ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 4/15 ojú ìwé 23-26
  • Ayẹyẹ Ìgbéyàwó Tí Ń Bọlá fún Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ayẹyẹ Ìgbéyàwó Tí Ń Bọlá fún Jèhófà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣe Ohun Tó Máa Jẹ́ Kí Ayọ̀ àti Iyì Ọjọ́ Ìgbéyàwó Rẹ Pọ̀ Sí I
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àwọn Ìgbéyàwó Aláyọ̀ Tí Ń bọlá Fún Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Jẹ́ Kí Ọ̀nà Tí o Gbà Ń gbé Ìgbésí Ayé Rẹ Fi Hàn Pé o Ní Ìgbàgbọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 4/15 ojú ìwé 23-26

Ayẹyẹ Ìgbéyàwó Tí Ń Bọlá fún Jèhófà

Etiópíà ni a ti pilẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ tí ó wà nísàlẹ̀ yí lórí ayẹyẹ ìgbéyàwó Kristẹni, láti pèsè ìtọ́sọ́nà wíwúlò ní èdè Amharic, fún ọ̀pọ̀ ní orílẹ̀-èdè náà, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ní í ṣe pẹ̀lú díẹ̀ lára àwọn àṣà ìbílẹ̀ àti ìwà tí ó lè yàtọ̀ sí ti apá ibi tí o ń gbé. Ìwọ dájúdájú yóò rí i pé àwọn ìyàtọ̀ yẹn fani mọ́ra. Lọ́wọ́ kan náà, àpilẹ̀kọ náà gbé ìmọ̀ràn tí ó wà déédéé, tí ìwọ yóò rí i pé, ó bá Bíbélì mu kalẹ̀, tí ìwọ yóò rí i pé ó ṣeé mú lò, àní bí àwọn àṣà ìbílẹ̀ ayẹyẹ ìgbéyàwó ba tilẹ̀ yàtọ̀ ládùúgbò rẹ pàápàá.

“AWỌN Ayẹyẹ Igbeyawo Kristian Ti Nmu Ayọ Wá” ni àkòrí àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ dáradára kan nínú Ile-Iṣọ naa ti October 15, 1984. A pe àkòrí àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e nínú ìtẹ̀jáde kan náà ní, “Rí Igbadun Oniwọntunwọnsi nibi Awọn Àsè Ayẹyẹ Igbeyawo.” (Fún ẹnikẹ́ni tí ń ronú àtigbéyàwó, àwọn àfikún ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n ń bẹ nínú ìwé Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ, orí 2, àti Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, orí 19 àti 20.)a Ọ̀pọ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn tí a tẹ àwọn àpilẹ̀kọ yẹn jáde, nítorí náà, a fẹ́ ṣàtúnyẹ̀wò díẹ̀ lára ìsọfúnni inú àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí, tí ó ṣeé mú lò ní pàtàkì ní àdúgbò wa, àti àwọn kókó yíyẹ mìíràn, tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí àwọn àkókò ayẹyẹ ìgbéyàwó jẹ́ èyí tí ó bọlá fún Jèhófà, Olùdásílẹ̀ ìgbéyàwó.

Ìbéèrè tí a lè kọ́kọ́ gbé yẹ̀ wò ni, Nígbà wo ni ó yẹ kí ayẹyẹ ìgbéyàwó wáyé? Àkókò àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ayẹyẹ ìgbéyàwó ládùúgbò ha ni ó yẹ kí ó pinnu ọjọ́ náà bí? Ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn àdúgbò ni pé, ìgbéyàwó tí ó bá wáyé ní àkókò míràn láàárín ọdún kì yóò yọrí sí rere. Ìgbàgbọ́ asán tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni èyí jẹ́, nítorí ọ̀pọ̀ tọkọtaya, tí wọ́n ń sin Jèhófà tayọ̀tayọ̀ pẹ̀lú ìṣọ̀kan, kò ṣe ìgbéyàwó wọn nígbà àkókò àṣà àtọwọ́dọ́wọ́. Àwa kò gbà gbọ́ nínú oríire tàbí orí burúkú. (Aísáyà 65:11; Kólósè 2:8) A kò ní ran àwọn ìbátan wa aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́ láti rí ìyàtọ̀ láàárín òtítọ́ àti èké, bí a bá fi ayẹyẹ ìgbéyàwó sí ọjọ́ ìgbàgbọ́ asán wọn. Òkodoro òtítọ́ tí ń bẹ níbẹ̀ ni pé, àwọn Kristẹni lè ṣègbéyàwó nínú oṣù èyíkéyìí.

Nígbà tí a bá ṣètò fún àsọyé ìgbéyàwó lẹ́yìn tí a ti ṣe ààtò òfin ìlú pípọn dandan, yóò bọ́gbọ́n mu láti má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ púpọ̀ wà láàárín àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì náà. Bí àwọn méjèèjì bá fẹ́ kí a sọ àsọyé ìgbéyàwó nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó yẹ kí wọ́n tọ àwọn alàgbà ìjọ lọ, tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò, láti béèrè fún lílo gbọ̀ngàn náà. Àwọn alàgbà àdúgbò yóò rí i dájú pé, ìṣètò ayẹyẹ náà kò ní kó ìdààmú bá ẹ̀rí ọkàn wọn. Wọ́n gbọ́dọ̀ yan àkókò kí ó má baà forí gbárí pẹ̀lú ìgbòkègbodò ìjọ kankan. Arákùnrin tí a yàn láti sọ àsọyé ayẹyẹ ìgbéyàwó náà yóò pàdé pọ̀ ṣáájú pẹ́lù ìyàwó àti ọkọ ìyàwó lọ́la yìí, láti fún wọn ní ìmọ̀ràn wíwúlò àti láti rí i dájú pé kò sí àwọn ohun ìdíwọ́ fún ìgbéyàwó náà ní ti ìwà pálapàla tàbí ti òfin, pé òun sì fọwọ́ sí àwọn ìwéwèé fún àpèjẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà èyíkéyìí tí yóò tẹ̀ lé e. Kí àsọyé ìgbéyàwó náà gùn tó nǹkan bí 30 ìṣẹ́jú, kí a sì sọ ọ́ ní ọ̀nà tí ń fi iyì hàn, ní títẹnu mọ́ ipa tẹ̀mí tí ó ní. Dájúdájú, àsọyé ìgbéyàwó ṣe pàtàkì púpọ̀ ju àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu èyíkéyìí tí ó lè tẹ̀ lé e.

Ayẹyẹ ìgbéyàwó Kristẹni jẹ́ àǹfààní tí ó dára láti fi hàn pé a kì í ṣe “apá kan ayé.” (Jòhánù 17:14; Jákọ́bù 1:27) Ó yẹ kí ìwàlétòletò wa fara hàn kedere. Èyí túmọ̀ sí pé a óò dé lákòókò, dípò jíjẹ́ kí àwọn ènìyàn máa dúró dè wá, tí ó sì lè ṣàkóbá fún ìgbòkègbodò ìjọ. Èyí jẹ́ ohun pàtàkì tí ìyàwó náà gbọ́dọ̀ lóye dáradára, níwọ̀n bí àwọn ìbátan tí wọ́n jẹ́ ẹni ayé ti lè rọ̀ ọ́ pé kí ó pẹ́ lẹ́yìn—bíi pé èyí yóò fi kún ìjẹ́pàtàkì rẹ̀. Ní dídé lákòókò, Kristẹni arábìnrin kan tí ó dàgbà dénú lè fi hàn pé àwọn ànímọ́ tẹ̀mí, bí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgbatẹnirò, jẹ òun lógún! Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí a bá ké sí onífọ́tò láti wá ya fọ́tò ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ìwàlétòletò ṣe pàtàkì. Yóò dára láti béèrè pé kí onífọ́tò náà wọ jákẹ́ẹ̀tì, kí ó de táì, kí ó sì wọ ṣòkòtò tí ó bójú mu, kí ó má sì ṣe pín ọkàn ẹni níyà bí ó ti ń ya fọ́tò rẹ̀ nígbà tí àsọyé ń lọ lọ́wọ́. A kò gbọ́dọ̀ ya àwòrán nígbà tí a bá ń gbàdúrà. Ìwàlétòletò wa yóò bọlá fún Jèhófà, yóò sì jẹ́rìí tí ó dára. Kò sí ìdí láti gbìyànjú láti tẹ̀ lé àwọn àṣà ìgbéyàwó ayé tí yóò ṣíji bo ìtumọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ náà gan-an.

Àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu kò pọn dandan fún ayẹyẹ ìgbéyàwó tí ó yọrí sí rere, ṣùgbọ́n, Ìwé Mímọ́ kò lòdì sí irú ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, irú àpèjẹ bẹ́ẹ̀ fún àwọn Kristẹni tòótọ́ yẹ kí ó yàtọ̀ sí àwọn àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu tí ayé ń ṣe, tí àṣerégèé, ìmutípara, àjẹkì, orin ẹhànnà, ijó arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè, àti ìjà pàápàá ti máa ń jẹyọ. Bíbélì ka “àwọn àríyá aláriwo” mọ́ àwọn iṣẹ́ ti ara. (Gálátíà 5:21) Ó máa ń rọrùn láti ṣàkóso, tí àpèjẹ náà kò bá jẹ́ èyí tí a fi gbogbo ilé pọntí fọ̀nà rokà. Kò sí ìdí láti tẹ́ àtíbàbà láti lè tẹ̀ lé àṣà ìbílẹ̀ olókìkí. Bí àwọn kan bá pinnu láti lo àtíbàbà, nítorí àyè tàbí ojú ọjọ́, ọ̀ràn ara ẹni nìyẹn.

Ìrírí ti fi hàn pé, ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ láti gbà dín àwọn àlejò kù ni lílo ìwé ìkésíni pàtó. Ó bọ́gbọ́n mu láti ké sí ẹnì kọ̀ọ̀kan ju láti ké sí gbogbo ìjọ lódindi, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tí ó wà létòletò, a gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún irú ìdiwọ̀n bẹ́ẹ̀. Ìwé ìkésíni tún ń ṣèrànwọ́ fún wa láti yẹra fún ojútì tí ń wáyé nígbà tí ẹni tí a ti yọ lẹ́gbẹ́ bá yọjú síbi àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu náà, nítorí ti ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin lè yàn láti fi ibẹ̀ sílẹ̀. (Kọ́ríńtì Kíní 5:9-11) Bí tọkọtaya kan bá ké sí àwọn ìbátan wọn tàbí àwọn ojúlùmọ̀ wọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, dájúdájú, àwọn wọ̀nyí yóò mọ níwọ̀n, ní fífi hàn pé àwọn tí wọ́n “bá wa tan nínú ìgbàgbọ́” ṣe pàtàkì jù. (Gálátíà 6:10) Àwọn kan ti yàn láti ké sí àwọn ojúlùmọ̀ wọn inú ayé tàbí àwọn ìbátan wọn aláìgbàgbọ́ wá síbi àsọyé ìgbéyàwó dípò síbi àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu. Èé ṣe? Tóò, ó ti ṣẹlẹ̀ rí pé, àwọn ìbátan ayé ṣe ohun tí ń tini lójú níbi àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu ìyàwó, tí ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin fi ronú pé, àwọn kò lè dúró mọ́. Àwọn tọkọtaya kan ti ṣètò láti ṣe àpèjẹ ráńpẹ́ pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà ìdílé tí ó sún mọ́ wọn àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn tí ó jẹ́ Kristẹni.

Ní ìbámu pẹ̀lú Jòhánù 2:8, 9, ó dára láti yan “olùdarí àsè.” Ọkọ ìyàwó yóò fẹ́ láti yan Kristẹni kan tí ó ṣeé gbará lé, tí yóò rí sí i pé, a pa ìwàlétòletò àti ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga mọ́. Bí àwọn ọ̀rẹ́ bá gbé ẹ̀bùn wá, a gbọ́dọ̀ ṣe èyí láìsí ‘ìfihànsóde lọ́nà ṣekárími.’ (Jòhánù Kíní 2:16) A lè gbádùn orin láìjẹ́ pé àwọn ọ̀rọ̀ orin tí ń gbé ìbéèrè dìde, ariwo gèè, tàbí ìlù ẹhànnà kó èérí bá a. Ọ̀pọ̀ ti rí i pé ó máa ń dára jù lọ láti jẹ́ kí alàgbà kan tẹ́tí sí àwọn orin tí a óò lò ṣáájú àkókò. Ijó lè kó wa sínú ọ̀fìn, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn ijó ìbílẹ̀ ti wá láti inú ijó ẹni lè bímọ, ó sì máa ń ru ohun tí kò bójú mu sókè. Nígbà míràn, “àkókò ìgékéèkì àti ọtí ṣanpéènì” máa ń jẹ́ àkókò fún àwọn ènìyàn ayé láti sọ ìkóra-ẹni-níjàánu wọn nù. Ní ti gidi, ọ̀pọ̀ tọkọtaya Kristẹni ti pinnu láti má ṣe lo ọtí líle níbi àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu ìgbéyàwó wọn, tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún ìṣòro.

Níwọ̀n bí a ti fẹ́ láti bọlá fún Jèhófà, a óò yẹra fún ẹ̀mí ṣekárími láti pe àfiyèsí sọ́dọ̀ ara wa lọ́nà rírékọjá ààlà. Àwọn ìwé ayé pàápàá ti sọ̀rọ̀ lòdì sí ẹ̀mí àṣerégèé tí ó wọ́pọ̀. Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó fún tọkọtaya kan láti jẹ gbèsè nítorí ayẹyẹ ìgbéyàwó híhẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀, kí wọ́n sì wá pọ́n ara wọn lójú fún ọ̀pọ̀ ọdún, kí wọ́n baà lè san àwọn owó tí wọ́n ná fún ọjọ́ kan ṣoṣo! Dájúdájú, ó yẹ kí aṣọ èyíkéyìí tí a bá wọ̀ nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ èyí tí ó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí ó wà létòletò, tí ó yẹ ẹni tí ń jẹ́wọ́ gbangba pé òun ń fi ọ̀wọ̀ onífọkànsìn fún Ọlọ́run. (Tímótì Kíní 2:9, 10) Àpilẹ̀kọ náà, “Ìgbeyawo Kristian Gbọdọ Fi Iwọntun-wọ̀nsi Han” (Ile-Iṣọ Na January 15, 1970) ṣàlàyé fífani lọ́kàn mọ́ra yìí lórí aṣọ:

“Igbeyawo ẹnikan jẹ akoko patàki kan, nitorina afiyesi li a fi si kiki jijẹ alayọ ati ẹlẹwa. Sibẹ, eyi ko tumọsi pe ẹnikan gbọdọ wọ iru aṣọ kan tabi ẹwu. Ẹnikan yio ṣe rere lati ronu lori awọn aṣa, inawo ati ifẹ olukuluku. . . . Yio ha jẹ iwọntunwọnsi fun nwọn lati ra aṣọ olowo-giga bẹ, èyiti yio mu ki nwọn di ẹru ìnawo lori ara nwọn tabi lori awọn ẹlomiran? . . . Awọn iyawo miran ti gbadun lilo aṣọ ọrẹ ti o ṣọwọn fun nwọn tabi ibatan. Awọn miran ti ri itunu gba lati inu riran aṣọ igbeyawo tiwọn, o le ṣeṣe ni iru ọna bẹ pe nwọn yio ni aṣọ ti nwọn le lo nigbamiran ni ọjọ iwaju. O si lọgbọn ninu daradara fun tọkọtaya kan lati gbeyawo ninu aṣọ nwọn ẹlẹwa ti nwọn nlo nigbagbogbo . . . Awọn miran ti nwọn wa ni ipo ti nwọn ti le ṣe igbeyawo olokiki le fẹ lati ṣe ‘igbeyawo bokẹlẹ’ nitori lile koko ti akoko wa.”

Lọ́nà kan náà, ẹgbẹ́ ìyàwó (àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó àti àwọn obìnrin alájọṣepọ̀ ìyàwó) kò gbọ́dọ̀ pọ̀ jù. Àwọn pẹ̀lú kò ní fẹ́ láti pe àfiyèsí tí kò yẹ sọ́dọ̀ ara wọn, nípasẹ̀ ìmúra àti ìṣesí wọn. Bí a tilẹ̀ lè yọ̀ǹda fún ẹnì kan ti a ti yọ lẹ́gbẹ́ láti wá síbi àsọyé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, Ile-Iṣọ Naa October 15, 1984, sọ pé: “Yoo jẹ ohun ti ko yẹ lati ni laarin ẹgbẹ ayẹyẹ iyawo naa awọn eniyan ti a ti yọlẹgbẹ tabi ti ọna igbesi-aye onitiju wọn forigbari gidigidi pẹlu awọn ilana Bibeli.”

Bí Jésù tilẹ̀ lọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, a kò lè finú wòye pé òun yóò fọwọ́ sí àṣà olókìkí ti kí ọkọ̀ tò tẹ̀ lé ra wọn láàárín ìlú pẹ̀lú ariwo ńláǹlà; àwọn ọlọ́pàá tilẹ̀ ti mú kí àwọn awakọ̀ san owó ìtanràn nítorí fífi fèrè ọkọ̀ pariwo nínú ìtọ́wọ̀ọ́rìn ayẹyẹ ìgbéyàwó. (Wo Mátíù 22:21.) Ní àkópọ̀, dípò fífarawé ẹ̀mí ṣekárími tàbí àwọn ìgbésẹ̀ àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè, ó yẹ kí àwọn Kristẹni fi ọgbọ́n tí ń bẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn oníwọ̀ntunwọ̀nsì hàn.—Òwe 11:2.

Ríre ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó aládùúgbò ẹni, òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni nínú ayé, tàbí àwọn ìbátan jíjìnnà àti ojúlùmọ̀ ẹni ńkọ́? Kristẹni kọ̀ọ̀kan ni yóò fúnra rẹ̀ ṣèpinnu lórí èyí. Yóò dára láti rántí pé, àkókò wa ṣeyebíye, níwọ̀n bí a ti nílò àkókò fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, àti fún àwọn ìlépa mìíràn nínú ìdílé àti ìjọ. (Éfésù 5:15, 16) Ní òpin ọ̀sẹ̀, a ní àwọn ìpàdé àti iṣẹ́ ìsìn pápá tí a kì í fẹ́ láti pa jẹ. (Hébérù 10:24, 25) Àkókò tí a máa ń ṣe ọ̀pọ̀ ayẹyẹ ìgbéyàwó máa ń forí gbárí pẹ̀lú àkókò àwọn àpéjọ tàbí àkànṣe iṣẹ́ ìsìn tí ó so pọ̀ mọ́ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Kò yẹ kí a jẹ́ kí a pín ọkàn wa níyà láti ṣe ìsapá àkànṣe tí àwọn ará wa kárí ayé ń ṣe láti pésẹ̀ síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Kí a tó wá sínú ìmọ̀ òtítọ́, a lo ọ̀pọ̀ àkókò pẹ̀lú àwọn ènìyàn ayé, bóyá ní àwọn àyíká ipò tí ó tàbùkù sí Ọlọ́run pàápàá. (Pétérù Kíní 4:3, 4) Àwọn ohun àkọ́múṣe wa ti yàtọ̀ báyìí. Ó sáà máa ń ṣeé ṣe láti fi hàn pé a ń fẹ́ ire tọkọtaya ayé kan nípa fífi káàdì ránṣẹ́ tàbí ṣíṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sí wọn ní àkókò míràn. Àwọn kan ti lo irú àkókò bẹ́ẹ̀ láti jẹ́rìí, ní ṣíṣàjọpín àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó bá àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó mu.

Ayẹyẹ ìgbéyàwó, nínú èyí tí àwọn ohun tẹ̀mí ti jọba lórí àwọn ọ̀nà ayé, yóò bọlá fún Jèhófà ní tòótọ́. Àwọn Kristẹni yóò gbádùn ìṣẹ̀lẹ̀ náà nípa rírí i dájú pé wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ pátápátá kúrò nínú ayé ní ti ṣíṣàìní ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti yíyẹra fún àwọn àṣerégèé rẹ̀, nípa ṣíṣàìjẹ́ kí ó forí gbárí pẹ̀lú àwọn ìgbòkègbodò déédéé ti ìṣàkóso Ọlọ́run, àti nípa fífi ẹ̀mí ìwọ̀ntúnwọ̀nsì hàn dípò ẹ̀mí ṣekárími. Síwájú sí i, yóò ṣeé ṣe fún wọn láti bojú wẹ̀yìn wo ìṣẹ̀lẹ̀ náà pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn rere àti ìrántí tí ń gbádùn mọ́ni. Ní fífi ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ hàn, ǹjẹ́ kí gbogbo ayẹyẹ ìgbéyàwó Kristẹni wa jẹ́rìí fún àwọn aláìlábòsí ọkàn tí ń wòran.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Àwọn Kristẹni kì í tẹ̀ lé gbogbo àṣà ayẹyẹ ìgbéyàwó àdúgbò bí ẹrú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́