Ìgbéyàwó Tó Ní Ọlá Lójú Ọlọ́run Àti Èèyàn
“Àsè ìgbéyàwó kan ṣẹlẹ̀ ní Kánà . . . Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni a ké sí síbi àsè ìgbéyàwó náà pẹ̀lú.”—JÒHÁNÙ 2:1, 2.
1. Kí ni ìtàn tí Bíbélì sọ nípa ibi ìgbéyàwó tí Jésù lọ ní Kánà jẹ́ ká mọ̀?
JÉSÙ, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kan àti ìyá rẹ̀ mọ̀ pé táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá ṣe ìgbéyàwó tó ní ọlá, ayẹyẹ ọ̀hún máa ń lárinrin. Kódà, Kristi mú kí ayẹyẹ ìgbéyàwó kan jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nítorí pé ibẹ̀ ló ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ, èyí tó mú káwọn èèyàn túbọ̀ gbádùn ayẹyẹ náà. (Jòhánù 2:1-11) Ó ṣeé ṣe kó o ti lọ síbi ìgbéyàwó àwọn Kristẹni tí wọ́n fẹ́ jọ máa fi ayọ̀ sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya, kó o sì gbádùn rẹ̀ gan-an. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ni ìwọ fúnra rẹ ń fojú sọ́nà fún irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ tàbí kó jẹ́ pé o fẹ́ bá ọ̀rẹ́ rẹ kan múra ìgbéyàwó rẹ̀ sílẹ̀ kí nǹkan lè lọ bó ṣe yẹ. Kí lo lè ṣe kí ayẹyẹ náà lè lọ bó ṣe yẹ?
2. Kí ni Bíbélì sọ nípa ìgbéyàwó?
2 Àwọn Kristẹni mọ̀ pé ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń ṣèrànwọ́ gan-an fún ọkùnrin àti obìnrin tó ń múra àtiṣe ìgbéyàwó. (2 Tímótì 3:16, 17) Ká sòótọ́, Bíbélì ò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa gbogbo ètò táwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìgbéyàwó. Àwa náà yóò sì gbà pé kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀ torí pé àṣà ìbílẹ̀ àtàwọn ohun tí ìjọba ń béèrè máa ń yàtọ̀ láti ibì kan sí ibòmíràn àti láti àkókò kan sí àkókò mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò sí ọ̀nà kan pàtó táwọn èèyàn gbà ń ṣe ìgbéyàwó. Lọ́jọ́ ìgbéyàwó, ọkọ ìyàwó yóò kàn mú aya rẹ̀ wá sílé rẹ̀ tàbí sílé bàbá rẹ̀ ni. (Jẹ́nẹ́sísì 24:67; Aísáyà 61:10; Mátíù 1:24) Mímú tí ọkọ ìyàwó mú ìyàwó rẹ̀ níṣojú gbogbo èèyàn yìí gan-an ni ìgbéyàwó wọn, láìsí pé wọ́n ń ṣe gbogbo ètò tí wọ́n máa ń ṣe nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ìgbéyàwó lónìí.
3. Ayẹyẹ wo ni wọ́n ṣe ní Kánà tí Jésù mú kó túbọ̀ lárinrin?
3 Lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìgbéyàwó lohun tí wọ́n ṣe yẹn jẹ́. Lẹ́yìn èyí, wọ́n lè wá pe àpèjẹ, irú èyí tí Jòhánù 2:1 mẹ́nu kàn. Bí wọ́n ṣe túmọ̀ ẹsẹ yẹn nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì nìyí: “Wọ́n ṣe ìgbéyàwó kan ní Kánà.” Àmọ́, ìtúmọ̀ tó bá ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí ìgbéyàwó mu jù lọ ni “àsè ìgbéyàwó.”a (Mátíù 22:2-10; 25:10; Lúùkù 14:8) Ìtàn yẹn fi hàn kedere pé Jésù lọ síbi àsè ìgbéyàwó àwọn Júù kan, ó sì ṣe ohun tó mú káwọn èèyàn túbọ̀ gbádùn ayẹyẹ náà. Àmọ́ o, kókó pàtàkì kan tó yẹ ká rántí ni pé ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe ìgbéyàwó láyé ìgbà yẹn yàtọ̀ sí ti ìsinsìnyí.
4. Irú ìgbéyàwó wo làwọn Kristẹni kan fẹ́, kí sì nìdí rẹ̀?
4 Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lóde òní, àwọn ohun kan wà tí òfin là kalẹ̀ táwọn Kristẹni tó bá fẹ́ ṣègbéyàwó gbọ́dọ̀ ṣe. Bí wọ́n bá ti ṣe é, wọ́n lè wá ṣègbéyàwó wọn lọ́nà èyíkéyìí tó bófin mu. Èyí lè jẹ́ ètò ráńpẹ́ kan tí adájọ́, olórí ìlú tàbí òjíṣẹ́ ìsìn kan tí Ìjọba Àpapọ̀ fún láṣẹ máa ṣe fáwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó náà. Irú ìgbéyàwó táwọn kan fẹ́ nìyẹn. Wọ́n lè sọ pé káwọn mélòó kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tàbí àwọn ọ̀rẹ́ wọn tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí wà níbẹ̀ láti bá wọn tọwọ́ bọ̀wé tàbí kí wọ́n kàn wá bá wọn yọ̀ lọ́jọ́ ayẹyẹ pàtàkì náà. (Jeremáyà 33:11; Jòhánù 3:29) Bákan náà, àwọn Kristẹni mìíràn lè pinnu pé àwọn ò ní se àsè bẹ́ẹ̀ làwọn ò ní pe àpèjẹ ńlá tí wàhálà àti ìnáwó rẹ̀ máa ń pọ̀ gan-an. Dípò ìyẹn, wọ́n kàn lè se oúnjẹ níwọ̀nba fáwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn mélòó kan. Èyí tó wù kéèyàn ṣe níbẹ̀, ó yẹ ká rántí pé èrò àwọn Kristẹni mìíràn tí wọ́n dàgbà dénú lórí ọ̀rọ̀ yìí lè yàtọ̀ sí tiwa.—Róòmù 14:3, 4.
5. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni fi máa ń fẹ́ kí wọ́n sọ àsọyé nígbà ìgbéyàwó àwọn, kí ni àsọyé yìí sì máa ń dá lé lórí?
5 Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni tó fẹ́ ṣègbéyàwó ló máa ń fẹ́ kí wọ́n sọ àsọyé tó dá lórí Bíbélì nígbà ìgbéyàwó wọn.b Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀, ó sì ti pèsè ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, èyí tó lè jẹ́ kí àárín tọkọtaya gún káwọn méjèèjì sì láyọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:22-24; Máàkù 10:6-9; Éfésù 5:22-33) Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló sì máa ń fẹ́ kí tẹbí-tọ̀rẹ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni bá wọn nípìn-ín nínú ayọ̀ ọjọ́ náà. Síbẹ̀, ojú wo ló yẹ ká fi wo onírúurú òfin ìjọba, àwọn ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe ìgbéyàwó àtàwọn àṣà ìbílẹ̀ tó ti wà tipẹ́tipẹ́? A óò jíròrò bí wọ́n ṣe ń ṣe ètò ìgbéyàwó níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí. Àwọn kan lè yàtọ̀ pátápátá sóhun tó o mọ̀ tàbí sóhun tí wọ́n ń ṣe lágbègbè rẹ. Síbẹ̀, wàá rí àwọn ìlànà tàbí àwọn ohun kan tó bára mu nínú wọn, èyí tó ṣe pàtàkì fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run.
Ìgbéyàwó Tó Ní Ọlá Gbọ́dọ̀ Bá Òfin Mu
6, 7. Kí nìdí tó fi yẹ ká fojú pàtàkì wo àwọn ohun tí òfin sọ nípa ìgbéyàwó ṣíṣe, báwo la sì ṣe lè fi hàn pé à ń ṣe èyí?
6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lẹni tó dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀, ìjọba èèyàn ṣì láṣẹ, lọ́nà kan tàbí òmíràn, lórí ohun táwọn tó fẹ́ di tọkọtaya ń ṣe. Kò sì sóhun tó burú nínú èyí. Jésù sọ pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Máàkù 12:17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sì sọ pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga, nítorí kò sí ọlá àṣẹ kankan bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; àwọn ọlá àṣẹ tí ó wà ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—Róòmù 13:1; Títù 3:1.
7 Ní ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè, Késárì, ìyẹn àwọn aláṣẹ, ló ń pinnu ẹni tó lè ṣègbéyàwó. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, táwọn Kristẹni méjì tí wọ́n lómìnira láti ṣègbéyàwó lójú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ bá fẹ́ ṣègbéyàwó, wọ́n máa ń rí i dájú pé àwọn ṣe ohun tí òfin ìjọba àgbègbè wọn sọ, bóyá kí wọ́n lọ gbàwé àṣẹ, kí wọ́n lo aṣojú ìjọba láti so wọ́n pọ̀, tàbí kí wọ́n lọ forúkọ ìgbéyàwó tí wọ́n ti ṣe sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba. Nígbà tí Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì sọ pé káwọn èèyàn lọ “forúkọ sílẹ̀,” Màríà àti Jósẹ́fù ṣègbọràn, ìyẹn ni wọ́n fi rìnrìn àjò lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù “láti forúkọ sílẹ̀.”—Lúùkù 2:1-5.
8. Kí làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe, kí sì nìdí rẹ̀?
8 Báwọn Kristẹni méjì bá ti ṣègbéyàwó tó bófin mu tó sì jẹ́ èyí táwọn èèyàn tẹ́wọ́ gbà, wọ́n ti di ọ̀kan nìyẹn lójú Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í tún ìgbéyàwó tó bófin mu tí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bákan náà, a kì í tún ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó kà nígbà tí a bá ń ṣe àyájọ́ ìgbéyàwó wa, irú bíi nígbà ọdún kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tàbí àádọ́ta ọdún ìgbéyàwó. (Mátíù 5:37) (Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kan kì í fojú pàtàkì wo ìgbéyàwó tí wọ́n bá ṣe lọ́dọ̀ ìjọba bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó bófin mu. Wọ́n sọ pé irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ torí pé àlùfáà tàbí olórí ìsìn kan kọ́ ló darí ètò náà tàbí ló so àwọn méjèèjì pọ̀.) Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ìjọba fún àwọn kan lára àwọn òjíṣẹ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láṣẹ láti so ọkùnrin àti obìnrin pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya. Níbi tí ìjọba bá ti yọ̀ọ̀da irú nǹkan bẹ́ẹ̀, òjíṣẹ́ náà lè ṣe èyí pa pọ̀ pẹ̀lú àsọyé ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn ibi táwọn Ẹlẹ́rìí ti ń pàdé fún ìjọsìn tòótọ́ ládùúgbò kọ̀ọ̀kan. Ibẹ̀ jẹ́ ibi tó yẹ fún sísọ àsọyé lórí ètò ìgbéyàwó tí Jèhófà Ọlọ́run dá sílẹ̀.
9. (a) Tó bá dọ̀rọ̀ ìgbéyàwó lọ́dọ̀ ìjọba, kí làwọn Kristẹni tí wọ́n fẹ́ ṣègbéyàwó lè ṣe tó bá wù wọ́n? (b) Báwo ni ètò ìgbéyàwó ṣe lè kan àwọn alàgbà?
9 Láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ohun tí òfin sọ ni pé káwọn tó bá fẹ́ ṣègbéyàwó lọ ṣe é ní ọ́fíìsì ìjọba tàbí kí aṣojú tí ìjọba yàn so wọ́n pọ̀. Lẹ́yìn èyí, àwọn Kristẹni sábà máa ń ṣètò àsọyé ìgbéyàwó nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́jọ́ kan náà tàbí lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e. (Kò yẹ kí wọ́n jẹ́ kí ọjọ́ púpọ̀ wà láàárín ọjọ́ tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó lọ́dọ̀ ìjọba àti ọjọ́ tí wọ́n máa sọ àsọyé ìgbéyàwó, nítorí pé ìgbéyàwó tí wọ́n ṣe lọ́dọ̀ ìjọba ti sọ wọ́n di tọkọtaya lójú Ọlọ́run àti èèyàn, títí kan ìjọ Kristẹni.) Bó bá wu àwọn tó fẹ́ ṣe ìgbéyàwó lọ́dọ̀ ìjọba (ìyẹn Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó) pé kí wọ́n gbọ́ àsọyé ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, wọ́n ní láti gbàṣẹ lọ́wọ́ àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ ibẹ̀ ṣáájú. Yàtọ̀ sí pé àwọn alàgbà wọ̀nyí á rí i dájú pé àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó náà jẹ́ ẹni tó ní orúkọ rere, wọ́n á tún rí i dájú pé àkókò tí ìgbéyàwó náà máa bọ́ sí kò forí gbárí pẹ̀lú àkókò ìpàdé àtàwọn ètò mìíràn tí wọ́n fẹ́ ṣe nínú gbọ̀ngàn yẹn. (1 Kọ́ríńtì 14:33, 40) Àwọn alàgbà náà á tún gbé àwọn ohun táwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó fẹ́ ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́jọ́ náà yẹ̀ wò, wọ́n á sì pinnu bóyá kí wọ́n ṣèfilọ̀ fáwọn ará pé àwọn kan fẹ́ lo gbọ̀ngàn náà.
10. Bó bá jẹ́ pé ìgbéyàwó lọ́dọ̀ ìjọba làwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó fẹ́ ṣe, báwo nìyẹn ṣe máa kan àsọyé ìgbéyàwó?
10 Alàgbà tó máa sọ àsọyé náà yóò gbìyànjú láti rí i pé ọ̀rọ̀ náà tuni lára, ó gbéni ró, ó sì buyì kúnni. Bí wọ́n bá ti ṣègbéyàwó lọ́dọ̀ ìjọba, alàgbà náà yóò sọ fáwọn olùgbọ́ pé wọ́n ti ṣègbéyàwó lọ́nà tó bá òfin Késárì mu ṣáájú. Bí wọn ò bá ka ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó nígbà yẹn, wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà àsọyé náà.c Bí wọ́n bá sì ti ka ẹ̀jẹ́ nígbà tí wọ́n ṣègbéyàwó níwájú aṣojú ìjọba ṣùgbọ́n tí wọ́n fẹ́ ka ẹ̀jẹ́ níwájú Jèhófà àti ìjọ, kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí bẹ̀rẹ̀ ẹ̀jẹ́ náà: “Mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ ní [sọ àkókò tàbí ọjọ́] pé . . . ,” kí èyí lè fi hàn pé a “ti so [wọ́n] pọ̀” gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya ṣáájú àkókò yẹn.—Mátíù 19:6; 22:21.
11. Láwọn ibì kan, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe ìgbéyàwó, báwo lèyí yóò sì ṣe kan àsọyé ìgbéyàwó?
11 Láwọn ibì kan, òfin lè má sọ ọ́ di dandan pé kí ẹnì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ so àwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó pọ̀ lọ́nà pàtó kan, ì báà tiẹ̀ jẹ́ aṣojú ìjọba pàápàá. Bí wọ́n bá ti lè mú fọ́ọ̀mù ìforúkọsílẹ̀ ìgbéyàwó tí wọ́n ti buwọ́ lù fún aṣojú ìjọba, tí aṣojú ìjọba sì fún wọn ní ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó wọn, wọ́n ti ṣègbéyàwó nìyẹn. Ohun tí wọ́n ṣe yìí ló máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé wọ́n ti di tọkọtaya, ọjọ́ tó sì wà lórí ìwé ẹ̀rí náà ni yóò jẹ́ ọjọ́ ìgbéyàwó wọn. Bá a ṣe sọ lókè, àwọn tí wọ́n bá ṣègbéyàwó lọ́nà yìí lè ṣètò pé kété lẹ́yìn gbígba ìwé ẹ̀rí yẹn, àwọn á lọ gbọ́ àsọyé ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Arákùnrin tó dàgbà dénú tí wọ́n yàn pé kó sọ àsọyé náà yóò sọ fún àwọn tó wà nínú gbọ̀ngàn náà pé ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà ti fi hàn pé wọ́n ti di tọkọtaya ṣáájú ìgbà àsọyé náà. Tí wọ́n bá máa ka ẹ̀jẹ́ rárá, wọ́n ní láti jẹ́ kó bá ohun tá a sọ ní ìpínrọ̀ 10 àti àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé ibẹ̀ mu. Àwọn tó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yóò bá tọkọtaya náà yọ̀ wọn yóò sì jàǹfààní nínú ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́.—Orin Sólómọ́nì 3:11.
Ìgbéyàwó Ti Ìbílẹ̀ àti Ìgbéyàwó Lọ́dọ̀ Ìjọba
12. Kí ni ìgbéyàwó ti ìbílẹ̀, kí ló sì bọ́gbọ́n mu kí tọkọtaya ṣe lẹ́yìn irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀?
12 Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ìgbéyàwó ti ìbílẹ̀ làwọn èèyàn máa ń ṣe. Kì í ṣe pé kí ọkùnrin àtobìnrin máa jọ gbé pa pọ̀ là ń sọ o, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé káwọn méjì kàn mú ara wọn ní ọkọ àtìyàwó, èyí tí wọ́n fàyè gbà láwọn ibì kan àmọ́ tí kò bá òfin mu délẹ̀délẹ̀.d Ìgbéyàwó ti ìbílẹ̀ tí à ń sọ níbí ni ìgbéyàwó tó bá àṣà ìbílẹ̀ táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa lágbègbè kan mu. Nínú irú ìgbéyàwó yìí, wọ́n lè ní kí ọkọ kọ́kọ́ san owó orí ìyàwó fún àna rẹ̀. Èyí ló máa fi hàn pé àwọn méjèèjì ti ṣègbéyàwó tó bófin mu tó sì bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu. Ìjọba ka irú ìgbéyàwó ti ìbílẹ̀ bẹ́ẹ̀ sí ìgbéyàwó tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, tó bófin mu, tó sì ti sọ àwọn méjèèjì di tọkọtaya. Lẹ́yìn èyí, wọ́n lè lọ forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba, kí wọ́n sì gba ìwé ẹ̀rí. Fífi orúkọ ìgbéyàwó sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba lọ́nà yìí yóò ṣàǹfààní fún tọkọtaya náà lọ́jọ́ iwájú, tàbí fún ìyàwó bó bá di pé ọkọ kú, tàbí fáwọn ọmọ tí wọ́n máa bí. Ìjọ yóò gba ẹnikẹ́ni tó bá ṣe ìgbéyàwó ìbílẹ̀ nímọ̀ràn láti lọ forúkọ ìgbéyàwó rẹ̀ sílẹ̀ láìjáfara. Àní nínú Òfin Mósè pàápàá, ó jọ pé àwọn èèyàn máa ń lọ forúkọ ìgbéyàwó tàbí ọmọ tí wọ́n bá bí sílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ.—Mátíù 1:1-16.
13. Lẹ́yìn ìgbéyàwó ti ìbílẹ̀, àwọn ìlànà wo ló yẹ ká tẹ̀ lé tí wọ́n bá máa sọ àsọyé ìgbéyàwó?
13 Gbàrà tí wọ́n bá ti so ọkùnrin àti obìnrin pọ̀ nígbà ìgbéyàwó ìbílẹ̀ ni wọ́n ti di tọkọtaya. Bá a ṣe sọ lókè, àwọn Kristẹni tí wọ́n bá ṣe irú ìgbéyàwó tó bófin mu bẹ́ẹ̀ lè fẹ́ gbọ́ àsọyé ìgbéyàwó kí wọ́n sì ka ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí wọ́n bá máa ṣe bẹ́ẹ̀, alásọyé yóò sọ nígbà àsọyé náà pé tọkọtaya náà ti di ọkọ àti aya ṣáájú àkókò yẹn níbàámu pẹ̀lú òfin Késárì. Ìgbéyàwó kan ṣoṣo ni wọ́n ṣe, ìyẹn ni ìgbéyàwó ti ìbílẹ̀. Ìgbéyàwó yìí bá òfin mu ó sì lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀, àsọyé ìgbéyàwó kan ṣoṣo la ó sì sọ. Bá ò bá jẹ́ kí ọjọ́ ìgbéyàwó àti àsọyé yìí jìn síra wọn, tó bá ṣeé ṣe kó jẹ́ ọjọ́ kan náà, á jẹ́ kí ìgbéyàwó àwa Kristẹni túbọ̀ ní ọlá lójú àwọn èèyàn.
14. Kí ni Kristẹni kan lè ṣe tí òfin bá yọ̀ọ̀da pé èèyàn lè ṣègbéyàwó ti ìbílẹ̀ tàbí ti ìjọba?
14 Láwọn ilẹ̀ kan tí wọ́n ti ka ìgbéyàwó ti ìbílẹ̀ sóhun tó bófin mu, òfin tún sọ pé èèyàn lè ṣe ìgbéyàwó lọ́dọ̀ ìjọba. Aṣojú ìjọba kan ló sábà máa ń so tọkọtaya pọ̀ nínú irú ìgbéyàwó yìí, wọ́n sì lè sọ pé káwọn méjèèjì ka ẹ̀jẹ́ kí wọ́n sì tọwọ́ bọ̀wé. Àwọn Kristẹni kan fẹ́ràn ìgbéyàwó tí wọ́n á ṣe lọ́dọ̀ aṣojú ìjọba yìí ju ìgbéyàwó ti ìbílẹ̀ lọ. Òfin ò sọ pé káwọn tó fẹ́ di tọkọtaya ṣe ìgbéyàwó méjèèjì yìí pa pọ̀ torí pé méjèèjì ló bófin mu. Ohun tí ìpínrọ̀ 9 àti 10 sọ nípa gbígbọ́ àsọyé ìgbéyàwó àti kíka ẹ̀jẹ́ la máa tẹ̀ lé nínú irú ìgbéyàwó yìí náà. Kókó ibẹ̀ ni pé kí tọkọtaya rí i pé ìgbéyàwó tó ní ọlá lójú Ọlọ́run àti èèyàn làwọn ṣe.—Lúùkù 20:25; 1 Pétérù 2:13, 14.
Ẹ Jẹ́ Kí Ọlá Wà Nínú Ìgbéyàwó Yín
15, 16. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ọlá wà nínú ìgbéyàwó?
15 Nígbà tí ìṣòro wà láàárín ọba ilẹ̀ Páṣíà kan àti ìyàwó rẹ̀, ọ̀kan lára àwọn bọ́bajíròrò tó ń jẹ́ Mẹ́múkánì dámọ̀ràn ohun kan tó lè ṣe tọkọtaya láǹfààní, ìyẹn ni pé ‘kí gbogbo àwọn aya máa fi ọlá fún ọkọ wọn.’ (Ẹ́sítérì 1:20) Nínú ìgbéyàwó àwọn Kristẹni, kò yẹ kó jẹ́ pé ọba tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn ló máa ṣẹ̀ṣẹ̀ pàṣẹ pé kí wọ́n tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn. Ńṣe ló yẹ káwọn aya máa bọlá fáwọn ọkọ wọn. Lọ́nà kan náà, ó yẹ káwọn ọkọ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni máa fi ọlá fáwọn aya wọn, kí wọ́n sì máa yìn wọ́n. (Òwe 31:11, 30; 1 Pétérù 3:7) Kì í ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lẹ́yìn téèyàn ti ṣègbéyàwó ló yẹ kó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa fi ọlá hàn nínú ìgbéyàwó rẹ̀. Àtìbẹ̀rẹ̀ ló ti yẹ kó máa fi í hàn, àní látọjọ́ ìgbéyàwó.
16 Ọkọ àti ìyàwó nìkan kọ́ ló yẹ kó fi ọlá hàn lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn. Bí alàgbà bá máa sọ àsọyé ìgbéyàwó, ó ní láti rí i pé àsọyé yìí ní ọlá pẹ̀lú. Tọkọtaya náà ló máa darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àsọyé náà wà lára ohun tó máa fi bọlá fún wọn, kò yẹ kí alásọyé náà sọ ọ́ di ọ̀rọ̀ àwàdà tàbí kó máa pa ìtàn àlọ́ lásán. Kò yẹ kó sọ àwọn ohun tó jẹ́ ọ̀rọ̀ àṣírí nípa tọkọtaya náà, èyí tó lè kó ìtìjú bá àwọn àtàwọn olùgbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kó fi ọ̀yàyà sọ̀rọ̀, kó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà gbéni ró. Kó tún rí i pé Ọlọ́run tó dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀ àti ìmọ̀ràn rẹ̀ tó ta yọ gbogbo ìmọ̀ràn ẹ̀dá ni òun gbé lárugẹ nínú ọ̀rọ̀ náà. Kò sí àní-àní pé àsọyé ìgbéyàwó tó buyì kúnni tí alàgbà náà bá sọ yóò wà lára ohun tó máa jẹ́ kí ìgbéyàwó náà bọlá fún Jèhófà Ọlọ́run.
17. Kí nìdí tí ohun tí òfin béèrè fi jẹ́ ara ètò ìgbéyàwó àwọn Kristẹni?
17 Wàá kíyè sí i pé nínú àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ púpọ̀ gan-an nípa onírúurú ohun tí òfin béèrè téèyàn bá fẹ́ ṣègbéyàwó. Àwọn kan lára ohun tá a sọ yìí lè má bá ohun tí wọ́n ń ṣe lágbègbè rẹ mu. Síbẹ̀, ó yẹ kí gbogbo wa máa rántí pé ó ṣe pàtàkì pé kí ètò ìgbéyàwó táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe fi hàn pé à ń tẹ̀ lé òfin Késárì, ìyẹn òfin ìjọba ibi tá à ń gbé. (Lúùkù 20:25) Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé: “Ẹ fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, ẹni tí ó béèrè fún owó orí, ẹ fún un ní owó orí; ẹni tí ó béèrè fún owó òde, ẹ fún un ní owó òde; . . . ẹni tí ó béèrè fún ọlá, ẹ fún un ní irúfẹ́ ọlá bẹ́ẹ̀.” (Róòmù 13:7) Bẹ́ẹ̀ ni o, ó dára kó jẹ́ pé látọjọ́ ìgbéyàwó ni Kristẹni yóò ti máa fi ọlá fún ètò tí Ọlọ́run ti ṣe fún àkókò tá a wà yìí.
18. Kí lohun táwọn tó fẹ́ ṣègbéyàwó lè ṣe tó bá wù wọ́n tá a máa gbé yẹ̀ wò, ibo la sì ti lè rí àlàyé nípa rẹ̀?
18 Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ Kristẹni bá ti ṣe ìgbéyàwó, àsè ìgbéyàwó tàbí àpèjẹ ló sábà máa ń tẹ̀ lé e. Má gbàgbé pé Jésù lọ sí ọ̀kan lára irú àwọn àsè bẹ́ẹ̀. Bí tọkọtaya kan bá wá ṣètò irú àpèjẹ bẹ́ẹ̀, báwo ni ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí i pé ìyẹn náà yóò bọlá fún Ọlọ́run, kò sì ní kó ẹ̀gàn bá àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó náà àti ìjọ Kristẹni? Kókó yẹn gan-an ni àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò jíròrò.e
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì yẹn kan náà tún lè túmọ̀ sí àsè tí kì í ṣe ti ìgbéyàwó.—Ẹ́sítérì 9:22, Bíbélì Septuagint.
b Ìwé àsọyé ọlọ́gbọ̀n ìṣẹ́jú tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Ìgbéyàwó Tí Ó Ní Ọlá Lójú Ọlọ́run,” làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lò. Inú ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé àtàwọn ìwé mìíràn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe la ti mú ìmọ̀ràn àtàtà látinú Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìwé àsọyé yìí. Ọ̀rọ̀ àsọyé náà wúlò gan-an fáwọn tó ń ṣègbéyàwó àti gbogbo àwọn tó bá wá síbẹ̀.
c Àwọn ẹ̀jẹ́ tó ń bọlá fún Ọlọ́run tó tẹ̀ lé e yìí làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lò, àyàfi tí òfin ìjọba ibi tá à ń gbé bá ṣe ètò míì. Ọkọ á sọ pé: “Èmi [orúkọ ọkọ] fi ìwọ [orúkọ ìyàwó] ṣe aya mi tí mo bá ṣe ìgbéyàwó, ẹni tí màá máa nífẹ̀ẹ́, tí màá sì máa ṣìkẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú òfin tí Ọlọ́run là lẹ́sẹẹsẹ sínú Ìwé Mímọ́ fún Kristẹni ọkọ, níwọ̀n ìgbà tí àwa méjèèjì bá fi jọ wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run ṣe.” Ìyàwó á sọ pé: “Èmi [orúkọ ìyàwó] fi ìwọ [orúkọ ọkọ] ṣe ọkọ mi tí mo bá ṣe ìgbéyàwó, ẹni tí màá máa nífẹ̀ẹ́, tí màá máa ṣìkẹ́, tí màá sì máa ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ní ìbámu pẹ̀lú òfin tí Ọlọ́run là lẹ́sẹẹsẹ sínú Ìwé Mímọ́ fún Kristẹni aya, níwọ̀n ìgbà tí àwa méjèèjì bá fi jọ wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run ṣe.”
d Ilé Ìṣọ́ May 1, 1962 (èdè Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 287 sọ̀rọ̀ nípa àṣà mímú tí àwọn ẹni méjì ń mú ara wọn ní ọkọ àtìyàwó.
e Tún wo àpilẹ̀kọ tó ní àkọlé náà “Ṣe Ohun Tó Máa Jẹ́ Kí Ayọ̀ àti Iyì Ọjọ́ Ìgbéyàwó Rẹ Pọ̀ Sí I,” èyí tó bẹ̀rẹ̀ látojú ìwé 28.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tó fi yẹ kí ohun tí òfin sọ àtohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìgbéyàwó jẹ wá lógún?
• Bí àwọn Kristẹni méjì bá lọ ṣègbéyàwó lọ́dọ̀ ìjọba, kí ni wọ́n lè pinnu pé àwọn yóò ṣe kété lẹ́yìn náà?
• Kí nìdí tá a fi máa ń sọ àsọyé ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un ṣe máa ń ṣègbéyàwó ni pé, ńṣe ni ọkọ ìyàwó á kàn mú aya rẹ̀ wá sílé rẹ̀ tàbí sílé bàbá rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Lẹ́yìn ìgbéyàwó ti ìbílẹ̀, àwọn Kristẹni tó bá fẹ́ lè lọ gbọ́ àsọyé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba