“Ìgbéyàwó Ìbílẹ̀” ní Gánà
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÁNÀ
ÌGBÉYÀWÓ—ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn jákèjádò ayé ní ń kó wọnú ipò ìbátan yìí lọ́dọọdún. Wọ́n sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àṣà ìgbéyàwó tí ó wọ́pọ̀ níbi tí wọ́n ń gbé.
Ní Gánà, irú ìgbéyàwó tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ni èyí tí a pè ní ìgbéyàwó ìbílẹ̀. Èyí kan kí ìdílé ọkọ san nǹkan orí ìyàwó fún ìdílé ìyàwó. Àwọn ènìyàn ń ṣe ìgbéyàwó ìbílẹ̀ níbi púpọ̀ ní Áfíríkà àti ní àwọn ilẹ̀ bíi Hong Kong, Papua New Guinea, àti Solomon Islands bákan náà láàárín àwọn ará Íńdíà ti Goajiro ní ìhà ìlà oòrùn àríwá Colombia àti ìhà ìwọ̀ oòrùn àríwá Venezuela, kí a dárúkọ ìwọ̀nba díẹ̀.
Sísan nǹkan orí ìyàwó jẹ́ àṣà kan ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì. (Jẹ́nẹ́sísì 34:11, 12; Sámúẹ́lì Kìíní 18:25) Òye tí ó wà nígbà ìjímìjí àti lónìí ni pé nǹkan orí ìyàwó jẹ́ àsanfidípò fún àwọn òbí ọmọdébìnrin náà fún pípàdánù iṣẹ́ tí ó ń ṣe fún wọn àti fún àkókò, agbára, àti ohun tí wọ́n ti ná lórí ẹ̀kọ́ àti ìtọ́jú rẹ̀ kí ó tó ṣègbéyàwó.
Ẹrù Iṣẹ́ Òbí
Ní Gánà, láyé àtijọ́, dídá ọjọ́ àjọròde àti ìfẹ́sọ́nà kò sí láàárín àwọn ọ̀dọ́. Àwọn òbí ní ń wọnú àdéhùn ìgbéyàwó fún àwọn ọmọ wọn tí wọ́n ti dàgbà, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fi tìṣọ́ratìṣọ́ra wádìí nípa àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin tí ó ṣeé fẹ́ láwùjọ wọn. Àwọn òbí kan ṣì ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní Gánà.
Àwọn òbí ọmọdékùnrin náà yóò gbé àwọn kókó bí àkópọ̀ ìwà ọmọdébìnrin náà; ìfùsì rẹ̀ àti ti ìdílé rẹ̀; àwọn àrùn àjogúnbá tí ó wà nínú ìdílé; àti ipò tẹ̀mí rẹ̀, nínú ọ̀ràn ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, yẹ̀ wò. Bí ó bá tẹ́ àwọn òbí náà lọ́rùn, wọn óò tọ àwọn òbí ọmọdébìnrin náà lọ, wọn óò sì sọ̀rọ̀ nípa gbígbé e níyàwó.
Àwọn òbí ọmọdébìnrin náà yóò wá wádìí ìpìlẹ̀ ìgbésí ayé ọmọdékùnrin náà àti ìdílé rẹ̀. Ní àfikún sí àwọn kókó tí a mẹ́nu kàn lókè, wọn óò gbé ìtóótun ọmọdékùnrin náà láti pèsè fún ìyàwó yẹ̀ wò—ṣé ó ń ṣiṣẹ́ tàbí kò níṣẹ́ lọ́wọ́? Bí ó bá tẹ́ àwọn òbí ọmọdébìnrin náà lọ́rùn, wọn óò sọ fún àwọn òbí ọmọdékùnrin náà, àwọn òbí náà yóò sì jùmọ̀ ṣètò gbogbo ohun tí ó yẹ nípa ìgbéyàwó náà, lẹ́yìn tí ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin náà bá ti jọ́hẹn.
Kí ló dé tí àwọn òbí kan ṣì máa ń wá alábàáṣègbéyàwó fún àwọn ọmọ wọn tó ti dàgbà? Obìnrin kan tí àwọn òbí rẹ̀ ṣètò ìgbéyàwó rẹ̀ ní Íńdíà sọ pé: “Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe lè tóótun láti ṣe irú ìpinnu ńlá bẹ́ẹ̀? Ó sàn jù láti jẹ́ kí àwọn tí ọjọ́ orí àti ìrírí wọn mú wọn tóótun láti mọ yíyàn tí ó bọ́gbọ́n mu jù lọ ṣe é.” Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún gbé ojú ìwòye ọ̀pọ̀ àwọn ará Áfíríkà yọ.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìgbà ń yí padà ní Gánà. Dídá ọjọ́ àjọròde àti ìfẹ́sọ́nà ń gbajúmọ̀ sí i. Ní àkókò kan tí ó bá a mu wẹ́kú nínú ìfẹ́sọ́nà, àwọn méjèèjì náà yóò sọ ohun tí wọ́n ń gbèrò fún àwọn òbí wọn. Lẹ́yìn ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ láàárín àwọn òbí wọn àti lẹ́yìn tí ó bá ti dá àwọn òbí náà lójú pé wọ́n bá ara wọn mu, àwọn ìdílé náà yóò ṣe ayẹyẹ elétò àṣà tí a mọ̀ sí ìkanlẹ̀kùn, ilẹ̀kùn ìgbéyàwó, ní àwọn èdè bíi mélòó kan ní Gánà.
Ayẹyẹ Ìkanlẹ̀kùn
Àwọn òbí àwọn méjèèjì yóò sọ fún àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wọn nípa déètì àti ète ìpàdé náà. Èdè ọ̀rọ̀ náà “àwọn mẹ́ḿbà ìdílé” ní Áfíríkà tọ́ka sí àwọn mọ̀lẹ́bí, tí ó ní nínú, àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò òbí àwọn alájọṣègbéyàwó náà lọ́kùnrin, lóbìnrin, àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n àti àbúrò òbí, àwọn òbí àgbà. Ní ọjọ́ tí wọ́n bá dá, àwọn aṣojú láti ìdílé méjèèjì yóò kóra jọ fún ayẹyẹ náà. Kì í ṣe dandan kí ọkọ ìyàwó wà níbẹ̀. Abala ráńpẹ́ nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ níbi ayẹyẹ ìkanlẹ̀kùn kan nìyí.
Alága ìjókòó: [Ó ń bá àwọn aṣojú ọkọ ìyàwó sọ̀rọ̀] A mọ ìdí tí ẹ ṣe wá, ṣùgbọ́n àṣà béèrè pé kí a ṣì béèrè, Kí ló gbé e yín wá síbí o?
Alága ìdúró: Ọmọkùnrin wa Kwasi ń kọjá lọ níbi ilé yín, ó sì rí òdòdó rírẹwà kan, ó sì fẹ́ kí ẹ fún òun láṣẹ láti já a.
Alága ìjókòó: [Ó ń díbọ́n] Kò sí òdòdó kankan ní ilé yìí. Ẹ lè wò ó fúnra yín o.
Alága ìdúró: Ọmọ wa kò ṣàṣìṣe. A ṣì ń sọ ọ́ pé òdòdó rírẹwà kan wà ní ilé yìí. Orúkọ òdòdó náà ní Afi.
Alága ìjókòó: Òdòdó abẹ̀mí lẹ̀ ń sọ nígbà náà. Ó dára, ibí ni Afi ń gbé.
Alága ìdúró: A fẹ́ kanlẹ̀kùn, kí a sì bẹ̀bẹ̀ pé kí Afi fẹ́ ọmọkùnrin wa, Kwasi.
Ìdílé ọmọdékùnrin náà wá gbé àwọn ohun kan sílẹ̀, bí onírúurú ọtí àti owó díẹ̀. Láti ẹ̀yà kan sí òmíràn, ohun tí wọ́n ń gbé sílẹ̀ àti bí ó ṣe pọ̀ tó ń yàtọ̀ síra. Ayẹyẹ yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ dọ́gba pẹ̀lú ọ̀nà tí àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé ń gbà ṣe ìkówọnú àdéhùn ìgbéyàwó, àti nínú àwọn ọ̀ràn kan, wọ́n máa ń béèrè fún òrùka àdéhùn ìgbéyàwó.
Aṣojú ìyàwó yóò wá béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin náà lójú gbogbo òǹwòran bóyá kí wọ́n gba àwọn ohun tí wọ́n gbé wá. Nípa ìjọ́hẹn rẹ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí ojúkojú sí ìfẹ́ rẹ̀ láti fọ́kọ. Wọn óò fohùn ṣọ̀kan lórí déètì kan tí ó wọ̀ fún àwọn ìdílé méjèèjì láti wá san nǹkan orí ìyàwó àti láti ṣègbéyàwó. Wọn óò jẹ ìpápánu láti fòpin sí ayẹyẹ náà.
Ayẹyẹ Ìgbéyàwó
Iye àwọn ènìyàn tí wọ́n kóra jọ sílé ọmọdébìnrin náà tàbí ilé aṣojú tí a yàn fún sísan nǹkan orí ìyàwó àti ìgbéyàwó sábà máa ń pọ̀ ju iye àwọn tí wọ́n ń wá fún ayẹyẹ ìkanlẹ̀kùn. Èyí jẹ́ nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ló wá lọ́tẹ̀ yìí.
Ìdùnnú ṣubú layọ̀ níbẹ̀. Àwọn àpọ́n àti ọmọge ń fojú sọ́nà láti rí ohun tí wọ́n rà fún ìyàwó. Ṣùgbọ́n ayọ̀ tí ń ṣù rànyìn níbẹ̀ yóò lọ́ tín-ínrín nígbà tí ìdílé ìyàwó bá ń ráhùn pé nǹkan orí ìyàwó kò pé. Ọkàn àwọn kan nínú àwùjọ náà kò ní balẹ̀ nígbà tí ó bá jọ pé àwọn ìdílé ìyàwó yarí. Alága ìdúró fi òye ṣàlàyé débi tí àwọn ìdílé ìyàwó yóò fi gba tiwọn rò. Ọkàn yóò balẹ̀ nígbà tí ìdílé ọmọdébìnrin náà bá ṣàánú wọn. Ipò nǹkan yóò tún yí padà. Ní báyìí, àríyá ló kàn, wọ́n óò sì fún àwọn ènìyàn ní ìpápánu ní ráńpẹ́.
Lẹ́yìn náà, alága ìjókòó yóò ní kí àwùjọ dákẹ́, yóò sì kí gbogbo wọn káàbọ̀. Yóò bi aṣojú ọkọ ìyàwó léèrè ohun tí wọ́n wá ṣe. Alága ìdúró yóò sọ ìdí tí wọ́n fi wá, yóò sì rán àwùjọ létí pé àwọ́n ti kanlẹ̀kùn tẹ́lẹ̀, a sì ti gba àwọn láyè láti wọlé.
Alága ìdúró ìdílé kọ̀ọ̀kan yóò wá fi àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí wọ́n sún mọ́ra gan-an han àwùjọ, títí kan ẹni tí ń fa ọmọ fún ọkọ àti ẹni tí ó jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà ọmọdékùnrin náà. Ayẹyẹ náà ń bá a lọ.
Alága ìjókòó: [Ó ń bá àwọn aṣojú ọkọ ìyàwó sọ̀rọ̀] Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbé nǹkan ìyàwó tí a béèrè fún wá.
Alága ìdúró ka àwọn nǹkan orí ìyàwó, kí gbogbo ènìyàn lè jẹ́rìí sí i pé ó pé. Bí àwọn aṣojú ọkọ ìyàwó bá ronú pé ìdílé ìyàwó ti béèrè ohun tí ó pọ̀ jù, wọn óò yanjú ọ̀ràn náà ní bòókẹ́lẹ́ kí ọjọ́ ìgbéyàwó tó pé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìdílé ọkọ yóò múra wá síbi ayẹyẹ náà láti dúnàádúrà lórí dídín èlé èyíkéyìí kù bí àwọn kan ní ìdílé ìyàwó bá gbé ọwọ́ líle. Ibi yòó wù kí ènìyàn lè máa gbé, gbogbo nǹkan orí ìyàwó tí a máa ń béèrè fún, tí a ti fohùn ṣọ̀kan lé lórí—yálà ó pọ̀ tàbí ó kéré—ni a ní láti san tán.
Àwọn ìdílé kan máa ń béèrè fún nǹkan bíi gbẹ̀dẹ̀ ọrùn, yẹtí, àti àwọn nǹkan èlò obìnrin mìíràn. Ní ìhà àríwá Gánà, nǹkan orí ìyàwó lè ní iyọ̀, obì, ẹyẹ awó, àgùntàn, kódà màlúù pàápàá nínú. Owó sábà máa ń jẹ́ apá kan nǹkan orí ìyàwó.
Nígbà tí wọ́n bá ń bá ìdúnàádúrà náà lọ, ìyàwó kì í sí níbẹ̀, ṣùgbọ́n ó ń wà nítòsí, tí ó ń wòran. Kì í ṣe dandan kí ọkọ ìyàwó wà níbẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹnì kan tí ń gbé ìdálẹ̀ lè ní kí àwọn òbí rẹ̀ lọ ṣètò ìgbéyàwó náà fún òun. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìgbà àṣeyẹ tí a ń ṣàpèjúwe níhìn-ín, ọkọ ìyàwó wà níbẹ̀. Ó wá kan ìdílé tirẹ̀ láti béèrè nǹkan.
Alága ìdúró: A ti san gbogbo ohun tí ẹ ní kí a mú wá, ṣùgbọ́n a kò tí ì rí ìyàwó wa.
Ayẹyẹ ìgbéyàwó náà kì í ṣe ohun tí a mú le dan-indan-in; ó tún jẹ́ àkókò ìdápàárá. Ìdílé ọmọdébìnrin náà wá fèsì sí ohun tí ìdílé ọmọdékùnrin náà béèrè fún láti rí ìyàwó.
Alága ìjókòó: Ó wù wá kí ìyàwó wà níbí. Ó dùn wá pé ó ti lọ sí òkè òkun, a kò sì ní ìwé àṣẹ ìrìn àjò tàbí òǹtẹ̀ àṣẹ ìwọ̀lú láti lọ mú un wá.
Gbogbo ènìyàn mọ ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìdílé ọkọ ìyàwó yóò gbé owó sílẹ̀—iyekíye tí ọkọ ìyàwó bá lágbára—ní wàràǹṣeṣà! ìwé àṣẹ ìrìn àjò àti òǹtẹ̀ àṣẹ ìwọ̀lú tí a finú wòye náà yóò ti délẹ̀. Ìyàwó yóò sì ti dé láti ìdálẹ̀!
Láti fi kún àpárá náà, àwọn ẹ̀yà kan máa ń ṣètò kí àwọn ọ̀rẹ́ ìyàwó díẹ̀ ṣe bí ìyàwó. Àwọn àwùjọ ń kọ ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó ṣe bí ìyàwó, títí di ìgbà tí ìyàwó gidi bá dé bí wọ́n ti ń pàtẹ́wọ́ iyì fún un. Alága ìjókòó yóò wá ké sí i láti wo oríṣiríṣi ohun tí ó wà nínú nǹkan orí rẹ̀. Wọ́n óò bi í léèrè bóyá kí wọ́n gba ohun tí ọkọ ìyàwó gbé wá. Gbogbo nǹkan yóò pa rọ́rọ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń fi pẹ̀lú ìháragàgà dúró láti gbọ́ ìdáhùn. Àwọn ọmọdébìnrin kan jẹ́ onítìjú, àwọn mìíràn sì jẹ́ onígboyà, ṣùgbọ́n ìdáhùn náà sábà máa ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, tí àtẹ́wọ́ iyì yóò sì máa sọ lálá lẹ́yìn náà.
Bí ọkọ ìyàwó bá wà níbẹ̀, ìdílé ìyàwó yóò fẹ́ láti mọ̀ ọ́n. Àpárá náà ń lọ láìsọsẹ̀ bí wọ́n bá ti ṣètò fún ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ láti ṣe bí ọkọ ìyàwó. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde, ó ń ṣe bí ẹni pàtàkì, ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn pariwo lé e lọ.
Àwọn òbí ìyàwó béèrè pé àwọ́n fẹ́ rí ọkọ ọmọ àwọn. Ọkọ ìyàwó gidi yóò wá dìde sókè, tí ó ń yọ̀ ṣìnkìn pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́. Ìdílé ìyàwó yóò jẹ́ kí ìyàwó lọ bá ọkọ rẹ̀, tí yóò ki òrùka bọ̀ ọ́ lọ́wọ́ bí wọ́n bá béèrè rẹ̀ mọ́ nǹkan orí ìyàwó. Òrùka jẹ́ ohun tuntun kan tí ó wá láti Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Òun náà yóò ki òrùka bọ̀ ọ́ lọ́wọ́. Ìbániyọ̀ àti ìdùnnú yóò gbalẹ̀ kan. Nítorí ìrọ̀rùn àti ìṣúnná owó, lákòókò yìí, àwọn kan máa ń ṣe ayẹyẹ ìkanlẹ̀kùn àti ìgbéyàwó pọ̀ lọ́jọ́ kan náà.
Àwọn mẹ́ḿbà ìdílé méjèèjì àti àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n nírìírí yóò wá gba àwọn tọkọtaya tuntun náà nímọ̀ràn nípa bí wọ́n ṣe lè kẹ́sẹ járí nínú ìgbéyàwó wọn títí ìgbà tí ikú bá yà wọ́n. Láti fòpin sí ayẹyẹ ọjọ́ náà, wọn óò fún àwọn ènìyàn ní ìpápánu.
Ayẹyẹ ìgbéyàwó náà ti parí! Ní Gánà, láti ọjọ́ yẹn lọ, àwọn ènìyàn àdúgbò ti ka tọkùnrin-tobìnrin náà sí ẹni tí ó ti ṣègbéyàwó lọ́nà bíbófin mu. Bí èyíkéyìí lára àwọn ẹni pàtàkì-pàtàkì nínú mẹ́ḿbà ìdílé ọmọdébìnrin náà kò bá lè wá síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà nítorí àwọn ìdí kan, wọn óò fi lára àwọn ọtí tí a kó wá ránṣẹ́ sí i láti fi ẹ̀rí pé wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó náà hàn. Bí ọkọ àti ìyàwó bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn Ẹlẹ́rìí yóò wá ṣètò fún sísọ àwíyé Bíbélì, pẹ̀lú ìpápánu ráńpẹ́ lẹ́yìn náà.
Ní Gánà, àwọn tọkọtaya kan máa ń ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó ní ọ̀nà ti ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé, tí a ń pè ní ìgbéyàwó arédè, tàbí ìgbéyàwó lábẹ́ òfin ìjọba. A lè ṣe èyí yálà àwọn òbí jọ́hẹn tàbí wọn kò jọ́hẹn níwọ̀n bí tọkùnrin-tobìnrin náà bá ti dàgbà tó lábẹ́ òfin. Nínú ìgbéyàwó ìbílẹ̀, ìjọ́hẹn àwọn òbí di dandangbọ̀n.
Nínú ìgbéyàwó arédè, tọkùnrin-tobìnrin náà yóò jẹ́jẹ̀ẹ́ ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀jẹ́ nínú àwọn ìgbéyàwó ìbílẹ̀. Ìjọba ń béèrè pé kí a forúkọ àwọn ìgbéyàwó ìbílẹ̀ sílẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ń ṣègbọràn sí i. (Róòmù 13:1) Wọn óò wá fúnni ní ìwé ẹ̀rí ìforúkọsílẹ̀.
Láti ìgbà láéláé títí di ìgbà tí Gold Coast, tí ń jẹ́ Gánà nísinsìnyí, fi di agbègbè àtòkèèrèṣàkóso fún Britain, ìgbéyàwó ìbílẹ̀ ni irú ìgbéyàwó kan ṣoṣo tí ó wà ní orílẹ̀-èdè yẹn. Àwọn ará Britain wá mú ìgbéyàwó lọ́nà ti àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé wọlé fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wọn tí ń gbé ibẹ̀. Wọ́n gba àwọn ọmọ ilẹ̀ náà pẹ̀lú láyè láti kó wọnú irú ìgbéyàwó yìí, àti pé fún ọ̀pọ̀ ọdún báyìí, ìgbéyàwó lọ́nà ti ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé àti ìgbéyàwó ìbílẹ̀ ti jùmọ̀ wà. Ní Gánà, méjèèjì ni a gbà pé ó bófin mu, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì tipa bẹ́ẹ̀ tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Ó wá kù sọ́wọ́ olúkúlùkù láti yan irú èyí tí wọ́n fẹ́.
Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà, a ní láti lọ forúkọ ìgbéyàwó ìbílẹ̀ sílẹ̀ kí a tó lè ka tọkùnrin-tobìnrin kan sí ẹni tí ó ti ṣègbéyàwó lọ́nà bíbófin mu. Bí ó ti wù kí ó rí, ní Gánà, ìgbéyàwó ìbílẹ̀, bí a ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀ lókè fìdí múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó bófin mu láìsí ìforúkọsílẹ̀, tí a óò sì ka tọkọtaya náà sí ẹni tí ó ti ṣègbéyàwó lọ́nà bíbófin mu tí a bá ti parí ìgbéyàwó ìbílẹ̀ náà. Nígbà tí ó bá yá, wọn óò lọ forúkọ ìgbéyàwó ìbílẹ̀ náà sílẹ̀ fún ète wíwulẹ̀ ní àkọsílẹ̀.
Láìṣe àní-àní, ìgbéyàwó jẹ́ ẹ̀bùn onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run fún aráyé, ẹ̀bùn aláìlẹ́gbẹ́ tí a kò tilẹ̀ fi fún àwọn áńgẹ́lì pàápàá. (Lúùkù 20:34-36) Ó jẹ́ ipò ìbátan ṣíṣeyebíye tí ó yẹ láti pa mọ́ fún ògo Olùdásílẹ̀ rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Wọ́n ń ki òrùka bọra wọn lọ́wọ́