítọ́. Tá a bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn nìkan ti tó láti mú kó dá wa lójú pé a ti rí òtítọ́, a ò sì ní ṣiyèméjì.
(3) JÉSÙ Ò TẸ̀ LÉ Ọ̀PỌ̀ NÍNÚ ÀṢÀ ÀWỌN JÚÙ
Ọ̀pọ̀ kọsẹ̀ nítorí pé Jésù bẹnu àtẹ́ lu àwọn àṣà wọn kan. Báwo lèyí ṣe lè mú káwọn èèyàn kọsẹ̀ lónìí? (Wo ìpínrọ̀ 13)d
13. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ fi bẹnu àtẹ́ lu Jésù?
13 Ó ya àwọn ọmọlẹ́yìn Jòhánù Arinibọmi lẹ́nu pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kì í gbààwẹ̀. Jésù ṣàlàyé fún wọn pé kò sídìí tí àwọn ọmọlẹ́yìn òun fi máa gbààwẹ̀ nígbà tóun ṣì wà láyé. (Mát. 9:14-17) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Farisí àtàwọn alátakò Jésù bẹnu àtẹ́ lù ú torí pé kò tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn. Inú bí wọn nígbà tó wo àwọn èèyàn sàn lọ́jọ́ Sábáàtì. (Máàkù 3:1-6; Jòh. 9:16) Àwọn èèyàn yìí gbà pé àwọn ń pa Sábáàtì mọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé, wọn ò rí ohun tó burú nínú bí wọ́n ṣe ń ṣòwò nínú tẹ́ńpìlì. Wọ́n gbaná jẹ nígbà tí Jésù dẹ́bi fún wọn nítorí òwò tí wọ́n ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì. (Mát. 21:12, 13, 15) Bákan náà, àwọn tí Jésù wàásù fún nínú sínágọ́gù tó wà ní Násárẹ́tì bínú gidigidi nígbà tó sọ ìtàn kan tó jẹ́ kó hàn gbangba pé onímọtara-ẹni-nìkan ni wọ́n, wọn ò sì nígbàgbọ́. (Lúùkù 4:16, 25-30) Ohun tí wọ́n retí pé kí Jésù ṣe àmọ́ tí ò ṣe mú kí ọ̀pọ̀ kọsẹ̀.—Mát. 11:16-19.
14. Kí nìdí tí Jésù fi dẹ́bi fún àwọn tó ń gbé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ lárugẹ?
14 Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ? Jèhófà gbẹnu wòlíì Àìsáyà sọ pé: “Àwọn èèyàn yìí ń fi ẹnu wọn sún mọ́ mi, wọ́n sì ń fi ètè wọn bọlá fún mi, àmọ́ ọkàn wọn jìnnà gan-an sí mi; àṣẹ èèyàn tí wọ́n kọ́ wọn ló sì ń mú kí wọ́n máa bẹ̀rù mi.” (Àìsá. 29:13) Ó tọ́, ó sì yẹ bí Jésù ṣe dẹ́bi fún àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Yàtọ̀ sí pé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ yìí ò bá Ìwé Mímọ́ mu, ńṣe làwọn tó ń gbé wọn lárugẹ tún kọ Jèhófà àti Mèsáyà tó rán wá sáyé.
15. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ fi ń bínú sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
15 Ṣé irú ìṣòro yìí wà lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Inú máa ń bí ọ̀pọ̀ èèyàn tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò bá bá wọn ṣe ayẹyẹ tí kò bá Bíbélì mu bí ọjọ́ ìbí àti Kérésìmesì. Àwọn míì máa ń bínú sí wa torí pé a kì í lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ orílẹ̀-èdè tàbí àwọn àṣà ìsìnkú tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Àwọn tó ń bínú sí wa torí àwọn nǹkan yìí lè ronú pé ọ̀nà tó tọ́ làwọn ń gbà jọ́sìn Ọlọ́run. Àmọ́, kò sí bí wọ́n ṣe lè múnú Ọlọ́run dùn tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ dípò ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni.—Máàkù 7:7-9.
16. Kí ló yẹ ká ṣe, kí sì ni kò yẹ ká ṣe bó ṣe wà nínú Sáàmù 119:97, 113, 163-165?
16 Kí la lè ṣe tá ò fi ní kọsẹ̀? A gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà. (Ka Sáàmù 119:97, 113, 163-165.) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò ní lọ́wọ́ sí àṣà èyíkéyìí tó kórìíra. Nípa bẹ́ẹ̀, a ò ní nífẹ̀ẹ́ ohunkóhun míì ju Jèhófà lọ.
(4) JÉSÙ Ò DÁ SÍ Ọ̀RỌ̀ ÒṢÈLÚ
Ọ̀pọ̀ kọsẹ̀ nítorí pé Jésù ò dá sọ́rọ̀ òṣèlú. Báwo lèyí ṣe lè mú káwọn èèyàn kọsẹ̀ lónìí? (Wo ìpínrọ̀ 17)e
17. Kí lọ̀pọ̀ èèyàn ń retí pé kí Jésù ṣe?
17 Nígbà ayé Jésù, ọ̀pọ̀ èèyàn ń wá bí wọ́n ṣe máa kúrò lábẹ́ àjàgà àwọn Róòmù, wọ́n sì retí pé Mèsáyà ló máa dá wọn nídè. Àmọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ fi Jésù jọba, ṣe ló kọ̀ jálẹ̀. (Jòh. 6:14, 15) Ẹ̀rù ń ba àwọn míì, títí kan àwọn àlùfáà pé Jésù fẹ́ gbé ìjọba kan kalẹ̀. Wọ́n gbà pé ìyẹn máa múnú bí àwọn ará Róòmù torí pé ìjọba Róòmù ti fún àwọn àlùfáà yẹn ní àṣẹ déwọ̀n àyè kan. Àwọn nǹkan yìí ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn Júù kọsẹ̀.
18. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo nípa Mèsáyà ni ọ̀pọ̀ ò fiyè sí?
18 Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ? Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ló sọ pé Mèsáyà máa jẹ́ ajagunṣẹ́gun. Àmọ́, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì sọ pé ó máa kọ́kọ́ kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Àìsá. 53:9, 12) Kí wá nìdí tí àwọn Júù fi ní èrò tí ò tọ́ nípa Mèsáyà? Ìdí ni pé nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ṣe lọ̀pọ̀ àwọn Júù máa ń gbójú fo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé Mèsáyà kò ní yanjú ìṣòro wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.—Jòh. 6:26, 27.
19. Kí làwọn èèyàn retí pé káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe lónìí?
19 Ṣé irú ìṣòro yìí wà lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọ̀pọ̀ èèyàn kórìíra wa torí pé a kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, wọ́n retí pé ó yẹ ká máa dìbò. Àmọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ kó ṣe kedere sí wa pé lójú Jèhófà, tá a bá yan èèyàn láti máa ṣàkóso wa, ṣe là ń kọ Jèhófà sílẹ̀. (1 Sám. 8:4-7) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn retí pé ó yẹ ká máa kọ́ ilé ìwé àti ilé ìwòsàn, ká sì máa ṣe àwọn nǹkan míì fún ìdàgbàsókè ìlú. Inú wọn ò dùn torí pé iṣẹ́ ìwàásù la gbájú mọ́ dípò ká wá bá a ṣe máa yanjú ìṣòro ayé yìí.
20. Kí ló yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wa bí Jésù ṣe sọ nínú Mátíù 7:21-23?
20 Kí la lè ṣe tá ò fi ní kọsẹ̀? (Ka Mátíù 7:21-23.) Ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù sí wa ni bá a ṣe máa ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa. (Mát. 28:19, 20) A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn nǹkan tó ń lọ lágbo òṣèlú àtàwọn nǹkan míì pín ọkàn wa níyà. A nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ wá lógún. Àmọ́, ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.
21. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
21 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti jíròrò àwọn nǹkan mẹ́rin tó mú káwọn Júù kọsẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọn ò sì gba Jésù ní Mèsáyà. A sì tún sọ bí àwọn nǹkan yẹn ṣe mú káwọn èèyàn kórìíra àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí. Àmọ́, ṣé àwọn nǹkan mẹ́rin yẹn nìkan ló lè mú ká kọsẹ̀? Rárá o. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a tún máa jíròrò àwọn nǹkan mẹ́rin míì tó lè fa ìkọ̀sẹ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá ṣe ohun táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, a ò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun mú wa kọsẹ̀!
ORIN 56 Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ
a Nínú àwọn tó tíì gbé láyé, Jésù ló mọ̀ọ̀yàn kọ́ jù. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló kọsẹ̀ nígbà ayé ẹ̀ nítorí ohun tó sọ tàbí ohun tó ṣe. Kí nìdí? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ìdí mẹ́rin tí wọn ò fi tẹ̀ lé e. A tún máa rí ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi fetí sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lónìí. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a máa rí ìdí tó fi yẹ ká ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jésù ká má bàa kọsẹ̀.
b ÀWÒRÁN: Fílípì sọ fún Nàtáníẹ́lì pé kó wá wo Jésù.
c ÀWÒRÁN: Jésù ń wàásù ìhìn rere.
d ÀWÒRÁN: Jésù wo ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ rọ sàn níṣojú àwọn alátakò.
e ÀWÒRÁN: Jésù lọ sí orí òkè ní òun nìkan.