ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 5-6
Ní Èrò Tó Tọ́ Bó O Ṣe Ń Tẹ̀lé Jésù
Nígbà tí Jésù lo àpèjúwe tó nira fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti lóye, àwọn kan kọsẹ̀, wọn ò sì tẹ̀ lé Jésù mọ́. Ní ọjọ́ kan ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù fún gbogbo wọn ní oúnjẹ lọ́nà ìyanu, wọ́n sì fojú ara wọn rí i pé àtọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni agbára rẹ̀ ti wá. Kí wá nìdí tí wọ́n fi kọsẹ̀? Ó hàn pé torí nǹkan tí wọ́n máa rí gbà ni wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé Jésù.
Ó yẹ kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Kí nìdí tí mo fi ń tẹ̀ lé Jésù? Ṣé torí àwọn ìbùkún tí mò ń gbádùn báyìí àtèyí tí màá gbádùn lọ́jọ́ iwájú ni? Àbí torí mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí mo sì fẹ́ múnú rẹ̀ dùn?’
Kí nìdí tó fi ṣeé sẹ ká kọsẹ̀ tó bá jẹ́ pé torí àwọn nǹkan tó wà nísàlẹ̀ yìí nìkan la ṣe ń sin Jèhófà?
À ń gbádùn bá a ṣe wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run
A fẹ́ gbé nínú Párádísè