ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w22 February ojú ìwé 30
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ètò Gbígba Owó Orí Ìyàwó Tó Mọ Níwọ̀n
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • “Ìgbéyàwó Ìbílẹ̀” ní Gánà
    Jí!—1996
  • Mímúra Sílẹ̀ fún Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ipa-iṣẹ́ Oníyì Ti Àwọn Obìnrin Láàárín Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọrun Ní Ìjímìjí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
w22 February ojú ìwé 30
Ọkùnrin ọmọ Ísírẹ́lì kan mú màlúù wá fún bàbá àfẹ́sọ́nà ẹ̀ láti fi san owó orí ìyàwó.

Wọ́n máa ń fi ẹran san owó orí ìyàwó

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ fi máa ń san owó orí ìyàwó?

LÁYÉ ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọjọ́ tí ọmọbìnrin kan bá ń lọ sílé ọkọ ni ìdílé ọkọ náà máa ń san owó orí ìyàwó. Wọ́n máa ń fi àwọn nǹkan tó ṣeyebíye, owó àti ẹran san owó orí ìyàwó. Nígbà míì, wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ àṣekára láti fi san owó orí ìyàwó, irú èyí tí Jékọ́bù ṣe nígbà tó ṣiṣẹ́ fún bàbá Réṣẹ́lì fún odindi ọdún méje. (Jẹ́n. 29:17, 18, 20) Àmọ́, kí nìdí tí wọ́n fi máa ń san owó orí ìyàwó?

Ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan tó ń jẹ́ Carol Meyers sọ pé: “Wọ́n máa ń san owó orí ìyàwó láti fi dípò iṣẹ́ tó yẹ kí ọmọbìnrin náà máa ṣe lóko ìdílé wọn.” Yàtọ̀ síyẹn, owó orí tí wọ́n bá san máa jẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín ìdílé méjèèjì túbọ̀ lágbára. Ìyẹn sì máa ń mú kí wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Bákan náà, owó orí yẹn máa ń fi hàn pé ọmọbìnrin kan ti ní àfẹ́sọ́nà, ó sì ti ń lọ sílé ọkọ ẹ̀.

Ti pé wọ́n san owó orí ìyàwó ò túmọ̀ sí pé ọmọbìnrin náà ò já mọ́ nǹkan kan tàbí pé nǹkan tí wọ́n lè fowó rà ni. Ìwé Ancient Israel​—Its Life and Institutions sọ pé: “Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa ń san owó tàbí àwọn nǹkan míì fún ìdílé ọmọbìnrin kan tí wọ́n fẹ́ gbé níyàwó máa ń jẹ́ kó dà bíi pé ṣe ni wọ́n ń ra ọmọbìnrin náà. Àmọ́, ó jọ pé àsanfidípò fún ìdílé náà ni wọ́n ń fi owó orí náà ṣe, kì í ṣe láti fi ra ọmọbìnrin náà.”

Láwọn orílẹ̀-èdè kan lónìí, àwọn èèyàn ṣì máa ń san owó orí ìyàwó. Táwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni bá ní kí àwọn àna wọn san owó orí ìyàwó, wọ́n máa “jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé [àwọn] ń fòye báni lò” tí wọn ò bá béèrè ohun tó pọ̀ jù. (Fílí. 4:5; 1 Kọ́r. 10:32, 33) Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á fi hàn pé àwọn ò “nífẹ̀ẹ́ owó,” àwọn ò sì lójú kòkòrò. (2 Tím. 3:2) Yàtọ̀ síyẹn, táwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ò bá béèrè ohun tó pọ̀ jù, ẹni tó ń fẹ́ ọmọ wọn sọ́nà ò ní máa sún ìgbéyàwó náà síwájú torí kó lè rí owó tó máa kájú ohun tí wọ́n béèrè. Kò sì ní ronú pé kóun fiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀ kóun lè lọ wáṣẹ́ tó máa mówó gidi wọlé láti fi san owó orí náà.

Láwọn ibì kan, òfin máa ń sọ iye owó orí ìyàwó táwọn òbí lè gbà. Láwọn ibi tí irú òfin bẹ́ẹ̀ bá wà, ó yẹ káwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni tẹ̀ lé òfin náà. Kí nìdí? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé káwa Kristẹni “máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ onípò gíga,” ká sì máa ṣègbọràn sí wọn tí ohun tí wọ́n béèrè ò bá ti ta ko òfin Ọlọ́run.​—Róòmù 13:1; Ìṣe 5:29.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́